Ilé aṣòfin ní kí Tinubu fi ọmọ ogun ránṣẹ́ sí Benin Republic

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/Facebook
Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà Nàìjíríà ti buwọ́lu ìbéèrè Ààrẹ Bola Tinubu láti fi àwọn ọmọ ogun ránṣẹ́ sí orílẹ̀ èdè Olómìnira Benin.
Ìgbésẹ̀ ààrẹ láti fi àwọn ọmọ ogun ránṣẹ́ sí Benin yìí jẹ́ ọ̀nà láti pẹ̀tù sááwọ̀ látàrí ìdìtẹ̀gbàjọba tó forí sánpọ́n ní orílẹ̀ èdè náà.
Ní ọjọ́ Àìkú ni àwọn ológun kan farahàn lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán pé àwọn ti gbàjọba lọ́wọ́ ààrẹ Patrice Talon.
Àwọn ológun náà tí ọ̀gágun Pascal Tigri ṣáájú wọn gbìyànjú láti lé ààrẹ Talon kúrò lórí ipò ṣùgbọ́n tí ìjọba ní ìdìtẹ̀gbàjọba náà forí sánpọ́n.
Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà náà padà jáde sọ̀rọ̀ pé àeọn wà lára àwọn tó ṣe ìrànwọ́ fún Benin láti ri pé ìdìtẹ̀gbàjọba náà kò kẹ́sẹ járí.
Lẹ́yìn náà ni Ààrẹ Tinubu kọ̀wé ránṣẹ́ sí ilé aṣòfin àpapọ̀ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun pé kí wọ́n buwọ́lù ú kí òun fi ọmọ ogun ránṣẹ́ sí Benin nítorí ìjọba orílẹ̀ èdè ń bèèrè fún ìrànlọ́wọ́ Nàìjíríà láti dènà àwọn tó fẹ́ dojú ètò ìṣèjọba àwaarawa délẹ̀ níbẹ̀.
Àlàyé rèé lórí bí Naijiria ṣe ran Benin lọ́wọ́ láti dojú àwọn ológun tó fẹ́ dìtẹ̀ gbàjọba bolẹ̀

Ẹni to to ni i gba lo yẹ ka fi ọrọ lọ ni ijọba orilẹede Olominira Benin, fi ọrọ wọn ṣe lọjọ Aiku ana, nigba ti awọn ologun kan fẹ doju ijọba ibẹ bolẹ, ti ijọba Benin si sare ke pe Naijiria lati gba wọn lọwọ ologun to fẹ yi wọn lagbo da sina.
Pascal Tigri ni olori Ogun ọlọtẹ to lewaju iditẹgbajọba naa bi wọn ṣe sọ.
Ẹsẹkẹsẹ ni Naijiria naa si ti huwa aṣiwaju, atoo-fiṣẹ-ogun ran fun Benin, wọn jẹ ipe wọn lẹyẹ o sọka, kapa iditẹgbajọba ọhun.
Ẹ o ranti pe aarọ ọjọ Aiku naa ni iroyin gbode, pe awọn ologun kan ti gba ijọba lorilẹede Benin, wọn si ti le Aarẹ Patrince Talon lọ raurau.
Iro ibọn to n ro lakọlakọ ati awọn baaluu ologun to n kọja, lo kọkọ bẹrẹ si i fu awon ara ilu lara.
Ko si pẹ sigba naa ti ikọ ologun kan fi bọ sori amohunmaworan ilẹ Benin, ti wọn kede pe awọn ti gbajọba.
Bi eyi ṣe n lọ lọwọ ni ikilọ n jade si araalu lati ma ṣe jade sita, ki wọn ma baa fi ara ko ina.
Ninu laasigbo naa ni ikọ Aarẹ Patrice ti ranṣẹ pe Naijiria fun aabo, ti ilẹ wa si jẹ wọn pẹlu ikọ ọmọ ogun.
Báwo ni Naijiria ṣe kàpà ìdìtẹ̀gbàjọba Benin gan-an?
Gẹgẹ bi atẹjade to ti ile ijọba Naijiria wa ṣe wi, eyi ti Agbẹnusọ Aarẹ Bola Tinubu, Bayo Onanuga, fi sita lọjọ Aiku, Aarẹ lo paṣẹ pe ki awọn ologun Naijiria tete gba Benin lọ.
O ni lẹyin ti Naijiria gba ipe 'ẹ gba wa' lati ọdọ Benin lẹẹmeji, ti wọn ni awọn ọlọtẹ ti gba tẹlifiṣan Benin, wọn ti n kede iditẹgbajọba lori rẹ ni Aarẹ paṣẹ pe ki wọn maa lọ si ilu naa.
Awọn ikọ ologun oju ofufufu lati Naijiria ni Tinubu kọkọ paṣẹ pe ki wọn gba gbogbo ọna irinajo ofurufu ilẹ Benin pata.
O ni ki wọn ṣe eyi lati da aabo bo ofin ilẹ naa, da aabo bo awọn ileeṣẹ ijọba, ki wọn si pese aabo fun araalu pata.
Lẹyin eyi ni ìpè keji tun waye lati Benin, nibi ti wọn ti beere fun awọn ọmọ ogun ori ilẹ ati awọn ti yoo maa wọde, ti wọn yoo si le kapa rogbodiyan to ba fẹ yọju.
Gbogbo eyi naa si ni Naijiria ṣe bii iranwọ fun alamuleti rẹ yii, gẹgẹ bi Olori ologun ilẹ Naijiria, Ọgagun Olufemi Oluyede, ṣe fidi rẹ mulẹ.
"Tiwa ni pe ka tẹle aṣẹ olori orilẹ ede, Aarẹ Bola Tinubu."
Bẹẹ ni Olori ologun Naijiria, Olufemi Oluyede, ṣalaye.
O ni awọn ikọ ologun Naijiria ti wa ni Benin, ti wọn n ṣiṣẹ aabo , gẹgẹ bi Benin paapaa ṣe fọwọ si iṣẹ iranwọ ti ologun Naijiria n ṣe fun wọn.
Ifọwọsowọpọ ẹka ologun to faramọ ijọba Aarẹ Patrice Talon ati iranlọwọ ti awọn ṣọja Naijiria fun wọn, lo pada so eso rere ti wọn fi gba awọn ẹka ijọba pada lọwọ awọn ṣọja to fẹ gbajọba.
Bakan naa ni won le wọn jade ni ileeṣẹ tẹlifiṣan ti wọn ti n kede iditẹgbajọba naa.

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency
Tinubu gbóríyìn fún àwọn ṣọ́jà Naijiria
Ninu ọrọ ikini rẹ to sọ lẹyin aṣeyọri awọn ṣọja Naijiria ni Benin, Aarẹ Bola Tinubu gboriyin fun awọn ologun ilẹ wa.
O yin wọn fun bi wọn ṣe ri iṣẹ naa ṣe lai ṣiyemeji, ti wọn si tẹle ilana to de iṣẹ iru eyi.
"Lonii, awọn ologun ilẹ Naijiria duro bii akọni, olugbeja ati oluda-aabo-bo, bi ofin ṣe la a kalẹ, lati ṣe iranlọwọ fun ilẹ Olominira Benin, nigba ti wọn pe wa.
"Wọn ti ṣe iranlọwọ lati mu alaafia wa ni orilẹede alamuleti, wọn si wu wa lori fun bi wọn ṣe ri i pe ijọba awaarawa fẹsẹ mulẹ lati ọdun 1999.
"Naijiria duro digbi lẹyin ijọba Olominira Benin ati awọn eeyan rẹ."
Aarẹ Bola Tinubu lo sọ bẹẹ ninu ọrọ rẹ.
O ni bi Naijiria ṣe da si ọrọ Benin yii ṣafihan ohun ti ajọ ECOWAS n fẹ, ati pe Naijiria paapaa nifẹẹ si alaafia agbegbe .
Àwọn aláṣẹ Benin Republic kéde pé ìdìtẹ̀gbàjọba forí sánpọ́n

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Mínísítà fọ́rọ̀ abẹ́lé ní orílẹ̀ èdè Benin Republic àti ètò ààbò Alassane Seidou ti kéde pé ìdìtẹ̀gbàjọba táwọn ológun kan gbèrò ní orílẹ̀ èdè náà ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú ti forí sánpọ́n.
Mínísítà Seidou nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán sọ pé àwọn olórí iléeṣẹ́ ológun orílẹ̀ èdè náà ṣe àmúṣẹ ẹ̀jẹ́ tí wọ́n jẹ́, tí wọ́n sì ri dájú pé ìdìtẹ̀gbàjọba náà kò kẹ́ṣe járí.
Ìjọba ní èròńgbà àwọn ológun tí wọ́n fẹ́ dojú ìjọba dé náà kò wá sí ìmúṣẹ, tó sì rọ àwọn aráàlú láti máa bá iṣẹ́ oójọ̀ wọn lọ láìsí ìbẹ̀rù.
Iléeṣẹ́ ààrẹ Benin sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn ológun tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ààrẹ Talon ni wọ́n ṣì ní ìfarajìn sí ìdúró ire ètò ìṣèjọba àwaarawa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ṣaaju ni ikọ ologun kan ti kede lori amohunmaworan ilẹ Olominira Benin, pe awọn ti gba iṣakoso orilẹede naa bayii, awọn si ti le Aarẹ Patrice Talon kuro nipo.
Aarọ ọjọ Aiku, ọjọ Keje, oṣu Kejila ọdun 2025 ni won kede naa.
Ori amohunmaworan ilẹ Benin ni awọn ṣọja ti kede pe awon ti gbesẹ le awon ofin ti tẹlẹ ti ilu naa n lo, fun asiko kan.
Wọn fi kun un pe awọn ti tu ijọba ati awọn ẹgbẹ oṣelu ka.
Awọn ologun ti wọn pe ara wọn ni "Military Committee for Refoundation" naa sọ pe igbesẹ yii waye lati tako bi Aarẹ Talon ṣe n dari orilẹ naa.
Olori ogun ti igbagbọ si wa pe o lewaju igbajọba yii ni Lieutenant-Colonel Pascal Tigri.
Lọwọ yii, a ko le sọ ibi ti Aarẹ Talon wa, pẹlu bi a ṣe gbọ pe awọn ologun ti lọ si ile rẹ ni Cotonou.
Ẹwẹ, ẹka iroyin AFP royin pe aarẹ naa wa ni alaafia.
Báwo ló ṣe bẹ̀rẹ́
Gẹgẹ bi iroyin ṣe ro o, iro ibọn ni awọn eeyan kọkọ bẹrẹ si i gbọ laaarọ ọjọ Aiku naa, bẹẹ ni wọn tun n gbọ pe ọkọ ofurufu agberapaa awọn ologun n fo kaakiri Cotonou.
Fun idi eyi ni French Embassy ṣe rọ awọn araalu lati wa ninu ile wọn, fun aabo to peye.
Tẹ o ba gbagbe, oṣu Kẹrin ọdun 2026 lo yẹ ki idibo apapọ waye ni Benin, nigba ti saa Aarẹ Talon yoo wa sopin.
Aarẹ Talon funra ẹ ti ni oun ko ni i lọ fun saa kẹta, o si ti darukọ ẹni ti yoo gba ipo lọwọ rẹ.
Igbajọba lati ọwọ ologun to waye ni Benin yii n ṣẹlẹ lẹyin ọjọ diẹ ti iru rẹ waye ni Guinea-Bissau, ilu to jẹ alamuleti Benin.
Wọn le Aarẹ Umaro Sissoco Embalo to wa nipo kuro lẹyin ọjọ kẹta ti idibo waye.
Iditẹgbajọba ologun ṣe n waye lẹmọlẹmọ lẹnu ọdun diẹ si asiko yii ni ẹkun Iwọ -oorun Africa, eyi to n mu ibẹru wa nipa aabo agbegbe naa.
Àwọn orilẹede ti ologun ti gbajọba ni Africa láìpẹ̀
Ilẹ Africa ti koju iditẹgbajọba latọwọ ologun lẹnu ọdun diẹ si asiko yii.
Mali: Nigba ti wọn gbajọba ni Mali, oṣu Kẹjọ ọdun 2020 lo ṣaaju, alakọkọ iru rẹ ni ilu naa.
Omiran si tun ṣẹlẹ loṣu Karun-un ọdun 2021.
Chad: Ko pẹ lẹyin eyi ni Chad naa ko tirẹ, ologun gbajọba ni oṣu Kẹrin ọdun 2021, lẹyin iku Aarẹ Idriss Déby.
Guinea: Oṣu Kẹsan-an ọdun 2021 ni tiwọn waye, nigba ti ologun le Aarẹ Alpha Condé lọ.
Burkina Faso: Iditẹgbajọba meji waye lọdun kan naa ni 2022-akọkọ loṣu Kin-in-ni, ikeji loṣu Kẹsan-an.
Niger:Awọn ologun le Aarẹ Mohammed Bazoum lọ loṣu Keje ọdun 2023.
Gabon: Oṣu Kẹjọ ọdun 2023 ni ologun gbajọba ibẹ, wọn fopin si ijọba Bongo to ti n dari tipẹ.
Sierra Leone: Oṣu Kọkanla ọdun 2023 ni ologun gbajọba.
Congo-Brazzaville: Oṣu Kẹsan-an odun 2023 ni awuyewuyẹ gbilẹ pe igbiyanju iditẹgbajọba waye, ṣugbọn awọn alaṣẹ ibẹ ni ko ri bẹẹ.
Naijiria: Oṣu Kẹwaa ọdun 2025 yii ni iroyin gbode, pe awọn ologun kan gbiyanju lati gbajọba, ṣugbọn ijọba ni ko ri bẹẹ.
Ti Guinea-Bissau to ṣẹlẹ lọsẹ meji sẹyin ni iroyin rẹ ko ti kasẹ nilẹ, nibi ti wọn ti le aarẹ wọn lọ nigba to ku ọjọ kan ṣoṣo ti ajọ eleto idibo yoo kede ẹni to jawe olubori ninu idibo.
Wayii si ni ti Ilẹ Olominira Benin, nibi ti ologun ti fi owurọ ọjọ Aiku kede gbigba ijọba .














