Olubadan Rashidi Ladoja figbe ta, ṣàlàyé ìdí tó fi nira láti dupò Ọba mú, ju ipò Gómìnà lọ, pé fún ṣíṣí àwọn bodè Nàíjíríà

Oríṣun àwòrán, Adeola Oloko/Facebook
Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Ladoja ti sọ pe o rọrun lati di ipo gomina mu ju ki eeyan di ipo ọba mu lọ.
Olubadan sọrọ yii lasiko ti Ọba Wasiu Omogbolahan Lawal, Oniru of Iru ti ilu Eko ṣabẹwo si i nile rẹ ni Bodija niluu Ibadan.
Ọba Ladoja, to ti figba kan ri jẹ gomina ipinlẹ Oyo, ṣalaye pe gomina lagbara lati paṣẹ gẹgẹ bii olori ijọba, amọ, ọba ko ni iru agbara bẹẹ.
Olubadan tun sọ pe ko si ibi kan gboogi ti ọba ti n rowo, nigba ti eto inawo gidi wa fun gomina.
Ladoja ni o ṣe pataki lati fun awọn ọba alaye ni ipo ti yoo wa ninu iwe ofin Naijiria nitori bi awọn ọba ti sun mọ araalu pẹkipẹki si.
Ọba ilẹ Ibadan fikun ọrọ rẹ pe nnkan ti araalu n reti lọdọ awọn ọba alaye pọ gan an.
Olubadan ranti asiko to n gbe niluu Eko lọpọ ọdun sẹyin, papaa julọ ni agbegbe Lagos Island.
Ṣaaju ni Oniru ti gboṣuba fun Ọba Ladoja fun oniruuru nnkan to ti ṣe fun ọpọlọpọ ọdun sẹyin.
Ọba Omogbolahan toun naa ti figba ri jẹ kọmiṣọna nipinlẹ Eko, sọrọ lori bi o ti nira fun ẹni to ba ti wa nipo ijọba ri tẹlẹ lati di ipo ọba mu.
Lara awọn to ki Oniru kaabọ si ile Ọba Ladoja ni Ekarun Balogun, Oloye Sharafadeen Alli ati Agbaakin Olubadan, Oloye Teslim Folarin.
"Asiko ti to lati ṣi awọn ibode ori ilẹ ni Naijiria pada"
Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Ladoja, ti rọ ijọba apapọ lati ṣi awọn ibode oriilẹ orilẹede Naijiria pada lati le jẹ ki awọn eeyan ati ẹru maa lọ lati ibikan si ibomiran lẹkun iwọ-oorun Afirika aisi idiwọ.
Ọba Ladoja sọ pe alakalẹ ti ajọ to n ri si eto ọrọ aje lẹkun iwọ oorun Afirika, ECOWAS, fi le lẹ niyii.
Ladoja sọrọ yii lasiko ti ọga agba ajọ aṣọbode ẹkun Oyo/Osun, Compt. Gambo Aliyu, ṣabẹwo si i ni aafin rẹ niluu Ibadan.
Lọdun 2019 ni ijọba apapọ labẹ aṣẹ Aarẹ Muhammadu Buhari gbe ibode oriilẹ Naijiria ti pa.
Amọ, ijọba pada ṣi awọn kan pada eyi ti bode Seme ati Idiroko wa ninu rẹ.
Olubadan ni ko si idi fun ijọba lati gbe ibode ti pa mọ lẹyin ti o ti yọ owo iranwọ ori epo kuro lọdun 2023.
Ọba Ladoja tun rọ ajọ aṣọbode lati ri pe awọn dẹkun bawọn eeyan kan ṣe n ko nnkan ija oloro wọ Naijiria.
Ladoja ko ṣai lu Ọga Aliyu lọgọ ẹnu fun iṣẹ taku takun ti o ti ṣe lati igba ti o ti n ṣakoso ajọ aṣobode lẹkun ipinlẹ Oyo ati Osun.
Ọga ajọ aṣọbode naa to dupẹ lọwọ Olubadan, rọ kabiyesi lati maa tẹsiwaju pẹlu iranwọ rẹ fun ajọ aṣọbode.
"Ọmọ Yoruba, ẹ wa foju sọri lori ọrọ eto aabo to mẹhẹ"
Ẹwẹ, Olubadan ti kepe awọn ọmọ Yoruba lati maa foju sọri pẹlu bi eto aabo ti di oju keji ni Naijiria bayii.
Ọba Ladoja sọrọ yii nibi ayẹyẹ ayajọ Ode-Omu nipinlẹ Osun, eto ti wọn maa n lo lati wo bi idagbasoke awujọ naa ṣe n lọ.
Ladoja gboṣuba fawọn eeyan Ode-Omu fun igbiyanju wọn lati jiroro lori nnkan ti wọn fẹ ṣe fun ọjọ iwaju.
Olubadan ṣeleri lati maa ṣe iranwọ fun ilu Ode-Omu lori gbogbo eto ti wọn ba fẹ ṣe.
Ninu ọrọ tiẹ, minisita fun ọrọ ọlọpaa tẹlẹ, Alhaji Jelili Wale Adesiyan, ṣalaye pe ọdun 1909 ni wọn da ilu Ode-Omu silẹ.
O ni awọn ogboju ọde lati ilu Ibadan lo da ilu naa silẹ.















