Ilé ìfowópamọ́ yóò máa bèèrè káàdì owó orí láti oṣù tó ń bọ̀, ìdí abájọ rèé

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu/X
Awọn ile ifowopamọ ní Naijiria yoo maa beere kaadi owo ori sisan lati ọjọ kinni oṣu Kinni ọdun 2026 to n bọ.
Alaga igbimọ ileeṣẹ aarẹ to n ri si àtúnṣe owo ori sisan, Taiwo Oyedele lo fọrọ yii lede loju opo X rẹ.
Oyedele ni eyi yoo bẹrẹ ni kete ti orilẹede Naijiria ba ti bẹrẹ sii lo ofin owo ori tuntun.
Oyedele sọ pe abala kẹrin ofin owo ori tuntun Naijiria fidi rẹ múlẹ pe kaadi owo ori sisan ti di dandan fun gbogbo awọn to ba yẹ ki wọn maa sanwo ori.
Ṣugbọn o salaye siwaju si pe eyi ko k'awọn akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn eeyan ti won n bọ.
Oyedele sọ pe eyi ti wa ninu ofin Naijiria lati ọdún 2020, amọ, àtúnṣe tun ṣẹṣẹ waye lori rẹ ni.
O fikun ọrọ rẹ pe awọn to ba ti ni nọmba owo ori sisan tẹlẹ ko nilo kaadi owo ori mọ.
Ọgbẹni Oyedele sọ pe ẹnikẹni ti ko ba ni Kaadi owo ori yoo ni ìyọnu pẹlu akaunti banki rẹ.
O ni ìjọba le gbẹsẹ le akaunti awọn eeyan ti ko ba ni Kaadi owo ori sisan lati oṣù Kínní ọdún 2026.
Oyedele ko sai fidi rẹ múlẹ pe oríṣìíríṣìí ahesọ ọrọ lawọn eeyan kan ti n gbe kiri lori ofin owo ori tuntun.
Amọ, Oyedele ni ofin owo ori tuntun yii yóò jẹ ki okowo dun un ṣe ni Nàìjíríà















