Àwọn gbajúmọ̀ t'áwọn ọmọ Naijiria wá ìròyìn nípa wọn jùlọ lórí Google lọ́dún 2025

Oloogbe Muhammadu Buhari, Sẹnẹtọ Natasha Akpoti-Udughan, Mr Eazi ati oloogbe Diogo Jota

Oríṣun àwòrán, Getty Images/X/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Atẹ igbọrọkaye Google ti kede awọn gbajumọ tawọn ọmọ Naijiria wa iroyin nipa wọn julọ lori itakun naa lọdun 2025.

Atẹjade naa ṣafihan oniruuru isọri awọn eeyan bi awọn oloṣelu, awọn gbajugbaja olorin, awọn oṣere atawọn isọri mii tawọn ọmọ Naijiria wa iroyin nipa wọn lọdun 2025.

Ninu awọn eeyan tawọn ọmọ Naijiria wa iroyin julọ nipa wọn lori Google ni Sẹnẹtọ Natasha Akpoti-Uduaghan, bebi Labubu, Achalugo to wa ninu ere ''Love In Every Word,'' Mr Eazi to ṣe igbeyawo pẹlu Temi ọmọbinrin gbajugbaja oniṣowo n ni, Femi Otedola.

Iku awọn eeyan bii Aarẹ Muhammadu Buhari, agbabọọlu Liverpool to doloogbe, Diogo Jota ati ọmọ Amẹrika Charlie Kirk wa lara awọn iroyin tawọn ọmọ Naijiria wa julọ lori Google.

Foonu iphone 17 ati idije Club World Cup naa wa lara awọn iroyin tawọn eeyan fẹ ka julọ lọdun 2025.

Sẹnẹtọ Natasha wa lara awọn oloṣelu tawọn ọmọ Naijiria wa iroyin nipa wọn julọ.

Faakaja to ṣẹlẹ laarin rẹ ati Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba l'Abija, Sẹnẹtọ Godswill Akpabio lo jẹ ki ọpọ eeyan fẹ ka nipa Natasha.

Awọn ọmọ Naijiria tun wa iroyin nipa ọrọ ogun to bẹ silẹ laarin Israel ati Iran to fi mọ eto idibo orilẹede Amẹrika.

Awọn eeyan tun wa awọn ọrọ kan bii nepo, Ozempic atawọn ọrọ mii

Bakan naa ni wọn tun wa iroyin nipa awọn foonu bii Techno Pop 10, Straw and Redmi 14C, Pop 10 ati iphone 17.

Awọn eeyan tun wa iroyin lori Google nipa bebi ''Labubu,'' Achalugo atawọn nnkan mi lọdun 2025.

Orin Oluwatosin ti Tkeyz ati Stevehills kọ lo leke awọn orin tawọn ọmọ Naijiria wa iroyin nipa rẹ julọ lọdun 2025.

Lẹyin rẹ lo kan fidio orin ''Joy Is Coming'' ti Davido ati Lay jọ gbe jade.

Orin Shallipopi, Laho ati orin My Darling ti Chella kọ naa gbajugbaja ninu orin tawọn eeyan fẹ mọ nipa rẹ lọdun 2025.

Awọn eeyan tun wa awọn eroja ounjẹ ti wọn fẹ se lori Google lọdun 2025.

Oriṣii isọri awọn nnkan tawọn ọmọ Naijiria wa iroyin nipa wọn julọ lori Google lọdun 2025:

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Isọri iroyin

Idije ife ẹyẹ agbaye fawọn ikọ agbabọọlu (Club World Cup)

Diogo Jota

Buhari

Charlie Kirk

Iphone 17

Awọn gbajumọ ọmọ Naijiria

Natasha Akpoti

Eberechi Eze

Fubara

Chika Ike

Mr Eazi

Gbajumọ lagbaaye

Gyokeres

Garnacho

Joao Pedro

Aaron Pierre

Tyler Perry

Awọn gbajumọ elere idaraya

Gyokeres

Garnacho

Xavi Simons

Sesko

Mbeumo

Gbajumọ oṣere

Aaron Pierre

Chika Ike

Juma Jux

Mr Eazi

Kemi Adetiba

Awọn to ti doloogbe

Diogo Jota

Buhari

Charlie Kirk

Pope Francis

Hulk Hogan

Ọrọ ati itumọ

Itumọ Achalugo

Itumọ Allegedly

Itumọ Labubu

Itumọ Kelebu

Itumọ Demure

Ibeere

Ta ni Charlie Kirk?

Ta ni Seyi Vodi?

Ta ni Poopu tuntun?

Ta ni Tompolo?

Ki ni Labubu?

Eroja ounjẹ

ERoja Martini

Eroja atalẹ

Eroja Chinchin

Eroja Sausage Roll

Eroja Hummus

Orin

Orin With You ti Davido ati Omah Lay gba jade

Orin Oluwatosin

Orin Xxxtentacion

Fidio orin Joy Is Coming

Orin Favour It Surrounds Me Like A Shield

Ere

Ere Wednesday Season 2

Ere Squid Game

Ere Squid Game Season 2

Ere Bon Appetit Your Majesty

Ere Koleoso

Ere

Ere Straw

Ere Sinners

Ere Love In Every Word

Ere To Kill A Monkey

Ere G20 Movie

Foonu

Iphone 17

Tecno Pop 10

Pop 10

Straw

Redmi 14c