Ààrẹ lẹ́tọ̀ọ́ láti kéde ìjọba ìlú-o-rọgbọ, yọ gómìnà àtàwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ nípò - ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ

Oríṣun àwòrán, Asiwajubolatinubu/x
Ile ẹjọ toga julọ lorilẹede Naijiria ti gbe idajọ kalẹ pe aarẹ ni aṣẹ lati kede ijọba ilu-o-fararọ, ni ipinlẹ yoowu lati dena wahala tabi hilahilo nibẹ.
Ninu idajọ ti awọn adajọ meje to joko gbọ ẹjọ naa gbe kalẹ, mẹfa ninu wọn dajọ gbe ẹtọ aarẹ lẹyin ti ọkan yooku si tako, ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria woye pe lasiko ijọba ilu o rọgbọ, aarẹ le ni ki awọn adari ti ilu dibo yan lọ rọọkunnile, amọṣa irufẹ igbesẹ bẹẹ ko gbọdọ ju iwọnba akoko kan lọ.
Ninu idajọ olubori to gbe kalẹ, Onidajọ Mohammed Idris gbe idajọ kalẹ pe abala karunlelọọdunrun iwe ofin Naijiria ro aarẹ lagbara latigbe igbesẹ to ba yẹ lati da alaafia pada si ibikibi ti wọn ba ti kede ijọba ilu o rọgbọ.
Onidajọ Mohammed Idris ni abala naa ko sọ ọ ni san an iru igbesẹ to le gbe, eleyii to tipasẹ bẹẹ fun aarẹ lagbara lati lo ọna yoowu to ba fẹ gẹgẹbi eyi to ri pe yoo tọna fun ohun to wa nilẹ.
Ipinlẹ Adamawa atawọn ipinlẹ mẹwaa kan ti ẹgbẹ oṣelu PDP n ṣakoso lorilẹede Naijiria lo pe ẹjọ naa tako ẹtọ ti Aarẹ Tinubu ni lati kede ijọba ilu o rọgbọ ni ipinlẹ Rivers ninu eyi ti aarẹ ti ni ki gbogbo awọn ti wọn dibo yan fun akoso ijọba ipinlẹ naa, titi kan Gomina Fubara lọ rọ̀ọ̀kun nile.










