Iléeṣẹ́ Ààrẹ fèsi lóri ẹsun òògùn olóró tí àjọ FBI ati DEA wádìí nipa Tinubu

Oríṣun àwòrán, President Bola Tinubu/ Facebook
Ileeṣẹ aarẹ orilẹede Naijiria ti sọrọ lori aṣẹ ti ile ẹjọ ilẹ America kan pa, pe ki ajọ atọpinpin Federal Bureau of Investigation (FBI) ati Drug Enforcement Administration, DEA), gbe iwadii wọn lori Aarẹ Bola Tinubu jade.
Ile ẹjọ to fidi kalẹ si Columbia naa paṣẹ yii lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin ọdun 2025.
O paṣẹ pe ki ajọ mejeeji gbe ohun ti wọn mọ nipa oogun oloro ti wọn ni Aarẹ Tinubu lọwọ ninu rẹ sita.
Nigba to n fesi si aṣẹ naa, agbẹnusọ Aarẹ Tinubu, Bayo Onanuga, kede loju opo X rẹ lọjọ Aiku, pe ko si kinni kan ti FBI ati DEA le ri gbe jade nipa Aarẹ.
Onanuga sọ pe,
" Ko si nnkan kan ti wọn fẹẹ gbe jade.
"Abọ iwadii Moss to ṣojuu FBI ati DEA ti wa nibi ti gbogbo eeyan ti le ri, o ti ju ọgbọn ọdun lọ to ti wa nibẹ.
"Ko si ohun kan to tọka ibajẹ nipa Aṣiwaju Naijiria nibẹ. Awọn amofin n yẹ idajọ yii wo lọwọ"
Bẹẹ ni Onanuga kọ soju opo naa.
Kí ni ìdájọ́ kóòtù wí ?
Ninu idajọ naa to wa loju opo ayelujara kootu ọhun, Adajọ Beryl Howell, paṣẹ pe FBI ati DEA gbọdọ ṣiṣẹ lori iwe kan ti wọn pe ni Freedom of Information Act (FOIA).
Ọmọ ilẹ America kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Aaron Greenspan, lo mu iwe naa wa bi wọn ṣe wi.
Kootu naa tun paṣẹ pe abajade kan ti wọn pe ni "Glomar responses", ti wọn ti kọkọ fi dahun ko wulo mọ.
Ni 2022 ati 2023, Greenspan to jẹ oludasilẹ ileeṣẹ PlainSite, beere fun akọsilẹ iwadii nipa Tinubu, Lee Andrew Edwards, Mueez Adegboyega Akande, ati Abiodun Agbele, ti wọn ni ikọ to n gbe oogun oloro ni wọn.
Greenspan gbe ẹsun mejila FOIA lọ si kootu mẹfa ọtọọtọ l'America, eyi ti FBI ati DEA jẹ ara wọn.
Ohun to n beere ni pe ki wọn gbe esi iwadii jade nipa awọn ikọ oloogun oloro Chicago ti wọn n fa gbuuru laaarin ọdun 1990 sisalẹ.
Awọn ẹka mi-in to tun kọwe si ni United States Department of State, Central Intelligence Agency (CIA), Internal Revenue Service (IRS), ati Executive Office of United States Attorneys (EOUSA).
Gẹgẹ bi kootu ṣe wi, marun-un ninu awọn to kọwe si naa sọ pe awọn ko le sọ pe akọsilẹ ti Greenspan n beere fun wa tabi ko si.
Awọn ni ti Glomar .
Eyi lo mu Greenspan tun pe ẹjọ miran lati koju awọn ajọ yii.
Ninu idajọ rẹ lọjọ Iṣẹgun, Adajọ Howell paṣẹ pe abajade Glomar ti FBI ati DEA gbe jade ko ṣiṣẹ mọ.
O ni wọn gbọdọ wa omiran sọ.
Kí ló kàn?
Ohun ti ọpọ eeyan gbagbọ ni pe FBI ati di DEA yoo tẹle aṣẹ ile ẹjọ, wọn yoo gbe akọsilẹ orukọ awọn ti wọn fẹsun kan yii jade.
Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ aarẹ Naijiria sọ pe awọn amofin ṣi n yẹ idajọ kootu naa wo lọwọ.
Ohun ti a ko mọ ni boya wọn yoo sọrọ lẹyin agbeyẹwo awọn amofin.
Tẹ o ba gbagbe, o ti pẹ ti ọrọ nipa ẹsun oogun oloro yii ti n ja nilẹ nipa Aarẹ Bola Tinubu.
Eyi si wa lara ohun ti awọn alatako rẹ ninu oṣelu fi koju rẹ lasiko ipolongo ibo aarẹ to gbe e wọle ni 2023.














