Wo iléẹ̀kọ́ àwọn olóyún tí wọn ti ń gba àmì ẹ̀yẹ fún ijó jíjó, oge ṣíṣe àti ìmọ́tótó

Àkọlé fídíò, Wo iléẹ̀kọ́ àwọn olóyún tí wọn ti ń gba àmì ẹ̀yẹ fún ijó jíjó, oge ṣíṣe àti ìmọ́tótó
Wo iléẹ̀kọ́ àwọn olóyún tí wọn ti ń gba àmì ẹ̀yẹ fún ijó jíjó, oge ṣíṣe àti ìmọ́tótó

Isẹ nla ni oyun nini nitori nigba miran, o maa n mu ẹmi lọ, paapaa nilẹ Afirika.

Akọsilẹ iku awọn alaboyun si fihan pe o kere tan, eeyan kan ninu ẹgbẹrun lọna gọrun alaboyun lo maa n rọrun lọjọ ikunlẹ.

Ọna lati mu adinku ba iku awọn alaboyun yii si lo mu ki wọn da ile ẹkọ awọn oloyun silẹ ni agbegbe Parambo ni orilẹede Ghana.

Pataki ile ẹkọ naa si ni lati mu ki awọn oloyun kopa ninu oniruuru ere idaraya ati apanilẹrin bii ijo jijo, irin oge, oge sise ati imọtoto.

Awọn ere idaraya yii si ni afojusun wọn wa lati mu ki ara alaboyun ji pepe, ki ọkan rẹ balẹ, ki ilera rẹ si wa nipo to dara lọjọ ikunlẹ.

Bakan naa ni wọn tun n gba ami ẹyẹ nile ẹkọ alaboyun naa ninu awọn ere idaraya ti wọn ti n kopa.

BBC wa de ile ẹkọ naa lati mọ bi awọn alaboyun ti n dara ya si ati ipa to n ni lọjọ ikunlẹ wọn.

Awọn oloyun to n sere idaraya nibudo awọn oloyun

O le ni ọgọta awọn oloyun ti a ri, wọn n kọrin, wọn n jo, fo soke, ti wọn si n fi tayọ tayọ ati ẹrin se awọn ere idaraya naa

BBC wa de ile ẹkọ naa lati mọ bi awọn alaboyun ti n dara ya si ati ipa to n ni lọjọ ikunlẹ wọn.

Nigba ti BBC kan si ibudo ilera alabọde to wa ni agbegbe Parambo ni orilẹede Ghana ti ile ẹkọ naa wa, o le ni ọgọta awọn oloyun ti a ri, ti wọn wa fun ere idaraya naa.

Ṣe ni wọn n kọrin, ti wọn n jo, fo soke, ti wọn si n fi tayọ tayọ ati ẹrin se awọn ere idaraya naa.

Koda, a ri lara awọn ọkọ awọn oloyun naa ti wọn tẹle awọn iyawo wọn wa si ile ẹkọ naa.

Awọn oloyun to n sere idaraya nibudo awọn oloyun

Ki o le rọrun fun iyawo mi lati bimọ ni mo se n sin wa si ile ẹkọ oloyun tori o nira fun tẹlẹ lati bimọ - Ọkọ Oloyun

Nigba to n ba BBC sọrọ, Arabinrin Sophia aya Mumuni to jẹ alaboyun ni inu oun dun lati wa sile ẹkọ naa.

Bakan naa, ọkan lara awọn ọkọ to tẹle iyawo wọn wa sile ẹkọ naa, Fuseini Alhassan ni inu oun maa n dun lati tẹlẹ iyawo oun wa sibẹ nitori yoo jẹ ki o rọrun fun lati bimọ.

"Nigba to bimọ tẹlẹ, ko rọrun fun rara, nnkan le fun ko to bimọ, mo si lero pe yoo rọrun fun lati bimọ lọtẹ yii tori pe o n wa si ile ẹkọ awọn alaboyun naa."

Nigba ti awọn osisẹ ibudo ilera alabọde naa n ba akọroyin BBC sọrọ, wọn ni alekun ti ba akọsilẹ iye alaboyun to n wa gba itọju nibẹ nitori agbekalẹ ile ẹkọ awọn oloyun yii.

Wọn ni ilọpo mẹta ni alekun to ba awọn oloyun naa lati ọdun mẹta ti ile ẹkọ awọn alaboyun naa ti wa.