Ṣó o láyà? Tope Osoba fakọyọ nínú ìmọ̀ èdè Yoruba
Gbajumọ oṣere, Tope Osoba ti farahan lori eto Ṣoolaya BBC News Yoruba.
Ori eto Ṣoola yii ni BBC ti maa n dan gbajumọ lawujọ wo lati mọ bi wọn ṣe gbọ ede Yoruba to.
Fun ti ọsẹ yii, Tope Osoba gbiyanju, o si fi han pe ọmọ Yoruba atata ni ohun.

Oríṣun àwòrán, Tope Osoba
Ta ni Tope Osoba?
Ọkan lara awọn oṣere tiata ti irawọ rẹ n milẹ titi lọwọ yii ni Tope Osoba.
Ẹnu aipẹ yii ni oṣere naa ṣiṣẹ abẹ jẹjẹrẹ ọmu, o si ṣalaye pe akoko naa ko rọrun fun oun rara.
Ninu ifọrọweọ pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC Yoruba o ni asiko ti oun yẹ ara oun wo gẹgẹ bii imọran awọn dokita loun ṣakiyesi nnkan to wa ninu ọmu oun ki awọn oniṣegun to fidi rẹ mulẹ pe jẹjẹrẹ ọmu ni.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, aduroti awọn akẹgbẹ rẹ nidi iṣẹ tiata atawọn oloju aanu mii lo jẹ ki iṣẹ abẹ naa ṣe aṣeyọri.
Wo fido oke yii fun itu ti Tope osoba pa lori eto Ṣoolaya.



