Seyi Makinde sọ Baálẹ̀ mẹ́rìnlá di ọba aládé l'Oyo

Gomina Seyi Makimde

Oríṣun àwòrán, Gov. Seyi Makinde/ Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Onimo ero Seyi Makinde tí ṣe agbega ipò fún àwọn baalẹ mẹ́rìnlá nílùú Oyo nípa sísọ wọn di ọba aládé.

Ọjọ́ Etí, òjò ketala oṣù Kejì ọdún 2026 yii ni Gómìnà Makinde sọ àwọn baálé náà di ọba, níbi ayẹyẹ tó wáyé ní Oliveth Heights, níjọba ìbílẹ̀ Ìwọ Oorun Oyo.

Igbakeji gomina Oyo, Bayo Lawal to soju fún Makinde lo gbe ọ̀pá àṣẹ fún àwọn baalẹ tó di ọba náà.

Awọn baalẹ tijọba Oyo sọ di ọba náà ree:

Alaaguo ti Aguo, Oba David Oyediran; Baba Eyaji Oyo, Oba Afonja Mukaila; Alajagba Oyo, Oba Samuel Odurinde; Ona-Isokun tí Oyo, Oba Isiaka Tella-Titiloye; Onimileke ti Imileke, Oyo, Oba Fakayode Alowonle; Onigbudugbu ti Gbudugbu, Oyo, Oba Salawu Oyeniran; Oloodu ti Ojongbodu, Oba Olaniyi Adegboye; ati Alapa-Ara ti Apa-Ara, Oba Tijani Ajeigbe.

Awon yoku ni:

Onidode ti Idode, Oba Oyeleke Yusuff; Samu Oyo, Oba Lamidi Jimoh; Alago-Oja ti Ago-Oja, Oba Ganiyu Busari; Agbaakin Oyo, Oba Asimiyu Jimoh; Alakeitan tí Akeitan, Oba Jimoh Oyeleye ati Elepe ti Iseke, Oba Abel Oyekan.

Nínú ọ̀rọ̀ Gómìnà Makinde, ó ní igbega tó dé ba awon baalẹ tó di ọba yìí fi hàn bí ijoba ipinle Oyo ṣe feran isembaye àti asa tó, tó sì ń bọ̀wọ̀ fún ìjọba ìbílẹ̀ nípa mímú àlàáfíà àti idagbasoke wáyé lẹsẹkuku tó sunmo aráàlú julo.

Makinde kí àwọn ọba tuntun náà kú oriire.

O ní bí wọn ṣe di ọba fi jíjẹ asiwaju rere hàn, ó sì tún tọ́ka sí bijọba oun se ká ipò ọba ibile si tó.

'Mo fẹẹ rọ gbogbo eyin ọba yìí láti máa gbé òtítọ́ àti ìwà ọmọlúwàbí ga fáwọn eeyan yín.

" Kí won mo ìgbà yín fún àlàáfíà, kí wọ́n nípa nínú ìjọba yín, kí wọ́n sì rí atileyin ijoba gba ninu awon eto ti yoo tún ìgbésí ayé aráàlú ṣe láàyè won."

Gómìnà Makinde lo sọ bẹẹ.

O ni ipo ọba ilẹ Yoruba ko kéré nilẹ Africa, ọkan lára àwọn ipò tí ọ̀wọ̀ wá fún julọ to sì ti pẹ ní.

Makinde sọ pé bẹẹ lo ṣí wa nínú ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo titi doni.