Sheikh Adam Al-Ilory àti Sheikh Muyideen Bello: Àwọn àgbàọjẹ̀ àáfà tí wọn ti kú àmọ́ tí iṣẹ́ wọn ṣì ń dáhùn nílẹ̀ Yorùbá

Oríṣun àwòrán, @Fuadoluwadamil1/X
Eeyan ju eeyan lọ, aafa si ju aafa lọ, awọn aafa kan wa taye ko le gbagbe wọn nilẹ Yoruba bo tilẹ jẹ pe wọn tik u.
Awọn musulumi to fi mọ awọn ẹlẹsin Kristẹni ko le gbagbe iru awọn aafa bẹẹ fun ipa ribi ribi ti wọn ti ko ninu igbelarugẹ ẹsin Islam.
Sheikh Adam Abdullahi Al-Ilory àti Sheikh Muyideen Bello wa lara awọn onimọ ẹlẹsin Islam ti a n sọ yii.
Ko lo mu awọn ogbontarigi aafa meji ti a n sọ yii yatọ gan an tawọn eeyan fi maa n sọ nipa wọn ni gbogbo igba?
BBC Yoruba ṣe alaye lẹkunrẹrẹ nnkan to mu kawọn aafa meji naa jẹ ilumọọka gan an.
Ta ni Sheikh Adam Abdullahi Al-Ilory?
Sheikh Adam Abdullahi Al-Ilory jẹ gbajugbaja onimọ nipa ẹsin Islam to ko ipa ribi ribi ninu ẹsin naa ti o si di ilumọọka nigba aye rẹ.
Lọdun 1917 ni wọn bi Sheikh Al-Ilory sinu ẹbi Abdul Baqi al-Ilory lati ilu Ilorin ipinlẹ Kwara.
Loootọ ọmọ Ilorin ni Sheikh Al-Ilory, amọ, ilu Waza ni ijọba ibilẹ Dendi lorilẹede Benin Republic ti baba rẹ n gbe ni wọn bi i si.
Onimọ nipa ẹsin Islam ni baba Shekh Al-Ilory, oun si tun ni Imaamu agba ilu Waza nigba aye rẹ.
Ọmọbabinrin ti baba rẹ wa lori oye ni Aishah to jẹ mama Shekh Al-Ilory, jẹ nigba naa.
Orilẹede Benin Republic ni Shekh Al-Ilory dagba si, lọdọ baba rẹ lo si ti n kọ Quran to fi di bii ọmọ ọdun mẹtala ki o to pada siluu Ilorin.
Sheikh Al-Ilory lọ sile ẹkọ giga fasiti Al-Azhar lọdun 1946 ni Egypt nibi to ti kẹkọọ gboye ninu ede Araabu ati imọ nipa ẹsin Islam.
Lẹyin naa lo lọ fun iṣẹ hajj ni Mecca nibi ti ọpọ onimọ nipa ẹsin islam ti ṣakiyesi pe Eledua fi ọpọlọ jinki rẹ.
Shekh Al-Ilory rinrin kaakiri awọn orilẹede bii Sudan, Somalia ati Senegal lati wa imọ nipa ẹsin Islam.
Lọdun 1952 lo da ile ẹkọ Markazu't-ta limi l-Arabi al-lslami silẹ niluu Abeokuta, nipinlẹ Ogun.
O pada ko Ile ẹkọ naa lọ si Agege niluu Eko lọdun 1957.
Ile ẹkọ yii ni akọkọ iru rẹ tawọn eeyan ti n kọ nipa ẹsin islam kaakiri ilẹ Yoruba.
Sheikh Adam kọ oriṣiiriṣii iwe lori ẹsin islam to le ni ọgọrun un nigba aye rẹ
Lọjọ kẹta oṣu Karun un ọdun 1992 ni Sheikh Al-Ilory ku niluu London, amọ, awọn iṣẹ ọwọ rẹ ko parẹ.
Ta ni Sheikh Muyideen Bello?
Ọkan ni Sheikh Muyideen Bello jẹ ninu awọn aafa to milẹ titi nilẹ Yoruba.
Ni owurọ ọjọ Ẹti, ọjọ kẹfa, oṣu Kejila, ọdun 2024 ni agba Alfa, to tun jẹ olukọ ẹsin Islam, jade laye ni ile rẹ to wa niluu Ibadan.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, oloogbe Bello ti sun mọ ẹni aadọrun ọdun, ki ọlọjọ o to o de.
Ọkan lara ẹbi oloogbe sọ fun BBC pe, baba sẹ aisan ranpẹ ko to o ku.
Ogbontarigi ni Sheik Muyideen Ajani Bello ninu ẹkọ ati imọ ẹsin Islam.
Ọmọ bibi ilu Ibadan, nipinlẹ Oyo si ni pẹlu.
Iroyin sọ pe apa Ariwa ni baba naa gbe fun eyi to pọ ninu igbeaye rẹ, ko to o fi ilu Ibadan ṣe ibugbe lati nnkan bi ogun ọdun sẹyin.
Bakan naa ni awọn akọsilẹ kan sọ pe ọmọ ọdun mẹwaa ni Bello wa to ti bẹrẹ sii ṣe waasi.
Baba rẹ to gbajumọ daadaa nigba naa labule Agberigbe, to wa niluu Iwo lo kọ ọ ni keu.
Muyideen Ajani Bello ni iroyin sọ pe o ṣiṣẹ olukọ ni Ansa-ru-deen College to wani Saki, ipinlẹ Oyo.
Sheik Ajani Bello tun ṣiṣẹ gẹgẹ bi olukọ nile ẹkọ girama kan niluu Abẹokuta, nibi to ti kọ iṣiro ati Biology.















