Ìtàn tó rọ̀ mọ́ òwe 'aṣọ kò bá Ọ́mọ́yẹ mọ́...' rèé

Ọkunrin to wa ninu ọgba ẹwọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Awọn baba nla wa nilẹ Yoruba jẹ ọlọpọlọ pipe, ti ori wọn kun fun ọgbọn ati oye.Oniruuru nlkan si ni wọn fi maa n se akawe ọrọ bii owe, akanlo ede, afiwe ati awọn isẹlẹ miran to kọ ni lọgbọn.

Ọkan ninu awọn isẹlẹ to kọ ni lọgbọn, ti wọn sọ di owe, to si di ohun manigbagbe ni itan kan to nii se pẹlu Ọmọyẹ ati ọmọ iya rẹ.

Itan naa si lo di owe, ti wọn fi n sọ pe "Asọ ko ba Ọmọyẹ mọ, Ọmọyẹ ti rin ihoho wọja."

Niwọn igba to jẹ pe bi ọmọ ko ba ba itan, yoo ba arọba, tii se baba itan, itan Ọmọyẹ yii lo ni ọpọ ọgbọ ati oye ninu, paapa fun itọni awọn ọdọ iwoyi, ti ko si yẹ ka ma mọ itumọ owe naa.

Niwọn igba to jẹ pe bi ọmọ ko ba ba itan, yoo ba arọba, tii se baba itan, itan Ọmọyẹ yii lo ni ọpọ ọgbọ ati oye ninu, paapa fun itọni awọn ọdọ iwoyi, ti ko si yẹ ka ma mọ itumọ owe naa.

Bi itan naa se lọ ree:

Obinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Iyalufa lo n gbe ni ilu kan laye atijọ, eyi ti wọn n pe ni Ijaye, obinrin yii ati ọkọ rẹ ti pinya nitori aawọ ti ko ni ojutu, ti onitọun si ti fẹ iyawo miran si agbegbe Ibarapa, ti Iyalufa si n da gbe pẹlu awọn ọmọ rẹ.

Iyalufa bi ọmọbinrin meji, ọkan n jẹ Ọmọyẹni nigba ti ekeji si n jẹ Ọmọlufa, ti wọn mu lati ara orukọ iya rẹ.

Ọmọyẹni lo jẹ aburo fun Ọmọlufa, agba naa kii si se agba kan to pẹ lọ titi, tori ọdun meji pere ni wọn gba lọwọ ara wọn.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹgẹ bii obinrin to n da gbe, Iyalufa n ko ba oju, to si n ko ba imu lati ri daju pe ile aye dun gbe fawọn ọmọ rẹ mejeeji.

O fẹ ki wọn lee jẹ oloriire lọjọ ọla, sugbọn gbogbo aayan obinrin yii lo so eso rere lori Ọmọlufa, to si ja si pabo lori Ọmọyẹni.

Ọmọlufa jẹ onirẹlẹ obinrin, o ni itẹriba, to si maa n gba imọran iya rẹ amọ onijagidi jagan ẹda, olori kunkun, alailẹkọ ati onipanle eniyan ni aburo rẹ, to n jẹ Ọmọyẹni, eyi ti apekuru rẹ n jẹ Ọmọyẹ.

Bi ọjọ ti n gori ọjọ, ti oṣu n gori oṣu, awọn ọmọbinrin mejeeji yii n dagba, wọn n to oju bọ, ti wọn si to ẹni to n yan isẹ ati okoowo ti wọn yoo se laayo.

Ọmọlufa yan iṣẹ agbẹ laayo, to si di agbẹ paraku, to ni oko nla, ti kii si ṣe imẹlẹ, ọwọ rẹ ji sowo, iṣu rẹ n ta, agbado rẹ n yọ ọmọ bọkua-bọkua, to si n fi owo, ounjẹ ati aṣọ kẹ iya wọn.

Ṣugbọn Ọmọyẹ, to jẹ aletilapa ọmọ ko kuku yan iṣẹ aayan laayo kan ni pato, ọlẹ, alapa-masisẹ ni, to si n ti ile ọkunrin kan bọ si omiran lai jẹ pe wọn fẹ sile nisu-lọka.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Asẹyinwa-aṣẹyinbọ, Ọmọyẹ, to ti balaaga to ẹni ọdun ogun ọdun ri oyun apete he, lo ba loyun oge, kẹtẹkẹtẹ ba ku, ni iso ba pin.

Yoruba ni bi eegun ẹni ba jo re, ori a maa ya atọkun rẹ.

Inu Iyalufa n dun si ọpọ aseyọri Ọmọlufa amọ ibanujẹ nla lo n dori agba rẹ kodo lori ọrọ Ọmọyẹ.

Lẹyin osu mẹsan ti Ọmọyẹ ti fi inu se oyun lai ri ẹni gba lọwọ rẹ, o papa fi ẹyin gbe ọmọ pọn, o ru re, to si tun sọ re.

Gẹgẹ bii aṣa iran Yoruba, Iyalufa n tọ Ọmọyẹ sọna lori awọn ọna ti yoo gba se abiamọ, ti yoo fi tọju ọmọ rẹ bo se yẹ ati awọn eewọ to rọ mọ itọju ọmọ.

Lara awọn eewọ ti Iyalufa ka fun Ọmọyẹ ni pe, iya ko gbọdọ pọn ọmọ rẹ sẹyin, ki ọmọ naa si jabọ lẹyin iya rẹ, bi eyi ba si ri bẹẹ, iya naa gbọdọ sare ni ihoho ọmọluabi wọ inu ọja ni kia-kia,were-were.

Àkọlé fídíò, HL;AFAFAFAFAFAFAFAFK

Bi bẹẹ kọ, ọkọ meje ni yoo ku mọ ọmọ naa lori, eyiun to ba jẹ obinrin, amọ ti ọmọ naa ba jẹ ọkunrin, aya meje ni yoo ku mọ ọmọkunrin naa lori to ba dagba tan.

Iyalufa kan sọ eewọ yii, gẹgẹ bi awọn agba atijọ ti maa n se lati dẹru ba awọn majesin, ki wọn ma ba a hu awọn iwa kan ni, ti Ọmọyẹ ko si mọ pe ẹru lasan ni ọrọ naa.

Wọn ni ọrọ agba bi ko sẹ lowurọ, yoo sẹ lọjọ alẹ.

Nigba to di ọjọ kan, ṣaa deede ni ọja ti Ọmọyẹ fi pọn ọmọ rẹ sẹyin ba tu lojiji laimọ nibi to ti bẹrẹ mọlẹ, to n fọ asọ.

Ọmọ naa jabọ lẹyin Ọmọyẹ, to si fi ori gba ilẹ.

Ọmọde yii bu sẹkun, ti ẹkun rẹ si gbalẹ. Igbe ẹkun yii ni Iyalufa gbọ ninu ile to wa, to si sare jade lati wa wo ohun to n sẹlẹ si ọmọ naa.

Ọmọyẹ bu sẹkun, to si sọ fun iya rẹ pe Ṣangba ti fọ, ọmọ oun ti jabọ lẹyin oun.

Iya rẹ binu gidigidi si i, to si gba ọmọ naa lọwọ Ọmọyẹ, pe ki oun lọ fi ẹrọ wọ ọ ni gbogbo ara ninu ile, ki ara ma ba a ro ọmọ naa, paapaa ori to fi gbalẹ.

Àkọlé fídíò, bbbbbbbbbbbbbbbbbbbb

Bi Iyalufa ṣe n pẹyinda lati wọnu ile, ni Ọmọyẹ bẹrẹ si ni bọ asọ lara titi to fi wa ni ihooho ọmọluabi, to si ki ere mọlẹ, to n sare lọ sinu ọja to sun mọ adugbo wọn.

Bi Iyalufa ti ri ohun ti Ọmọyẹ se yii, lo ranti eewọ ijọsi ti oun ka fun Ọmọyẹ, ipa to lee ni ati ọna abayọ, ni oun naa ba sare mu iro ti Ọmọyẹ bọ silẹ, to si n sare lee lọ si aarin ọja, toun tọmọ lọwọ.

Bo ṣe n lo n pariwo pe, "ẹ ba mi mu Ọmọyẹ, ko duro fi aṣọ sara, ẹru lasan ni mo da ba a pẹlu eewọ naa, ẹ jọwọ, ẹ ma jẹ ki Ọmọyẹ rin ihooho wọ ọja."

O pẹ diẹ ki Iyalufa to pade ẹnikan to n ti ọja naa bọ, to si beere pe ṣe o ba oun ri Ọmọyẹ lọna ọja ni ihooho, tori oun fẹ fun un lasọ ti yoo fi bo ihooho rẹ ni.

Onitọhun se haa, to si da Iyalufa lohun pe, "ASỌ KO BA ỌMỌYẸ MỌ, ỌMỌYẸ TI RIN IHOOHO WỌ ỌJA."

Lati ọjọ naa si ni wọn ti maa n fi isẹlẹ yii pa owe fun ohun to ba ti kọja atunṣe, to ti bọwọ sori, ti ko si ni ojutu mọ.