Àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà mọ́kànlá tó há sí Burkina Faso gba ìtúsílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Yusuf Tuggar/X
- Author, Annette Arotiba
- Author, Nicholas Négoce
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Àwọn ọmọ ogun ojú òfurufú Nàìjíríà mọ́kànlá tí wọ́n há sí orílẹ̀ èdè Burkina Faso lẹ́yìn tí ọkọ̀ iléeṣẹ́ ológun C-130 balẹ̀ síbẹ̀.
Àtẹ̀jáde kan tí Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè, Yusuf Tuggar fi sójú òpó X rẹ̀ ní àwọn ọmọ ogún náà ti mórílé orílẹ̀ èdè Portugal tí wọ́n ń lọ gangan tẹ́lẹ̀ kí wan tó ní ìdádúró.
Tuggar ní àwọn ológun náà ti balẹ̀ sí pápákọ̀ òfurufú Accra ní Ghana lẹ́yìn tí àwọn aláṣẹ orílẹ̀ èdè Burkina Faso fún wọn láàyè láti kúrò níbẹ̀.
Ṣáájú ni ikọ̀ kan tí Mínísítà Tuggar kó sòdí ṣe ìrìnàjò lọ sí Ouagadougou láti lọ jíròrò pẹ̀lú Ààrẹ Ibrahim Traore lórí àwọn ọmọ ogun náà.
Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni àwọn aláṣẹ ẹkùn Sahel sọ pé àwọn ń ṣe ìwádìí lórí ohun tó fa ìdí táwọn ọmọ ogun náà fi balẹ̀ sí orílẹ̀ èdè Burkina Faso àti pé àwọn máa mọ ohun tí àwọn máa ṣe lẹ́yìn ìwádìí náà.
Burkina Faso ṣàlàyé ìdí tí kò ṣe tíì fi ọmọ ogun Nàìjíríà mọ́kànlá tó wà ní àhámọ́ rẹ̀ silẹ àti bàálù wọn tó gbésẹ̀lé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà mọ́kànlá tó jẹ́ àwọn awakọ̀ òfurufú méjì àtàwọn ọmọ ogun mẹ́sàn-án táwọn aláṣẹ orílẹ̀ èdè Burkina Faso fi òfin gbé, ṣì wà ní àhámọ́ orílẹ̀ èdè náà.
Mínísítà fọ́rọ̀ ààbò àti ààbò àwọn aráàlú ní Mali, Daoud Aly Mohammedine sọ fún BBC pé, àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ìwádìí lórí ohun tó ṣokùnfà ìdí tí ọkọ̀ òfurufú Nàìjíríà fi balẹ̀ sí Burkina Faso àti pé àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ máa pinnu lórí ohun tí wọ́n máa ṣe fún wọn ni.
Ó ní pẹ̀lú àṣẹ àwọn olórí orílẹ̀ èdè, àwọn ti ní káwọn ọmọ ogun ojú òfurufú wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí.
Mali jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀ èdè Sahel, tí wọ́n sì ń kojú ìkọlù àwọn alákatakítí ẹ̀sìn.
Ẹ̀wẹ̀, ìjọba Nàìjíríà ni àwọn ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti gba ìtúsílẹ̀ àwọn ọmọ ogun náà àti láti gba ọkọ̀ òfurufú ológun C-130 tí àwọn aláṣẹ Burkina Faso fofin gbà kalẹ̀.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè, Kimiebi Ebienfa sọ fún BBC pé ìjọba Nàìjíríà ti ń bá àwọn aláṣẹ Burkina Faso sọ̀rọ̀.

Oríṣun àwòrán, Nigerian Air Force/X
"Ohun tó ṣe kókó ni láti gba ìtúsílẹ̀ àwọn ọmọ ogun àti kí ọkọ̀ òfurufú ológun náà padà sílé. Fún àwa ìjíròrò la fẹ́, ìjíròrò ti ń lọ ṣùgbọ́n a ò tíì mú ọjọ́ tí a máa fẹnukò."
Ní ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Kejìlá ni ọkọ̀ òfurufú iléeṣẹ́ ológun òfurufú Nàìjíríà C-130 balẹ̀ ní pàjáwìrì sí Bobo-Dioulasso ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Burkina Faso.
Mínísítà fún àmójútó ẹnubodè Burkina Faso, Emile Zerbo sọ pé ọkọ̀ òfurufú náà balẹ̀ sí orílẹ̀ èdè náà láì gbàṣẹ.
Àtẹ̀jáde kan tí àwọn ìjọba ológun Burkina Faso, Mali àti Niger èyí tí wọ́n pe ara wọn ní Alliance of Sahel States (AES) sọ pé ọkọ̀ òfurufú náà wọ ojú òfurufú Burkina Faso láì gba àṣẹ èyí ló sì mú kí wọ́n ní kí ọkọ̀ òfurufú náà balẹ̀.
Àmọ́ ìjọba Nàìjíríà ní bẹ́ẹ̀ kọ́ ni ọ̀rọ̀ rí. Àwọn aláṣẹ sọ pé níṣe ni ọkọ̀ òfurufú náà ṣàdédé yọnu nígbà tí wọ́n wà lójú òfurufú èyí ló sì mu balẹ̀ sí pápákọ̀ òfurufú tó súnmọ wọn jùlọ ní ìbámu pẹ̀lú òfin ìrìnnà òfurufú.
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ológun òfurufú Nàìjíríà, Ehimen Ejodame fi síta lọ́jọ́ Kẹsàn-án, oṣù Kejìlá, ó ní orílẹ̀ èdè Portugal làwọn ọmọ ogun náà ti ń bọ̀ kó tó di pé ó balẹ̀ sí pápákọ̀ òfurufú tó súnmọ́ wọn jùlọ nígbà tí ọkọ̀ náà yọnu.
Àtẹ̀jáde náà fi kun pé àwọn ọmọ ogun náà wà láyọ̀ àti pé àwọn aláṣẹ orílẹ̀ èdè tí wọ́n wà ń ṣe ìtọ́jú wọn.
Wọn kò sọ bóyá àwọn ọmọ ogun náà wà ní àhámọ́.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló ń wáyé láàárín ìfaǹfà tó ń wáyé láàárín Nàìjíríà àti AES lẹ́yìn tí àjọ di Economic Community of West Africa (Ecowas) rán àwọn ọmọ ogun lọ sí orílẹ̀ èdè Olómìnira Benin láti ṣe ìdádúró ìdìtẹ̀gbàjọba kan tó fẹ́ wáyé níbẹ̀ lópin ọ̀sẹ̀ tó kọjá.















