Ọwọ́ ọlọ́pàá Kwara tẹ afurasí ajínigbé tó múra bíi oníbárà

Ọkunrin to wọ aṣọ alawọ ewe

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọwọ sinku awọn ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti tẹ afurasi ajinigbe kan ti o n ṣe bi ẹni pe onibara ni oun.

Ni ilu Igbaja ati ilu Olayinka ni ijọba ibilẹ Ifelodun ni Ipinlẹ Kwara ni iṣẹlẹ yii ti waye.

Ohun tí a mọ̀ rèé

Awọn ilu wọn yii si ni wọn wa ni arọwọto awọn ilu Babanla ati Oke-Ọdẹ ti ijinigbe ati ipaniyan ti jingiri lọdun to kọja.

Ni ọjọ Kejila, oṣu Keji ọdun 2026 ni iroyin gba ori ayelujara kan wi pe awọn ọlọpaa Kwara nawọ gan afurasi kan to n ṣe bii onibara.

Lẹyin ti ọwọ iya dun un, o jẹwọ ibi tii awọn iyoku rẹ farapa mọ si.

Ohun tí ọlọ́pàá sọ

Lẹyin ọpọ iwadii lati fidi Isẹlẹ yii mulẹ, ọlọpaa kan to bẹbẹ ki a fi orukọ bo oun lasiri nitori aabo iṣẹ rẹ sọ fun BBC News Yoruba bi iṣẹlẹ naa se waye.

O sọ pe, o ti to bii ọjọ mẹta bayii ti awọn ti mu afurasi to n ṣe bi onibara ko to ṣe atọna bi awọn ṣe ri awọn iyoku rẹ mu.

"Ilu Igbaja ni wọn ti rii to mura bii onibara, sugbọn ọkan lara awọn ẹsọ asọgbo lo daa mọ gẹgẹ bii agbodegba fun awọn ajinigbe, to si tuu lasiri.

"Afurasi naa ko mọ wi pe oju ti wa lara oun lati ẹyin wa.

"Lẹyin igba ti a mu un ti a si bẹrẹ iwadii, lo jẹwọ pe, bi ijọba ṣe n gbena woju awọn ni awọn abẹtẹ awọn lo mu ki awọn fọn si igboro."

Saaju ni ijọba ti fọn awọn ọmọ ogun si inu igbo, paapaa julọ, ni awọn ibuba wọn ti wọn wa ni Baba Sango ati Oro-Agọ lati le wọn jina rere si Ipinlẹ Kwara.

Ọlọpaa naa ṣalaye pe awọn ti ọwọ tẹ pọ sugbọn oun o le sọ boya gbogbo wọn ni ajinigbe, bayii ti iwadii n lọ lọwọ.

O fi kun un pe, awọn yoo se ọpọlọpọ iwadii ni Kwara titi de Abuja lati ri aridaju iṣẹlẹ naa.

O sọ pe lọgan ti iwadii ba ti pari ni awọn to jẹbi ọrọ naa yoo foju bale ẹjọ.

Titi di asiko ti a ko iroyin yii jọ, agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ejirẹ-Adetoun Adeyemi ko tii dahun ipe rẹ lori ẹrọ ibanisọrọ lati fesi si ọrọ yii.