Ológun Nàìjiríà kò lè borí àwọn agbébọn, ìdí rèé tí mo fi ní kí ìjọba dúnàádúrà pẹ̀lú wọn - Sheikh Gumi

- Author, Helen Oyibo
- Reporting from, Abuja
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Onímọ̀ nípa ẹ̀sìn Islam, Sheikh Ahmad Gumi ti jiyàn ẹ̀sùn kan pé wí pé òun ń ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn agbébọn láti ọdún 2021 lẹ́yìn tí ìjọba Nàìjíríà kéde ẹgbẹ́ náà bíi agbáṣùmọ̀mí.
Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tí gbajúmọ̀ Alfa náà ṣe pẹ̀lú BBC ló ti sọ̀rọ̀ nípa ìhà tó kọ sáwọn agbébọn àti ipá tí wọ́n ń kó lórí ìpèníjà ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra lọ́wọ́ yìí.
Gumi ní òun gbàgbọ́ pé àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà kò lè ṣẹ́gun àwọn agbébọn náà, tó sì jẹ́ pé ìdúnàádúrà nìkan ni ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro ààbò.
Fún ọ̀pọ̀ ọdún ni Sheikh Gumi, ẹni tó jẹ́ dókítà ìṣègùn òyìnbó, tó sì tún ti fìgbà kan rí jẹ́ ológun sọ pé gbígbé ogun kojú àwọn agbébọn náà kò lè tán ìṣòro ààbò Nàìjíríà.
Àwọn ọ̀rọ̀ tó máa ń sọ yìí jẹ́ kí àwọn èèyàn máa ń ríi bí ẹni tí ó ń ṣe àtìlẹyìn àti agbẹnusọ fún àwọn agbébọn.
Ó sọ fún BBC pé "nígbà tí wọ́n sọ pé àwọn kìí ṣe ìdúnàádúrà pẹ̀lú àwọn agbéṣùmọ̀mí, mi ò mọ ibi tí wọ́n ti gbọ́ ìyẹn. Kò sí nínú Bíbélì àti Kùránì, kódà kò sí níbì kankan nítorí gbogbo èèyàn ló máa ń dúnàádúrà.
"Amẹ́ríkà ní ọ́fíìsì tí wọ́n ti ń dúnàádúrà pẹ̀lú àwọn Taliban ní Qatar, gbogbo èèyàn ló máa ń dúnàádúrà. A máa dúnàádúrà fún àlááfíà láti ri dájú pé á fòpin sí ìtàjẹ̀sílẹ̀."
Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú BBC náà, Gumi sọ̀rọ̀ nípa bí irú èèyàn táwọn agbébọn náà jẹ́ àti ohun tí wọ́n ń fẹ́.
'Iléeṣẹ́ ológun Nàìjiríà kò lè borí àwọn agbébọn'
Nàìjíríà ń kojú ìpèníjà ààbò èyí tó mú ààrẹ Bola Tinubu kéde àwọn àyípadà kan lẹ́ka iléeṣẹ́ ológun, tó sì kéde pàjáwìrì lẹ́ka ètò ààbò.
Èròńgbà ni láti kojú ìpèníjà ààbò, láti mọ ohun tó ṣokùnfà ìpèníjà náà ṣùgbọ́n Gumi tún tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ tó ti máa ń sọ tipẹ́ pé ìjíròrò pẹ̀lú àwọn agbébọn náà ni ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro ààbò.
"A nílò iléeṣẹ́ ológun tó kájú òṣùwọ̀n. Àwọn ológun ń gbìyànjú agbára wọn báyìí, wọ́n nílò ìdánilẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n ra ohun ìjà ogun fún wọn."
Ò wòye pé ìjà tó wà nílẹ̀ kìí ṣe ohun tí wọ́n le fi ipá ṣẹ́gun rẹ̀ nítorí ìjọba àtàwọn aráàlú níṣẹ́ tó pọ̀ láti ṣe lórí rẹ̀ nítorí iléeṣẹ́ ológun kò lè dá iṣẹ́ náà ṣe.
'Ọdún 2021 ni mo ti bá àwọn agbébọn sọ̀rọ̀ gbẹ̀yìn'
Lára ohun táwọn èèyàn fi máa ń tako Sheikh Gumi ni pé ó máa ń gbẹnusọ fáwọn agbébọn, tó sì máa ń rọ ìjọba láti dúnàádúrà pẹ̀lú àwọn agbébọn.
Ṣùgbọ́n Gumi jiyàn ọ̀rọ̀ náà pé ọdún 2021 ni òun ti bá àwọn agbébọn sọ̀rọ̀ gbẹ̀yìn àti pé òun jẹ́ kí gbogbo ìdúnàádúrà òun àti wọn hàn sí gbogbo èèyàn nítorí òun kìí dá lọ lásán.
Ó ní òun ààwọn ọlọ́pàá, àwọn aráàlú àtàwọn akọ̀ròyìn ni àwọn jọ máa ń ló sọ́dọ̀ àwọn agbébọn náà nígbà náà lọ́hùn-ún.
Ó fi kun pé òun ń wá ọ̀nà láti ri bí àwọn ṣe máa mú àwọn náà mọ́dọ̀ ṣùgbọ́n ìjọba tó wà lóde nígbà náà kò ṣetán láti gbọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ.
"Lẹ́yìn ìgbà náà ni wọ́n kéde wọn gẹ́gẹ́ bí agbéṣùmọ̀mí, àti ìgbà náà ni mo sì tig é àjọṣepọ̀ èmí pẹ̀lú wọn."
'Pípa àwọn ọmọ ogun burú ju jíjí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé lọ'
Lára àwọn ọ̀rọ̀ tí Sheikh Gumi sọ lọ́dún 2021 tó fa awuyewuye ni ọ̀rọ̀ tó so nípa jíjí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé.
Ó ní kìí ṣe ohun tó burú púpọ̀ pé àwọn agbébọn náà ń jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé nítorí ìdúnàádúrà ló máa gbẹ̀yìn rẹ̀ àti pé àwọn agbébọn máa ń ṣe jẹ́jẹ́ pẹ̀lú ẹ̀mí àwọn èèyàn.
Nígbà tí a bí pé ṣe bẹ́ẹ̀ náà ló ṣì rí ọ̀rọ̀ jíjí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé, ó ní bẹ́ẹ̀ni àti pé bẹ́ẹ̀kọ́.
"Mo rò pé òótọ́ ṣì wà lára ọ̀rọ̀ tí mo sọ tí àwọn míì kò sì rí bẹ́ẹ̀. Ohun tó burú ni jíjí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé lóòótọ́ àmọ́ kò burú tó pípa àwọn ọmọ ogun ṣùgbọ́n ohun tó burú ni gbogbo rẹ̀.
'Fulani darandaran tó ń jagun láti wá ìgbé ayé rere ni àwọn agbébọn'
Ìwà àwọn agbébọn ní Nàìjíríà ti kúrò lọ́rọ̀ àwọn àgbẹ̀ àti darandaran nìkan mọ́ báyìí, ó tin í ìwà ọ̀daràn nínú.
Jíjà sí ọ̀nà láti dẹran joko ló ti dọ̀rọ̀ ìjínigbé láti fi gbowó èyí tó ti di ìpèníjà ńlá bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Sheikh Gumi gbàgbọ́ pé àwọn agbébọn tó n ṣọṣẹ́ lẹ́kùn ìwọ̀ oòrùn àríwá Nàìjíríà àtàwọn ìpínlẹ̀ kan ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà, tí wọ́n sì ń jí ọ̀pọ̀ èèyàn gbé ló jẹ́ àwọn Fulani darandaran tó ń jà fún ìgbéayé látàrí pé ọ̀nà jíjẹ wọn ti ń dí.
"Wọ́n fẹ́ gbáyé. Ohun tí wọ́n mọ̀ ní ìgbé ayé wọn ni dída ẹranjẹ̀. Wọ́n mọ ibi tí wọ́n máa ń da ẹran wọn gbà, ìgbé ayé wọn nìyẹn."










