Àlàyé lórí ìdí tí àjọ NSCDC Ondo ṣe lo ìwà ipá pẹlu obìnrin tó pọnmọ sẹ́yìn àti ọkọ rẹ lórí ọ̀rọ̀ títa afẹ́fẹ́ gáàsì

Àkọlé fídíò, Àlàyé lórí ìdí tí àjọ NSCDC Ondo ṣe lo ìwà ipá pẹlu obìnrin tó pọnmọ sẹ́yìn àti ọkọ rẹ lórí ọ̀rọ̀ títa afẹ́fẹ́ gáàsì
Àlàyé lórí ìdí tí àjọ NSCDC Ondo ṣe lo ìwà ipá pẹlu obìnrin tó pọnmọ sẹ́yìn àti ọkọ rẹ lórí ọ̀rọ̀ títa afẹ́fẹ́ gáàsì

BBC Yoruba ti lọ siluu Akure, nipinlẹ Ondo, nibi ti iṣẹlẹ ipa laarin awọn oṣiṣẹ ajọ NSCDC ati idile kan ti wọn n ta gaasi lagbegbe Saitn Luke, niluu naa ti waye.

Ṣaaju ni fidio bi awọn oṣiṣe NSCDC ṣe n fi ipa wọ ọkunrin to n ta gaasi ọhun, Balogun Alaba, lati fi ṣikun mu.

Lẹyin fidio naa ni ọpọ araalu binu, ti wọn si bẹrẹ si n bu ẹnu atẹ lu awọn oṣiṣe NSCDC ọhun.

Nigba ti BBC Yoruba kan si ọgbẹni Alaba, o ni ọrọ lori iwe aṣẹ gaasi tita naa, DPR, lo fa gbas-gbos laarin awọn ati oun.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye fun wa, o ni awọn oṣiṣẹ panapana ti kọkọ maa n yọ oun lẹnu tẹlẹ ti wọn yoo si gba owo lọwọ oun ki awọn oṣiṣẹ NSCDC to tun bẹrẹ ti wọn.

O ṣalaye pe owo lemọlemọ ti wọn n gba lọwọ oun naa ti pọ ju lai ṣalaye bi oun ṣele ri ri iwe ẹri DPP ti wọn n bere naa gba.

O ni idi ree ti oun fi yari mọ wọn lọwọ lasiko ti wọn n ko awọn ẹru inu ṣọọbu oun.

Ninu ọrọ rẹ, o ni wọn pada gbe silinda 50kg inu sọọbu naa lọ lẹyin ti wọn fi iya jẹ oun tan pẹlu afẹfẹ gaasi ti wọn fẹ si oun loju.

Nigba ti iyawo rẹ Adenike n ba wa sọrọ, o ni wọn ṣe oun leṣe lọwọ, wọn si fi iya jẹ oun ati ọkọ oun.

Lẹyin naa lo ke si ijọba ko ma jẹ ki iya naa jẹ awọn gbe.

Wọn maa jẹjọ ti wọn ba gba owo - Ọga agba NSCDC l'Ondo

BBC Yoruba tun kan si Ibiloye Oluyemi, to jẹ ọga agba ajọ NSCDC nipinlẹ Ondo.

Ibiloye sọ pe iṣẹ ti wọn ran awọn oṣiṣẹ naa lọ ṣe ko gba ki wọn gba owo lọwọ awọn ti ọrọ naa kan.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn oṣiṣe naa yoo foju bale ẹjọ ti ẹri ba wa pe wọn gba owo lọwọ idile naa ṣaaju.

O tun sọ pe iwadii ti n lọ lọwọ lori ọrọ naa lati mọ igbesẹ to kan.

Ẹwẹ, onimọ nipa ọrọ ayika kan, Henry Olonimoyo ti sọ pe o yẹ ki ẹnikẹni to ba fẹ maa ta gaasi gba aṣẹ lọwọ ijọba ko to bẹrẹ iṣẹ ọhun.

Wo fidio yii fun ẹkunrẹrẹ alaye.