Olórí ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò kú sí àhámọ́ lẹ́yìn oṣù kan

Oloogbe Anicet Ekane, o n wo orere ninu aworan yii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Anicet Ekane
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọkan lara awọn olori ẹgbẹ oṣelu African Movement for New Independence and Democracy (MANIDEM), lorilẹede Cameroon, Anicet Ekane, ti dagbere faye ninu ahamọ ti ijọba orilẹede naa sọ ọ si lẹyin oṣu kan to ti wa nibẹ.

Agbẹjọro rẹ ati ẹgbẹ oṣelu MANIDEM lo kede iku Anicet laarọ ọjọ kin-in-ni, oṣu Kejila odun 2025.

Anicet Ekane to ku si ahamọ yii jẹ ọkan lara awọn to ṣe atileyin fun Issa Tchiroma Bakary, alatako Aarẹ Paul Biya, ninu ibo to wa ye loṣu Kẹwaa ọdun yii.

Awọn alaṣẹ lo ṣadeede gbe Anicet atawọn ọmọ ẹgbẹ alatako kan ni Douala, ti wọn gbe wọn lọ si ahamọ ni olu iu Cameroon ti i ṣe Yaoundé.

Ẹnikan to ba BBC sọrọ lori iku ojiji yii sọ pe Anicet ku si ile iwosan awọn ologun ti wọn gbe e lọ.

"A ko ri alaye kankan gbọ, wọn kan pe iyawo rẹ pe ko wa ni, nigba to si debẹ, wọn gbe oku ọkọ rẹ fun un."

O fi kun un pe awọn ẹbi ni wọn pada gbe oku naa lọ si ile igbokuusi.

Kí ló pa Anicet sí àtìmọ̀lé, ẹ̀ṣẹ̀ wo ló ṣẹ̀ tí wọ́n fi mú un?

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ologun, Ọgagun Cyrille Serge Atonfack, fi sita lo ti ni aisan lo pa Anicet, ẹni ọdun mẹrinlelaadọrin (74).

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"O ti pẹ diẹ ti wọn ti n tọju Oloogbe ti aisan oriṣiiriṣii n ṣe naa ni ileewosan awọn ologun, awọn dokita si n ṣetọju rẹ lati ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹwaa ti wọn ti fi ofin mu un."

Bẹẹ ni agbẹnusọ fun ileeṣẹ ologun naa wi.

Nipa ẹṣẹ ti Oloogbe Anicet Ekane ṣẹ ti ijọba fi ti i mọle, awọn agbẹjọro rẹ ṣalaye pe ijọba fi ẹsun aifẹran ilu rẹ kan an, pẹlu kikọ awọn ẹlomiran si ijọba, titako ijọba ati dida oju ija kọ ijọba.

"Wọn ko gbe e lọ siwaju adajọ kankan tabi fi ẹsun kan an ni kootu."

Ọkan lara awọn lọọya Oloogbe, Hippolyte Meli, lo sọ bẹẹ loju opo ayelujara.

O ṣapejuwe atimọle Anicet, olori ẹgbẹ MANIDEM bii eyi to lodi sofin.

Iku Oloogbe Anicet Ekane ti da jinni-jinni bolẹ ni Cameroon, bẹẹ ni ọpọ alatilẹyin rẹ ni wọn ti kora jọ si olu ile ẹgbẹ naa to wa ni Douala lati kẹdun rẹ.

Bakan naa ni ẹgbẹ rẹ ti kede pe awọn agbofinro ti yi ile olori ẹgbẹ to ku si ahamọ naa po.

Nigba aye rẹ, Anicet Ekane kọkọ ṣe atilẹyin fun Maurice Kamto lati di aarẹ.

Ṣugbọn ajọ eleto idibo Cameroon, ELECAM, ko gba Kamto wọle, wọn ni ẹgbẹ naa fa eeyan kalẹ ju ẹyọkan lọ.

Nigba naa ni Ekane ati awọn oloṣelu miran lọ da ẹgbẹ mi-in silẹ, eyi ti wọn pe ni Union for Change Coalition, nibẹ ni wọn si ti yan Issa Tchiroma Bakary bii oludije.

Íjọba Cameroon dárò ikú Anicet Ekane

Ninu atẹjade ti wọn fi sita lati daro ilu Oloogbe Anicet Ekane, Minisita fun eto iroyin ni Cameroon, René Emmanuel Sadi, ṣalaye pe o wulẹ ti rẹ Oloogbe ṣaaju ki ijọba to fi i si ahamọ.

O ni oriṣiiriṣii aisan lo ti n ṣe oloṣelu naa ko de atimọle lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹwaa, to si pada ja si iku loṣu Kejila.

Bo tilẹ jẹ pe Sadi ko sọ iru aisan to ni o n ṣe Anicet tẹlẹ, o ni o gba itọju to peye nileewosan awọn ologun to ku si.

"Lorukọ olori orilẹede, mo fi asiko yii ki ẹbi Oloogbe ati ẹgbẹ MANIDEM"

Bẹẹ ni Sadi, Minisita eto iroyin ni Cameeroon, daro iku naa lorukọ ijọba apapọ wọn.

O ni ijọba paapaa n ṣe iwadii ohun to fa iku Anicet.

Bakan naa ni wọn ni ki araalu ṣọra lori ikayasoke nitori iku Anicet Ekane, ko ma si ṣe di rogbodiyan kankan.

Àjọ EU àti àwọn mí-ìn korò ojú sí ikú Ekane

Ọpọ eeyan lo ti n koro oju si iku olori ẹgbẹ MANIDEM ti iroyin rẹ jade lowurọ oni.

Lara wọn ni ajọ European Union, to ni alafo nla ni iku Anicet Ekane yoo mu ba oṣelu Cameroon .

Wọn rọ ijọba lati ri si aabo ati alaafia awọn oloṣelu, ki wọn si fi gbogbo awọn to wa ni ahamọ latigba ti wọn ti dibo lọjọ kejila, oṣu Kẹwaa ọdun yii silẹ.

Ẹwẹ, gbajumọ lọya to maa n fi igba gbogbo bu ẹnu atẹ lu iwa ajẹbanu, Akere Muna, ti ṣapejuwe iku Ekane bii igba ti eeyan ba pa ina to nla to n jo lọwọ, bẹẹ ina naa n jo fun ijangbara ijọba awaarawa ni.

Muna, toun naa kuro ninu ere idije dupo aarẹ Cameroon, sọ pe Ekane ti sọ foun ri pe ara rẹ ko le to bo ṣe yẹ.

Ṣaa, ẹgbẹ MANIDEM ti ni ki awọn alatilẹyin awọn ṣe suuru, ki wọn si duro niṣọkan, maa reti ibi ti yoo yọri si.