Iná ṣẹ́yọ nílé alájà púpọ̀ ní Hong Kong, èèyàn 65 jáde láyé, ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ èèyàn míì di àwátì

- Author, Tiffany Wertheimer
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Eeyan marundinlaadọrin ti jade laye, nigba ti wọn ṣi n wa eeyan omilẹgbẹ eeyan mii lẹyin ina kan to ṣẹyọ nileegbe alaja pupọ kan ni Hong Kong, lorilẹede China.
Iroyin ni o ti fẹ ẹ le ni odidi wakati mẹrinlelogun ti ina ọhun bẹrẹ.
Bo tilẹ jẹ pe awọn oṣiṣẹ panapana n ṣiṣẹ takuntakun lati rẹyin rẹ, ina ọhun ṣi n jo kikankikan.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Nibo ati pe igba wo ni ina naa bẹrẹ?
Ina naa ṣẹyọ ni Wang Fuk Court, to jẹ ile nla ọlọpọ ero to ni aja mọkanlelọgbọn ni Tai Po, niluu Hong Kong.
Nnkan bii aago mẹta ọsan ku isẹju mẹsan an lo bẹrẹ lọjọru.
Ojule 1,984 lo wa nile naa ti nnkan bii 4,600 eeyan n gbe gẹgẹ bii eto ikaniyan ọdun 2021.
Ọdun 1983 ni wọn kọ ile ọhun amọ wọn n ṣe awọn atunṣe kan lara rẹ eyii ti wọn fi igi ọparun bo.
Awọn aworan lati ibẹ ṣafinhan bi ina ṣe n jo awọn ọparun naa kikankika.

Awọn wo lo n gbe ninu ile ọhun?
Ileegbe ti awọn arugbo pọ si ni iṣẹlẹ naa ti waye niluu Tai Po.
Awọn ile naa ti orukọ rẹ n jẹ Wang Fuk Court ni eeyan 4,600 n gbe.
Ninu eeyan 4,600 yii, 1,840 ninu wọn, to jẹ ida ogoji lo jẹ agbalagba ti ọjọ ori wọn ti le ni ọdun marundinlaadọrin.
Pupọ ninu wọn lo si ti n gbe nibẹ lati ibẹrẹ ọdun 1980 ti wọn ti kọ awọn ile ọhun.
Pupọ ninu wọn lo si ti n gbe nibẹ lati ibẹrẹ ọdun 1980 ti wọn ti kọ awọn ile ọhun.
Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe igba akọkọ ree ti ina yoo ṣẹyọ nile alaja pupọ ni Hong Kong, awọn alaṣẹ ni ina yii lo buru julọ lati ọgọta ọdun sẹyin.
Ijọba agbegbe naa ti sọ pe ile ẹkọ mẹtala to wa lagbegbe ti ina ọhun ti n jo ni wọn yoo gbe tipa titi ti wọn yoo fi rẹyin ina ọhun.
Ẹnikan to gbẹnusọ fun ijọba ni awọn yoo kọ awọn ile alaburada ti awọn eeyan le wa fun akoko diẹ titi wọn yoo fi rẹyin ina naa.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọwọ tẹ awọn afurasi
Lọwọ yii, ọwọ ọlọpaa ti tẹ eeyan mẹta ti wọn funra si pe wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ naa, wọn si ti fi ẹsun gbigbẹmi eeyan lairotẹlẹ kan wọn.
Awọn mẹta naa ti ọjọ ori wọn jẹ lati ọdun mejilelaadọta si mejidinlaadọrin ni wọn jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ to n kọ ile, meji ninu wọn jẹ adari nileeṣẹ naa nigba ti ẹnikẹta wọn jẹ amojuẹrọ.
Ọlọpaa ni awọn ri eroja 'mesh' ati 'Styrofoam' lara ile naa eyii to le jẹ ki ina tere jo daadaa.
Awọn oṣiṣẹ panapana ti juwe iṣẹlẹ naa bii 'level five alarm' to jẹ iṣẹlẹ ina to buru julọ.
Wọn ni yoo gba wọn ni odidi ọjọ kan ki wọn to le pa ina ọhun tan.
Wayi o, titi di asiko ti a n ko iroyin yii, ko tii si ẹni to le sọ ohun pato to ṣokunfa ina naa.
Jack Lau, BBC Global China Unit ati Gemini Cheng,to fi mọ BBC Chinese niluu Hong Kong fi kun iroyin yii.













