Kí ni ìdìtẹ̀gbàjọba ọmogun ọlọ̀tẹ̀ tó forí ṣánpọ́n ní Benin Republic túmọ̀ sí fún ilẹ̀ náà àti Áfíríkà?

Ọmogun mẹjọ duro lẹyin tabili ikaroyin nileeṣẹ tẹlifisan orilẹede Benin lọjọ keje oṣu Kejila yii

Oríṣun àwòrán, Reuters

    • Author, Paul Njie
    • Role, BBC Africa
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọpọ eeyan lo gboṣuba fawọn ọmogun olufọkansin to koju awọn ọmogun ọlọtẹ ti wọn gbiyanju lati ditẹ gbajọba Aarẹ Patrice Talon orilẹede Benin lọjọ Aiku to kọja.

Aarẹ ni igbesẹ awọn ọmogun ọlọtẹ naa le ṣakoba nla fun ẹkun iwọ oorun ilẹ Afirika.

Amọ, awọn ọmogun ọlọtẹ ọhun koro oju si nnkan ti wọn ṣapujuwe gẹgẹ bii ọna ti ko dara to ti Aarẹ Talon fi n mu ọrọ eto aabo pẹlu bi ẹgbẹ agbesunmọmi Al-Qaeda to n ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹgbẹ JNIM ṣe n ṣọṣẹ ni Benin.

Awọn ẹgbẹ alakakiti ẹsin naa fẹ tan kalẹ ju ẹkun Sahel lọ, wọn si ti ṣe oriṣiiriṣii ikọlu ni Benin ni bii ọdun meloo kan sẹyin.

Ọkunrin kan to wọ aṣọ buba alawọ buluu mu iwe iroyin lọwọ niluu Cotonou

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images

Ikọlu awọn alakakiti ẹsin

Ikọlu ẹgbẹ JNIM kan to ṣẹlẹ loṣu Kẹrin ọdun 2025 ṣekupa aadọrin ọmogun Benin lẹkun Kandi.

Eyi ni ikọlu tawọn eeyan to pọ julọ ti padanu ẹmi wọn lorilẹede Benin.

Awọn onwoye sọ pe ikọlu awọn alakakiti ẹsin atawọn agbesunmọmi n pọ si ni Benin, bo tilẹ jẹ pe awọn lajọlajọ lagbaaye n ṣeranwọ fun orilẹede naa.

Lọdun 2023 nikan, akọsilẹ fi han pe ikọlu 171 lo waye ni Benin, eyi to ju 71 to ṣẹlẹ lọdun 2022 lọ.

Awọn ọmogun ọlọtẹ ti wọn fẹ ditẹ gbajọba Aarẹ Talon tun tọka si awọn isẹlẹ mii to waye eyi to ṣafihan kudiẹ-kudiẹ to wa ni ijọba Aarẹ Talon.

Aworan awọn agbegbe ti Al-Qaeda ti n ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹgbẹ Jama'at Nusrat al-Islam wal-Muslimin (JNIM) lẹkun iwọ oorun Afirika papaa julọ lorilẹede Burkina Faso, Mali ati Niger.
Àkọlé àwòrán, Al-Qaeda n ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹgbẹ Jama'at Nusrat al-Islam wal-Muslimin (JNIM) lẹkun iwọ oorun Afirika papaa julọ lorilẹede Burkina Faso, Mali ati Niger.

Ṣe araalu ko nigbagbọ ninu ijọba mọ ni?

Onimọ nipa eto iṣejọba, Ọmọwe Jude Mutah, sọ pe awọn nnkan to n ṣẹlẹ kaakiri orilẹede Benin le jẹ ohun to ṣokunfa igbiyanju awọn ọmogun ọlọtẹ lati ditẹ gbajọba Aarẹ Talon.

Ọmọwe Mutah sọ pe ''nnkan to maa n ṣẹlẹ lasiko ti iditẹgbajọba ba ṣẹlẹ ni pe awọn ọmogun ọlọtẹ maa n lo anfaani kudiẹ-kudiẹ ijọba lati ṣe nnkan ti wọn ba fẹ ṣe ni.''

Aarẹ Talon to ṣeleri wi pe oun ko ni dupo aarẹ ninu eto idibo ọdun to n bọ ti kede minisita eto iṣuna, Romuald Wadagni, gẹgẹ bi ẹni ti yoo rọpo rẹ ninu ẹgbẹ oṣelu to wa.

Ọpọ eeyan lo si n sọ pe ọwọ Aarẹ Talon yoo si wa nijọba ti ọkan ninu awọn minisita rẹ ba le wọle ibo aarẹ.

Ọkunrin kan wọ buba alawọ funfun, o si mu ere oju minisita eto iṣuna Benin dani

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images

Ile igbimọ aṣofin agba Benin ṣe agbekalẹ ofin ti yoo maa jẹ ki aarẹ lo ọdun meje ni saa kan dipo ọdun marun un to wa ninu ofin orilẹede naa tẹlẹ.

Bakan naa tun ni ile ṣofin fun idasilẹ ile aṣofin agba tawọn aarẹ tẹlẹri yoo wa nibi.

Awọn alatako sọ pe ọgbọn ni Aarẹ Talon n da lati maa jẹ gaba lori ẹni to ba wọle ibo aarẹ ninu ibo ọdun to n bọ.

Lara awọn alẹnulọrọ to n sọrọ lori ọrọ naa ni Olivier Boko, oniṣowo ati minisita ere idaraya tẹlẹ, Oswald Homeky.

Boko ko fi erongba rẹ lati gbapo aarẹ lọwọ Talon bo rara, pẹlu atilẹyin Ọgbẹni Homeky.

Koda, Aarẹ Talon sọ fun ileeṣẹ iroyin Jeune Afrique pe oun mọ pe Olivier fẹ gba ipo oun.

Ọmọwe Mutah ni iru ọrọ bayii le ṣokunfa iditẹgbajọba.

Amọ, onimọ nipa ọrọ ilẹ Afirika, Mucahid Durmaz, sọ pe iditẹgbajọba to fori ṣanpọn le ṣe anfaani fun Aarẹ Talon.

O ni eyi le mu ki aarẹ ṣiṣẹ pẹlu ẹgbẹ oṣelu rẹ lati jawe olubori ninu eto idibo to n bọ.

Ọkunrin kan lori alupupu niluu Cotonou lorilẹede Benin Republic.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images

Nnkan to ṣẹlẹ lẹkun iwọ oorun Afirika ati ibeere tawọn eeyan n beere

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Orilẹede Benin jẹ orilẹede kan ti eto ijọba awarawa ti fẹsẹ mulẹ lẹkun iwọ oorun ilẹ Afirika ti iditẹgbajọba ti n ṣẹlẹ lera lera.

Iditẹgbajọba ti waye lawọn orilẹede bii Mali, Niger, Burkina Faso, ati Guinea-Bissau to yi Benin ka.

Lẹyin iditẹgbajọba to fori ṣanpọn ni Benin ni ajọ Ecowas sọ pe oun yoo ko ọmogun lọ si Benin lati ṣeranwọ fun ijọba ki eto iṣejọba awarawa le fẹsẹ mulẹ daadaa.

Ijọba Naijiria gan an ran awọn baalu ijagun lọ si Cotonou lati kọju ija sawọn ọmogun ọlọtẹ to fẹ ditẹ gbajọba Aarẹ Talon.

Awọn adari ẹkun Sahel kọju si orilẹede Russia fun atilẹyin nipa ọmogun, nigba ti wọn fẹsun kan awọn orilẹede to wa layika pe wọn n gbimọ pọ pẹlu France lati dawọn orilẹede awọn ru.

Ko si ẹni to le sọ nnkan to maa ṣẹlẹ lọjọ iwaju pẹlu bii ijọba Benin ṣe n wa iranwọ lati ṣegun awọn ọmogun ọlọtẹ ati lati ri pe eto ijọba awarawa fẹsẹ mulẹ.

Ju gbogbo rẹ lọ, ẹni to ba jawe olubori ninu ibo aarẹ oṣu Kẹrin ọdun 2026 niṣẹ lati ṣe lati daabo bo orilẹede Benin lọwọ awọn ọmogun ọlọtẹ to fẹ ditẹ gbajọba ati lọwọ awọn agbesunmọmi.