Ǹjẹ́ o mọ̀ pé fífi ẹ̀rọ ìlọta lọ ata tí ò ń jẹ ń ṣe àkóbá fún ìlera rẹ?

Aworan bi awọn eeyan ṣe n lọ ata pẹlu ẹrọ ilọ ata

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ iwadii ti ijọba apapọ, Federal Institute of Industrial Research to wa ni Oshodi nipinlẹ Eko, ti ni bi alekun ṣe n ba bi awọn kidinrin, ẹdọ ati awọn ohun ara mii ṣe n kọsẹ silẹ ni ara awọn eeyan lo ṣeeṣe ko jẹ nitori awọn ounjẹ ti wọn fi ẹrọ lọ ti ọpọ n jẹ.

Fifi ẹrọ lọ ounjẹ jẹ ohun to wọpọ ni orilẹede Naijiria, awọn ounjẹ bii ata, ogi, agbado, ati bẹbẹ lọ ni awọn eeyan ma n fi ẹrọ lọ, boya ẹrọ igbalode tabi ti ibilẹ.

Alaga FIIRO, Dokita Jummai Adamu Tutuwa, ninu atẹjade kan to fi ransẹ si awọn akọroyin, to si ṣalaye iwadii ileeṣẹ naa to ni ọpọ awọn aisan kidinrin, ẹdọ ati bẹbẹ lọ to n ba ọpọ finra lo jẹ pe o waye nitori awọ ounjẹ ti wọn jẹ to lọpọ mọ kẹmika kan to n jade lati inu ẹrọ ilọ ounjẹ yii.

O ni iwadii FIIRO to waye ni ọdun 2013 ri pe ẹrọ ti wọn n fi lọ tomato, ata, alubọsa, ẹgusi ati awọn ounjẹ mii, paapa ni awọn agbegbe kan nipinlẹ Eko, ni kun fun awọn irin bii lead, copper, chromium, nickel, cadmium, ati manganese, pẹlu awọn ohun mii to n ṣe akoba ni ara bii calcium, magnesium, zinc, ati iron.

Gẹgẹ bii o ṣe ṣalaye, jijẹ awọn ounjẹ yii ṣe fa ki awọn ẹdọ, kidinrin ati awọn mii da iṣẹ silẹ ni ago ara, koda eyi wọpọ laaarin awọn ọdọ.

Dokita Tutuwa ni awọn eroja buburu yii lo ma n ko sinu ounjẹ lasiko ti wọn ba n lọ ounjẹ ninu ẹrọ yii.

Ọpọ awọn eeyan ni ko mọ eyi to si jẹ ohun gan ni orison ọpọ awọn iṣoro ilera to n ba ọpọ finra .

"Awọn eroja bii Zn, pPb Fe, ati Cu wa ni agbegbe wa, ti wọn si kopa ribiribi ni ayika wa ṣugbọn wiwa ninu ounjẹ wa lo da bi majeje jijẹ."

Dokita tẹsiwaju pe lati dẹkun iṣoro yii, ajọ FIIRO ti ṣeda ẹrọ mii t imo adikun ba awọn eroja yii ṣe n da sinu ounjẹ lasiko ti wọn ba n lọ ounjẹ.