Ẹ̀rín àríntàkìtì bí Màmá Deola ṣe kópa lórí ètò Só o Láyà
Yoruba dun, o si larinrin fun ẹni to ba gbọ ọ, to si tun mọ ọ.
Bi BBC News Yoruba se gba gbajumọ alawada lori ayelujara kan, Folagbade Banks, ti ọpọ eeyan mọ si Mama Deola ni alejo.
O tun ba wa kopa lori eto wa ti a ti n se idanwo fawọn alejo wa ni BBC News Yoruba lati mọ bi wọn se dantọ si lori eto Yoruba.
Eto naa ni a n pe ni Soo Laya.
Mama Deola se bẹẹ, to si sọ eto naa di ti awada patapata.
Ẹ darapọ mọ wa lati rẹrin arintakiti lori eto So o Laya ti oni.

Oríṣun àwòrán, Abiri Tobi Festus/ Instagram
Ta a lo n jẹ Mama Deola?
Abiri Tobi Festus ni orukọ abisọ Mama Deola to si tun n jẹ Folagbade Banks lori ayelujara.
Ọkunrin ni amọ o maa n mura, sọrọ bii obinrin lasiko to ba n se bii Mama Deola, to si n dẹrin pa Osonu.
Mama Deola yatọ si awọn alawada ori ayelujara yoku nitori akọ to n se bi abo ni, yoo wọ asọ obinrin, we gele, wọ bata.
Mama Deola tun maa n so okun nla kan mọ inu, ti yoo si maa sọrọ bi awọn abilekọ se maa n se ninu ile.
Nigba to n salaye idi to se n mura bẹẹ, mama Deola ni oun n se bii ọpọlọpọ mama se maa n huwa ninu ile ni, si awọn ọmọ ati ara adugbo.
Yatọ si pe Mama Deola jẹ adẹrinposonu, o tun maa n se isẹ adari eto lagbo ariya, bakan naa lo tun jẹ gbajumọ osere.

Oríṣun àwòrán, Abiri Tobi Festus/ Instagram






