APC, NNPP Kọminú lórí ìgbésẹ̀ Amẹ́ríkà láti fòfin de Kwankwaso lórí ìkọlù sáwọn Kristẹni

Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC àti New Nigeria Peoples Party, NNPP ti ní àwọn kò faramọ́ ìgbésẹ̀ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà láti fòfin de físà àti gbígbé ẹsẹ̀ lé àwọn ohun ìní gómìnà tẹ́lẹ̀ rí fún ìpínlẹ̀ Kano, Rabiu Kwankwaso àti ẹgbẹ́ Miyetti Allah Cattle Breeders Association lórí ẹ̀sùn pé wọ́n ń tàpa sófin ẹ̀sìn ní Nàìjíríà.
APC bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ náà pé ẹ̀sùn lásán ni wọ́n fi kan Kwankwaso, tí kò sì tó láti dènà láti rìn sí ibi tó bá wù ú àyàfi tí wọ́n bá ṣe ìwádìí rẹ̀, tí ilé ẹjọ́ sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn náà.
Agbẹnusọ APC, Bala Ibrahim nínú ìròyìn iléeṣẹ́ The Punch júwe orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà bíi àmì ìṣèjọba àwaarawa, tí kò sì yẹ láti máa gbé ìgbésẹ̀ lórí àhesọ ọ̀rọ̀ lásán.
Bákan náà ni ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP júwe ìgbésẹ̀ àwọn aṣòfin Amẹ́rikà náà bí ìbanilórúkọ jẹ́ fún adarí àpapọ̀ ẹgbẹ́ wọn.
Níbi àpérò kan tí ẹgbẹ́ náà ṣe nílùú Abuja lọ́jọ́rú sọ pé ohun ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn láti ri pé Amẹ́ríkà fi orúkọ Kwankwaso sára àwọn tí wọ́n fẹ́ fi òfin dè.
Agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP, Ladipo Johnson sọ pé àwọn rí ìgbésẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí títẹ ẹ̀tọ́ ojú ẹni tí kò ní ìbáṣepọ̀ lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn mọ́lẹ̀.
Ó ní gbogbo bí Kwankwaso ṣe lo ìgbé ayé rẹ̀ ni àwọn èèyàn le rí nítorí ó hàn gbangba àti pé ó yẹ láti ṣe ìwádìí rẹ̀ kí wọ́n tó máa gbé ìròyìn jáde nípa rẹ̀.
Kí ni Amẹ́ríkà sọ?
Ní ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Kejì, ọdún 2026 ni aṣòfin ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Riley Moore kéde lójú òpó X rẹ̀ pé òun àtàwọn akẹgbẹ́ òun, Chris Smith, Brian Mast àti Bill Huizenga ti gbé àbá kan dìde láti kojú bí wọ́n ṣe ń pa àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ní Nàìjíríà.
Nínú àbá ọ̀hún làwọn aṣòfin náà ti ń bèèrè pé kí ìjọba Amẹ́ríkà kéde àwọn alájàngbilà ikọ̀ Fulani gẹ́gẹ́ bí agbéṣùmọ̀mí àgbáyé.
Bákan náà ni wọ́n pè fún fífi òfin de físà àti gbígbẹ́sẹ̀ lé dúkìá àwọn èèyàn tó fi mọ́ iléeṣẹ́ tí wọ́n bá ti kẹ́fín pé ó lọ́wọ́ lórí gbígbógunti àwọn ẹlẹ́sìn kan ní Nàìjíríà.
Lára àwọn tí wọ́n kéde pé wọ́n ń ṣe àtìlẹyìn fún ìkọlù tí wọ́n ń ṣe sáwọn Kristẹni ni gómìnà ìpínlẹ̀ Kano tẹ́lẹ̀ rí, Rabiu Kwankwaso àti ẹgbẹ́ Miyetti Allah Cattle Breeders Association of Nigeria.
Àbá náà tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní "Nigeria Religious Freedom and Accountability Act of 2026 (HR 7457)" ni èròńgbà wà pé yóò mú àlékún bá bí Amẹ́ríkà yóò ṣe kojú ìjà ìjà sáwọ tí ìgbàgbọ́ wà pé wọ́n ń gbógunti ẹlẹ́sìn Kristẹni ní Nàìjíríà.
Àwọn aṣòfin náà sọ nínú àbá ọ̀hún pé Nàìjíríà ló ń ṣokùnfà ikú ìdá méjìléláàádọ́rin àwọn Kristẹni tí wọ́n ń pa káàkiri àgbáyé gẹ́gẹ́ bí ìwádìí Open Doors' 2026 Watch List ṣe fi hàn.
Wọ́n ní láti ọdún 2009, àwọn Kristẹni tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ ìkọlù àwọn Boko Haram, ISWAP àti ikọ̀ alájàngbilà Fulani tit ó 50,000 sí 125,000, tí ṣọ́ọ̀ṣì ti wọ́n sì parun ti lé ní 19,000.
Àmọ́ ìjọba Nàìjíríà ti jiyàn pé àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi nìkan làwọn agbéṣùmọ̀mí ń ṣe ìkọlù sí ní Nàìjíríà, tí wọ́n sì sọ pé gbogbo èèyàn làwọn agbébọn àti agbéṣùmọ̀mí ń kọlù láì fi ẹ̀sìn tàbí ẹ̀yà ṣe.
Lára ohun tí àbá náà ń bèèrè fún ni pé:
- Kí ìjọba Amẹ́ríkà lo gbogbo ohun tó wà ní ìkápá rẹ̀ láti ri pé ìjọba Nàìjíríà fòpin sí ìpànìyàn àti pípa àwọn ẹlẹ́sìn kan tó ń wáyé.
- Dídá ààbò bo àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi àtàwọn ẹlẹ́sìn míì táwọn agbébọn ń dojú ìjà kọ
- Kí wọ́n ri dájú pé gbogbo èèyàn ní ìpele ìpele le ṣe ẹ̀sìn tó bá wù wọ́n àti pé gbogbo àwọn tó wà lẹ́wọ̀n látàrí ẹ̀sìn gba ìtúsílẹ̀.
- Kí ìjọba Amẹ́ríkà pẹ̀lú àjọṣepọ̀ ìjọba Nàìjíríà pèsè ohun amáyédẹrùn fáwọn ìpínlẹ̀ tó wà ní ààrin gbùngbùn tí ìkọlù yìí ti ń wáyé.
- Kí ìjọba Amẹ́ríkà fòfin de àwọn tó ń lọ́wọ́ tàbí ṣe àtìlẹyìn nínú ìkọlù lórí ẹ̀sìn tàbí kí wọ́n sọ ìdí tí wọn kò ṣe fòfin de àwọn ẹni náà fún ilé aṣòfin.
- Kí Amẹ́ríkà ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú ìjọba Nàìjíríà láti gbéná ìjà kojú àwọn ará ilẹ̀ China tó ń wa kùsà lọ́nà àìtọ́, kí wọ́n sì dènà wọn láti máa san owó fáwọn Fulani alájàngbilà fún ààbò lórí iṣẹ́ wọn.



























