Èmi ni máa borí ìbò Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun pẹ̀lú olùdíje APC Oyebamiji - Adeleke

Gomina Ademola Adeleke aṣọ buba funfun pẹlu fila olomi ọsan, Oludije sipo gomina f'ẹgbẹ òṣèlú APC Ajibola Oyebamiji wọ aṣọ buluu pẹlu fila lori

Oríṣun àwòrán, Senator Nurudeen Jackson Ademola Adeleke

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gomina Ademola Adeleke ipinlẹ Osun ti kede wi pe oun loun maa jawe olubori ninu eto idibo ipinlẹ naa ti yoo waye lọdun 2026.

Adeleke ni o da oun loju pe oun yoo la oludije ẹgbẹ oṣelu APC, Sẹnẹtọ Ajibola Oyebamiji mọlẹ ninu eto idibo naa.

Gomina fi ọrọ yii lede loju opo Facebook rẹ lọjọ Aiku ọjọ kẹrinla oṣu Kejila yii.

''Ẹyin eeyan mi nipinlẹ Osun, mo fẹ fi daa yin loju pe a ti ṣetan lati ri wi pe ẹgbẹ oṣelu APC yoo fidi rẹmi ninu eto idibo ọdun 2026 to n bọ.

Lagbara Ọlọrun ati atilẹyin awọn eeyan, mo maa bori Oyebamiji ninu eto idibo naa lati le tẹsiwaju awọn iṣẹ ti ijọba mi n ṣe.

Gbogbo nnkan ti gomina to ṣaaju mi to ti di minisita bayii sọ ni mo gbọ pata pata, mo fẹ fi daa yin loju pe irọ nla lọrọ to sọ wi pe APC ni yoo jawe olubori.

Awọn eeyan wa nipinlẹ Osun ko gba ti ẹgbẹ oṣelu APC mọ, ko si nnkan ti wọn le ṣe to le yi eleyii pada,'' Gomina Adeleke ṣalaye.

Gomina Adeleke ni asiko to buru jai ninu itan ipinlẹ Osun ni asiko ti ẹgbẹ oṣelu APC wa nijọba.

Adeleke ni ọrọ aje ipinlẹ Osun dẹnu kọlẹ nigba toun di gomina lọdun 2022, nitori eto iṣejọba ti ko dara.

O ni idaji owo oṣu ni ijọba n san fawọn oṣiṣẹ nigba naa, nigba ti gbese si pọ nilẹ rẹpẹtẹ lati san.

''Ifasẹyin ni ẹnikẹni to ba dibo fun APC lọdun to n bọ yoo mu ba ipinlẹ Osun''

Gomina ni awọn eeyan ipinlẹ Osun ko ṣetan lati pada si iru asiko bayii mọ.

Adeleke ni ''dipo ki a maa lo awọn nnkan ti a ṣe lati ṣe ipolongo ibo fun araalu, ọna ti ko ba ijọba awarawa mu ni APC n tọ.

Emi maa n sọ fun wọn pe ti o ba dawọn loju pe awọn araalu n fẹ wọn, ki lo de ti ẹru n bawọn lati jẹ ki eto idibo lọ ni irọwọ rọsẹ?'' Adeleke lo beere bẹẹ.

Gomina sọ pe awọn araalu ti n jẹ igbadun ijọba gidi to wa lode bayii, pẹlu bi ijọba oun ti mu igbayegbadun awọn oṣiṣẹ, ipese ohun amayedẹrun, eto iwosan alabọde atawọn eto miran ni ọkunkundun.

O ni awọn eeyan ipinlẹ Osun ti sọ pe ijọba to wa lode tẹ awọn lọrun, ati pe ko sẹni to fẹ pada si asiko ijọba APC nipinlẹ Osun mọ.

Gomina ni ijọba oun si n ṣe atunṣe ọpọ nnkan to ti bajẹ lati ẹyin wa.

Adeleke ni gbogbo araalu lo mọ pe ifasẹyin ni ẹnikẹni to ba dibo fun APC lọdun to n bọ yoo mu ba ipinlẹ Osun.