Ẹbí kéde bí ètò ìsìnkú Abisola, ọmọ Ajimobi yóò ṣe lọ

Aworan Abisola Kola Daisi

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Mọlẹbi Kola-Daisi ti kede bi eto isinku akọbi ọmọ gomina ana nipinlẹ Oyo, Abisola Kola-Daisi yoo ṣe waye.

Ni ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹta ni ẹni to jẹ akọbi ọmọbinrin fun gomina ipinlẹ Oyo nigba kan, oloogbe Abiola Ajimobi, jade laye.

Owurọ Ọjọbọ ọjọ kẹtadinlọgbọn ni iroyin nipa iku Abisola Kola-Daisi, jade si ori ayelujara.

Arabinrin Abisola Kola-Daisi, ni iroyin sọ pe o dagbere fun aye lẹni ọdun mẹrinlelogoji.

Iku rẹ waye lẹyin ọdun mẹrin ti baba rẹ, oloogbe Abiola Ajimobi, to jẹ gomina ipinlẹ Oyo nigba kan ri, jade laye.

Ṣaaju iku rẹ, Bisola jẹ oludamoran pataki fun minisita to wa fun owo iṣuna, Atiku Bagudu.

Bakan naa lo jẹ iyawo fun Kolapo Kola-Daisi, ọmọ ọkan lara awọn oloye agba ilẹ Ibadan.

Oun naa si ni ọmọbinrin to dagba julọ ni awọn ọmọ Abiola ati Florence Ajimobi.

Ọmọ mẹta ni Bisola bi nigba aye rẹ.

Orukọ inagijẹ ti ọpọ mọ Abisola si ni Abi-KD nigba aye rẹ.

Aworan eto isinku Abisola Kola Daisi

Oríṣun àwòrán, Others

Eto isinku yoo bẹrẹ pẹlu orin ati iyin lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2025, ti yoo ni ile itura Eko Hotels.

Bakan ni adura fun oku yoo waye ni ile ijọsin, Redeemed Christian Church of God (RCCG) City of David, Trinity Tower, to wa ni opopona Yesufu Abiodun Oniru , Victoria Island, nipinlẹ Eko.

Lẹyin naa ni wọn o gbe ara rẹ lọ si itẹ oku fun isinku. Ṣugbọn ṣa, eto eyi ko si fun awọn ti kii ṣe ẹbi.