Wo orílẹ́èdè mẹ́sàn án tí ìjọba ti fòfin de tàbí tí ó ti nira láti ṣe àyájọ́ ọjọ́ olólùfẹ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọ kẹrinla lọdọọdun lawọn eeyan kaakiri agbaye maa n ṣe ayajọ ọjọ awọn ololufẹ eyi tawọn oloyinbo n pe ni Valentine's Day.
Ayajọ naa bẹrẹ pẹlu awọn ọmọlẹyin Kristi nigba ti wọn maa n ranti agbaọjẹ kan ninu igbagbọ ti wọn n pe orukọ rẹ St. Valentine ẹni ti wọn gbagbọ wi pe o fi ifẹ han sawọn eeyan.
Bi ayẹyẹ ase onigbagbọ ti wọn fi sọri Papa Mimọ Valentine ni wọn maa n kọkọ n ṣe lọdọọdun tẹlẹ.
Kẹrẹ kẹrẹ ni ayẹyẹ ayajọ ọjọ ololufẹ di nnkan ti ogunlọgọ eeyan n ṣe lọdọọdun kaakiri agbaye.
Bo tilẹ jẹ pe ọjọ kẹrinla oṣu Keji kii ṣe ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ ni ọpọ orilẹede, ọpọ lo ti ya ọjọ naa sọtọ lati fifẹ han si ololufẹ wọn kaakiri agbaye.
Ṣugbọn kii ṣe gbogbo orilẹede naa lo faye gba ṣiṣe ayajọ ọjọ ololufẹ yii.
Wọnyii lawọn orilẹede ti ko faye gba siṣe ayajọ ọjọ ololufẹ ni gbangba tabi to fofin de ṣiṣe ayajọ ọjọ naa:
Russia
Orilẹede Russia kii ṣe ayajọ ọjọ ololufẹ lọjọ kẹrinla oṣu Keji lọdọọdun bawọn orilẹede yooku nilẹ Yuroopu ṣe maa n ṣe.
Dipo ayajọ ọjọ ololufẹ, ọjọ kẹjọ oṣu Kẹta to jẹ ayajọ awọn obinrin lagbaaye ni orilẹede Russia maa n ṣe.
Lọjọ yii lawọn ọkunrin maa n fawọn obinrin ni ododo to rẹwa atawọn ẹbun mii.
Gbogbo ọjọ kẹjọ oṣu Kẹta ọdọọdun yii ni awọn ọkunrin maa n fi n ṣe imọyi fawọn obinrin ni Russia.
Iran
Ijọba orilẹede Iran tako ṣiṣẹ ayajọ ọjọ awọn ololufẹ, wọn ni aṣa awọn oyinbo ni.
Ni ọpọ igba ni ijọba ti kilọ fawọn oniṣowo wi pe ki wọn ma ta ẹbun fun ayajọ ọjọ ololufẹ mọ.
Amọ, a gbọ pe awọn ile itaja kan niluu Tehran si maa n yọ ọja ta fun ayajọ ọjọ awọn ololufẹ.
Amọ, ijọba Iran ko gbọdọ mọ pe awọn kan n yọ iru ọja bẹẹ ta.
Indonesia
Loootọ ni orilẹede Indonesia ko si fun ẹsin kan, amọ, ijọba ẹkun Aceh to jẹ ẹkun ti wọn ti n tẹle ofin Islam ti fofin de ṣiṣe ayajọ ọjọ awọn ololufẹ.
Ọpọ olori ẹsin lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu ọjọ awọn ololufẹ, wọn ni ihuwasi awọn eeyan lọjọ naa tako ofin ẹsin islam.
Amọ, awọn eeyan si maa n ṣe ayajọ naa lawọn ilu mii bii Jakarta lorilẹede Indonesia.
Malaysia
Awọn olori ẹsin ni orilẹede Malaysia ti sọ pe ṣiṣe ayajọ ọjọ ololufẹ tako ofin ẹsin islam.
Awọn musulumi ko ida mọkanlelọgọta ninu ida ọgọrun un awọn eeyan to wa ni orilẹede naa.
Lati ọdun 2005 ni wọn ti sọ pe kawọn musulumi ma ṣe ayajọ ọjọ awọn ololufẹ naa mọ.
Lọdun 2011, ko din ni ọgọrin tọkọ taya tawọn ẹṣọ eleto aabo mu lori ẹsun pe wọn n ṣe ayajọ awọn ololufẹ.
Pakistan
Ọrọ ṣiṣe ayajọ ọjọ awọn ololufẹ ti da wahala silẹ fun ọpọ ọdun lorilẹede Pakistan.
Rogbodiyan bẹ silẹ lọdun 2014 laarin awọn akẹkọọ ni Peshawar lori ṣiṣe ayajọ ọjọ awọn ololufẹ.
Eyi lo jẹ ki ile ẹjọ giga Islamabad fofin de ṣiṣe ayajọ ọjọ awọn ololufẹ ni Pakistan lọjọ keje oṣu Keji ọdun 2018.
India
Lọdun 1947 ni orilẹede India gbominira lọwọ Ilẹ Gẹẹsi, amọ, ọpọ lo ti koro oju si awọn aṣa kan to jẹ aṣa awọn oyinbo.
Ninu iru aṣa bayii ni ṣiṣe ayajọ ọjọ awọn ololufẹ wa.
Ọpọ le maa ṣe ayajọ ọjọ awọn ololufẹ lawọn ilu nla ni India, amọ, ẹgbẹlẹgbẹ awọn ọmọ ilẹ naa ni wọn koro oju si i.
Qatar
Wọn kii ṣe ayajọ ọjọ awọn ololufẹ ni gbangba bi wọn ṣe maa n ṣe e lawọn ilu oyinbo.
Ọpọ le maa ṣe ayajọ ọjọ awọn ololufẹ fun ra wọn, amọ, ko wọ pọ kawọn eeyan maa daawọ ọjọ ayajọ awọn ololufẹ ni gbangba.
Somalia
Awọn eeyan orilẹede Somalia naa kii saba ṣe ayajọ ọjọ awọn ololufẹ.
Aṣa ati ẹsin islam ni kii faye gba ọpọ eeyan lati ṣe ayajọ ọjọ awọn ololufẹ bo ti wu wọn.
Nitori naa, ọjọ kẹrinla oṣu Keji kii ṣe ọjọ kan pataki lorilẹede naa.
Saudi Arabia
Ijọba ko faye gba ṣiṣe ayajọ ọjọ awọn ololufẹ ni gbangba lorilẹede Saudi Arabia.
Awọn alaṣẹ orilẹede naa ti kilọ ṣaaju pe kawọn eeyan ma ta ododo fun ayajọ ọjọ awọn ololufẹ mọ.
Iroyin kan fidi rẹ mulẹ pe awọn ọmọbibi Saudi marun un lọdun 2014 ni wọn ri ẹwọn he ti wọn si tun lu wọn lẹyin ti ọwọ tẹ wọn nibi ti wọn ti n jo pẹlu awọn obinrin ti kii ṣe iyawo wọn lọjọ ayajọ awọn ololufẹ.



























