Kókó mẹ́fà nípa ìgbésí ayé Brice Oligui Nguema, ṣọ́jà adìtẹ̀gbàjọba tó di ààrẹ alágbádá nílẹ̀ Gabon

Aworan Nguema ati awọn ṣọja ninu ọkọ nigba ti wọn gbajọba ni 2023

Oríṣun àwòrán, EPA-EFE/REX/SHUTTERSTOCK

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Gbogbo aye lo ti gbọ bayii, pe igba tuntun ti de si Gabon, pẹlu ṣọja to di aarẹ adibo yan ni Satide to kọja yii, Brice Oligui Nguema.

Lẹyin to le aarẹ tẹlẹ lorilẹede naa, Ali Bongo, kuro lori oye ni 2023, awọn ọdọ ilu gbe e kọrun, wọn si n kọrin fun un pe "Aarẹ Oligui"

Latilẹ wa ni Ọgagun Nguema ti jẹ ẹni ti awọn eeyan Gabon nifẹẹ si, awọn ọmọ ogun rẹ paapaa si bọwọ fun un gidi.

Ni bayii, wọn ti fun un ni anfaani lati tukọ orilẹẹde naa fun ọdun meje gbako, lẹyin to bori ibo ti ida aadọrun-un eeyan (90%) di fun un.

Ṣugbọn ta a gan-an ni Ọgagun Brice Oligui Nguema yii?

Eyi ni itan igbesi aye ṣọja to ditẹ gbajọba ni 2023, to pada waa di aarẹ gan-an ni 2025 lorilẹede Gabon.

Ìgbà èwe rẹ̀

Ọgagun Brice Oligui Ngueme

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Wọn bi Brice Oligui Nguema ni Guusu-Ila Oorun Haut-Ogooué, ni Gabon.

Ibi ti wọn ti bi i yii jẹ agbegbe ti awọn ẹbi Bongo to ti ṣejọba ilu naa fun ọgọta ọdun pọ si.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn kan tilẹ sọ pe ibatan Ali Bongo ni Nguema paapaa.

Oligui Nguema fi iṣẹ ṣọja jọ baba rẹ, ọmọde lo wa to ti gba ibi iṣẹ ologun lo.

Nguema darapọ mọ Gabon Republican Guard, lẹyin to ti kẹkọọ ni gbaju-gbaja ileeṣẹ ologun Morocco ti i ṣe Meknes Royal Military Academy ni 1997 .

Ko pẹ to fi di amugbalẹgbẹẹ fun Aarẹ Omar Bongo, iyẹn baba to bi Ali Bongo.

Nguema ṣiṣẹ pẹlu aarẹ tẹlẹ naa titi to fi ku ni 2009 ni.

Nigba ti Ali Bongo gba ipo aarẹ lọwọọ baba rẹ ni 2009, o le Nguema kuro nipo amugbalẹgbẹẹ to wa, ṣugbọn wọn yan an bii ologun ti yoo maa ṣiṣẹ nilẹ ibo mi-in.

Bayii ni Nguema ṣe kuro ni Gabon to si gbe ni Morocco ati Senegal fun ọdun mẹwaa gbako.

Bo tilẹ jẹ pe awọn iroyin adugbo n sọ ọ nigba naa pe wọn le e jade ni Gabon ni, ifẹ rẹ fun ilu abinibi rẹ jẹ ko pada wa, gẹgẹ bi wọn ṣe ka a nigba ti wọn n gbe e sipo aarẹ to ditẹ gba ni 2023.

2018 ni Nguema tun pada si Gabon, o si rọpo ọbakan aarẹ to di ipo ṣoja nla mu.

Lẹyin oṣu mẹfa, Nguema di ṣọja to n ṣiṣẹ bii adari agba.

Ni 2019, o gbe eto kan kalẹ to pe ni "clean hands" operation, eyi to wa fun yiyẹ ọwọ awọn to wa nijọba wo boya wọn n ṣowo ilu mọkumọku.

Ṣugbọn awọn kan tun fẹsun kan an pe oun naa n kowo ilu pamọ.

Ìjọba ológun fagilé ìbò tí wọ́n dì ní 2023, fi Nguema ṣe ààrẹ fìdí-hẹ-ẹ́

Awọn ọdọ ilu Gabon kun fun ayọ lẹyin ti Nguema bori ninu ibo aarẹ

Oríṣun àwòrán, Rex/Shutterstock

Àkọlé àwòrán, Awọn ọdọ ilu Gabon kun fun ayọ lẹyin ti Nguema bori ninu ibo aarẹ

Ọgbọnjọ oṣu Kẹjọ ọdun 2023, lẹyin ti wọn dibo tan ni Gabon ni ṣọja kede pe awọn fagile ibo naa.

Wọn fi Ali Bongo si ahamọ abẹle, wọn si kede Ọgagun Brice Clothaire Oligui Nguema bii aarẹ fidi-hẹ-ẹ.

Ṣugbọn ohun to foju han ni pe iṣakoso awọn iran Bongo to sọ ipo aarẹ di oye idile ti su awọn araalu naa.

Eyi lo fa a ti wọn fi sowọpọ pẹlu ṣoja to lewaju iditẹ gbajọba naa, ti wọn si pada dibo fun un gidi lọjọ Abamẹta to kọja.

Ajọ UN ati France koro oju si iditẹgbajọba naa ti i ṣe ẹlẹẹkẹjọ iri u rẹ to waye ni ẹkun-un Ila Oorun ati Aarin gbungbun Africa lati ọdun 2020.

Ṣugbọn araalu nifẹẹ Oligui Nguema, ẹni aadọta ọdun, ṣọja to so wọn pọ to si ṣeleri ọrọ aje ọtun fun wọn.

Nguema loun yoo tun ijọba ṣe, koju ẹlẹyamẹya, mu idẹrun ba owo ile gbigba, bẹẹ ni awọn ọmọ Gabon to wa lẹyin odi yoo le pada wale.

Gẹgẹ bii ẹni ti wọn ti fẹsun kiko owo ilu jẹ kan nigba to n ṣiṣẹ pẹlu ijọba awọn Bongo, Nguema n gbiyanju lati mu ayipada rere ba Gabon, ki igbe aye irọrun si ba awọn eeyan ibẹ gbogbo.

Àkọlé fídíò, Wo iléẹ̀kọ́ àwọn olóyún tí wọn ti ń gba àmì ẹ̀yẹ fún ijó jíjó, oge ṣíṣe àti ìmọ́tótó
Ọgagun Brice Oligui Nguema to bori idibo Gabon, ti yoo tukọ ilu naa fun ọdun meje ree

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ọgagun Brice Oligui Nguema to bori idibo Gabon, ti yoo tukọ ilu naa fun ọdun meje ree

Ológun tó dìtẹ̀ gbàjọba Gabon gbégbá orókè nínú ìdìbò ààrẹ

Ọgagun Brice Oligui Nguema, olori awọn ṣọja to gbajọba lorilẹede Gabon ni 2023 ti bori ninu ibo aarẹ ti wọn di lọjọ Abamẹta.

Nguema to fidi awọn ondupo yoku janlẹ pẹlu ibo to to ida aadọrun( 90%) lo lewaju iditẹ gbajọba to le idile to ti n wa nipo aarẹ fun ọgọta ọdun kuro lori ipo naa ni Gabon.

Ṣaaju ibo yii ni awọn kan ti sọ pe ilana ti wọn gbe e gba yoo fi aaye gba Nguema lati gbegba oroke nirọrun.

Ati pe wọn ti mu awọn alatako ti ko ba dena rẹ kuro lọna ki idibo too waye rara.

Nguema, ẹni aadọta ọdun, lo lo agbara rẹ gẹgẹ bii ṣọja lati le aarẹ Ali Bongo to wa nipo aarẹ ilu naa ni 2023.

Bẹẹ lati ọdun 1967 ni idile awọn Bongo ti n jẹ aarẹ Gabon.

Lara awọn ti wọn jọ dupo aarẹ yii ni, Olootu ijọba; Alain Claude Bilie-by-Nze, ẹni to ba Bongo ṣiṣẹ, pẹlu awọn eekan meji mi-in ninu ẹgbẹ PDG, iyẹn Stéphane Germain Iloko ati Alain Simplice Boungouères.

Báwo ni Nguema ṣe jáwé olúborí?

Nigba to n ṣalaye nipa bi Nguema ṣe gbegba oroke ninu idibo naa, Minisita fun ọrọ abẹle ni Gabon, Hermann Immongault, sọ pe ọpọlọpọ eeyan lo dibo fun un.

"Wọn dibo fun Brice Clotaire Oligui Nguema pẹlu iye ibo ti i ṣe 575,222 "

O ni diẹ ni alatako rẹ, Bilie-by-Nze, fi ri ibo to le diẹ ni ida mẹta.

Aṣeyọri yii tun waye pẹlu bi ida eeyan to ju meje lọ ṣe dibo lẹyin iforukọsilẹ, eyi ti awọn onwoye ibo kan saara si gidi.

Wọn ni ibo naa ko ruju, o si lọ ni irọwọrọsẹ.

Pẹlu aṣeyọri yii, Nguema yoo lo ọdun meje lati tukọ Gabon, ko si ṣe atunṣe si awọn ohun ti wọn ni Bongo bajẹ ni saa tirẹ.

Orilẹede ti ko fi bẹẹ tobi ni Gabon, ṣugbọn wọn ni epo ati Timber bii nnkan alumọni.

Aarin gbungbun ilẹ Africa lo wa, eeyan ibẹ ko si ju miliọnu meji aabọ lọ.( 2.5 million people)

Ṣugbọn pẹlu nnkan amuṣọrọ ti wọn ni yii naa, o ṣi fẹrẹ to ida marundinlogoji (35%) eeyan ti ìṣẹ́ n ṣẹ nibẹ.

Ìbò kíka bẹ̀rẹ̀, aráàlú ń retí ìkéde ààrẹ tuntun ní Gabon

Àwọn tó ń ka èsì ìbò

Níṣe ni àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè Gabon ń retí èsì ìbò ààrẹ èyí tí ìgbàgbọ́ wà pé wọ́n máa kéde ní ọ̀sán ọjọ́ Àìkú.

Ní kété tí ìbò dídì ti parí ní ọ̀sán ọjọ́ Àbámẹ́ta ni ìbò kíkà ti bẹ̀rẹ̀ táwọn èèyàn sì ti ń retí ìkéde ẹni tọ gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò náà.

Àwọn èsì ìbò tó ti jáde ṣàfihàn pé olùdíje Brice Oligui Nguema, ọ̀gágun tó fipá gba ìjọba lọ́wọ́ ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí Ali Bongo lọ́dún 2023, ló ń léwájú níbi ètò ìdìbò ọ̀hún.

Iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ abẹ́lé ló máa kọ́kọ́ kéde èsì ìbò náà kí àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ òfin orílẹ̀ èdè náà tó gbé ìkéde ẹni tó wọlé ìbò síta nígbà tí wọ́n bá yanjú gbogbo kùdìẹ̀kudiẹ tó bá jẹyọ lásìkò ìbò náà.

Ṣáájú ètò ìdìbò yìí, àwọn lámèyítọ́ ní níṣe ni wọ́n ṣe ìwé òfin àti òfin ètò ìdìbò lọ́nà tó máa fún àwọn tó fipá gba ìjọba láàyè láti dé ipò ààrẹ ní ìrọ̀rùn.

Àwọn alátakò tí wọ́n le gbéná wojú Oligui Nguema níbi ètò ìdìbò náà ni wọ́n ti yọ kúrò, tí wọn kò sì ní àǹfàní láti kópa níbi ètò ìdìbò náà.

Lára àwọn iṣẹ́ tí ẹnikẹ́ni tó bá jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò náà yóò kojú ni fífi òpin sí ìwà àjẹbánu, fífi òpin sí ètò ìṣèjọba tí kò dára àtàwọn ìwà ìbàjẹ́ míì tó gbilẹ̀ lásìkò ìṣèjọba àwọn ẹbí Bongo.

Ètò ìdìbò Ààrẹ Gabon bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu

Aworan awọn oludibo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Eto idibo fun ipo aarẹ ti bẹrẹ bayii lorilẹede Gabon, ti ọpọ araalu si ti n jade sita lati yan olori tuntun lẹyin ọdun meji ti iditẹgbajọba waye, ti wọn si yọ Aarẹ Ali Bongo.

Aarẹ Ologun fun orilẹede naa, Brice Oligui Nguema, ti ṣe ileri ṣaaju pe, oun yoo da ijọba pada si ijọba awaarawa – amọ o tun wa lara awọn oludije to n dije dupo naa, to si ti n fojuhan pe, o ṣeeṣe ko bori eto idibo naa.

O n figagbaga pẹlu oludije meje mii, to fi mọ olootu ijọba orilẹede naa tẹlẹ, Alain Claude Bilir-By-Nze.

Iṣẹlẹ iditẹgbejọba naa waye ni ọdun 2023, eyi to fopin si aadọta ọdun ti idile Bongo ti n ṣe ijọba orilẹede naa.

Lara ohun to jẹ ki ọpọ eeyan gbagbọ pe Nguema ni o ṣee ṣe ko wọle ibo aarẹ ọjọ Satide ni pe, Alain-Claude Bilie-By-Nze to jẹ olootu ijọba Aarẹ Bongo ni oludije to tun fẹẹ lẹnu julọ ninu gbogbo awọn alatako rẹ.

Ọdun meje ni ẹni to ba jawe olubori ninu eto ibo aarẹ ọjọ Abamẹta yoo lo lori aleefa.

Eeyan bii miliọnu meji ati abọ lo wa ni Gabon, orilẹede naa si wa lara awọn orilẹede to ni epo rọbi ati okuta iyebiye ''manganese.''

Yatọ si rogbodiyan lẹyin eto idibo gbogbogbo to ṣẹlẹ ni Libreville ti i ṣe olu ilu Gabon lọdun 2016, alaafia ti jọba ni Gabon fun ọpọlọpọ ọdun sẹyin bayii.

Ọgbọnjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 ni Nguema atawọn ọmọ ogun rẹ ditẹ gbajọba lorilẹede Gabon, lẹyin ti ajọ eleto idibo fẹẹ kede laarin oru wi pe Aarẹ Ali Bongo Ondimba ti wọle ibo aarẹ fun saa kẹta.

Aworan