Àwọn olórin tó kọrin lórí bí ìlú ṣe rí sẹ́yìn tí ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé orin wọn

Aworan awọn agbaọjẹ olorin

Oríṣun àwòrán, Fela Kuti/Instagram/Evang Niyi Adedokun/Hubert Ogunde/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ọpọ eeyan lori ayelujara lo si n sọ ero wọn lori bi ajọ NBC to n mojuto igbohunsafẹfẹ ni Naijiria ti fofin de awọn ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ - redio ati tẹlifisan – pe wọn ko gbọdọ gbe orin "Tell Your Papa", ti ogbontarigi akọrin takasufe, Eedris Abdulkareem, gbe sita lori afẹfẹ mọ.

Kii ṣe Eedris Abdulkareem nikan ni ijọba ti gbẹsẹ le orin to gbe sita Naijiria, awọn akọrin kan naa ti fara kaasa sẹyin lọwọ ijọba lẹyin ti wọn ko orin lori bi ilu ṣe ri.

Koda, awọn mii wa tiẹ wa ninu wọn ti wọn tun dero atimọle tori ijọba ni wọn kọrin tako awọn alaṣẹ ijọba.

Wọnyi ni awọn olorin ti ijọba ti fofin de orin wọn tẹlẹ ri ni Naijiria:

Fela Kuti

Lọdun 1989 ni ijọba ologun labẹ alaṣẹ Ogagun Ibrahim Babangida to ti fẹyin ti bayii fofin de orin ti gbajugbaja akọrin AfroBeat, Fela Anikulapo Kuti, to pe akọle rẹ ni ''Beast of No Nation.''

Idi ti ijọba fi gbẹsẹ le orin naa ni pe wọn lo tako ijọba ologun, iwa ifiyajẹni ati iwa ika to gbode nigba naa kaakiri orilẹede Naijiria.

Fela sọ ninu orin ọhun pe awọn ologun to n ṣejọba dabi ẹranko to gbe awọ eeyan wọ lasan, eyi to tumọ si pe wọn n huwa ipa ati iwa ibajẹ, wọn ko si tun ni aanu araalu loju.

Ilumọọka olorin ati ajafẹtọọ ọmọniyan naa bu ẹnu ẹtẹ lu ijọba ologun nigba naa wi pe wọn o bikita nipa araalu, bẹẹ ni wọn o si sọ ododo.

Bo tilẹ jẹ pe tita ko ijọba ologun nigba naa le jẹ ki eeyan dero ẹwọn, Fela duro lori ẹsẹ rẹ pẹlu orin to kọ eyi ti ijọba ologun ri gẹgẹ bi idunkoko mọ ijọba to wa lode.

Aimọye igba ni Fela dero atimọle lori wi pe orin to gbe sita tako ijọba orilẹede Naijiria.

Hubert Ogunde

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gbajugbaja oṣere ori itage ati akọrin, Hubert Ogunde, to ti di oloogbe wa lara awọn akọrin ti ijọba kọkọ fofin de orin ti wọn gbe sita lẹyin ti orilẹede Naijiria gbominira tan lọdun 1960.

Ọdun 1964 ni Ogunde gbe orin ati ere kan jade eyi to pe akọle rẹ ni ''Yoruba Ronu.''

Orin ati ere naa da lori aawọ to bẹ silẹ laarin Oloye Ladoke Akintola to jẹ Olootu ijọba iwọ oorun guusu Naijiria ati Oloye Obafemi Awolowo to jẹ adari ẹgbẹ Action Group nigba naa.

Ijọba Akintola ko foju ire wo Ogunde pẹlu orin to gbe jade ọhun, eyi lo si jẹ ki ijọba iwọ oorun guusu Naijiria nigba naa fofin de ẹgbẹ oṣere Ogunde wi pe wọn o gbọdọ kọ orin Yoruba Ronu tabi fi ṣere fun ọdun meji.

Bakan naa, ni ijọba tun sọ pe awọn ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ naa ko gbọdọ lo orin ọhun lori afẹfẹ.

Iru igbesẹ yii tẹsiwaju laye ijọba awọn ologun pẹlu bi wọn ṣe n fofin de ọkan o jọkan orin to ba ti da lori bi ilu ṣe ri.

Ogunde maa n lo orin ati ere to n ṣe nigba aye rẹ lati tako iwa ibajẹ ninu ijọba ati lawujọ ki araalu ba le gbaye gbadun.

Niyi Adedokun

Ajinjinrere Niyi Adedokun ṣe oniruuru awo lọpọ ọdun sẹyin papaa julọ lasiko ijọba ologun ni Naijiria, eyi to fi n beere fun eto iṣejọba ti yoo maye dẹrun fun araalu.

Akọrin ẹmi Adedokun fi igboya sọrọ si ijọba ologun Naijiria lori iwa ibajẹ atawọn iwa ọdaran mii ti wọn n hu.

Bakan naa ni o tun bu ẹnu ẹtẹ lu ajọ awọn ọmọlẹyin Kristi CAN atawọn ajọ mii lori bi wọn ko ṣe tako ijọba ologun to wa lode nigba naa.

Okiki tiẹ kan lasiko kan pe Ajagun fẹyinti Babangida to jẹ olori orilẹede lasiko naa fi miliọnu meji naira ati ọkọ ayọkẹlẹ Peugeot 504 ranṣẹ si Ajihinrere Adedokun wi pe ko maa kọrin ki Babangida ko si maa fi orin rẹ sọ fun araalu pe ijọba IBB yoo so ero rere.

Amọ, ohun ti a gbọ ni pe akọrin Adedokun kọ lati gba owo ati ọkọ naa, o si tun sọ pe ki IBB parẹ pẹlu owo ati ọkọ naa.

Wo àwọn olórin tí àjọ NBC ti fòfin dè orin wọn ṣaájú orin "Tell Your Papa'' Eedris Abdulkareem

Aworan Wizkid, Tiwa Savage ati Davido

Oríṣun àwòrán, Instagram

Awuyewuye si n lọ lori bi ajọ to n ṣe amojuto igbohunsafẹfẹ ni Naijiria, National Broadcasting Commission (NBC), ti fofin de awọn ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ - redio ati tẹlifisan – pe wọn wọn o gbọdọ gbe orin "Tell Your Papa", ti ogbatarigi akọrin takasufe, Eedris Abdulkareem, gbe sita lori afẹfẹ mọ.

Lọjọ kẹsan an oṣu Kẹrin yii ni ajọ NBC sọ ninu atẹjade kan to fi sita pe orin naa ni awọn ọrọ to tọka abuku si ẹnikan ninu.

Ṣugbọn kii ṣe igba akọkọ ti ajọ NBC yoo fofin de awọn ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ wi pe wọn o gbọdọ gbe awọn orin kan tabi omiran safẹfẹ mọ ree.

Wọnyii lawọn olorin ti ajọ NBC ti fofin de orin wọn tẹlẹ ni Naijiria:

Davido – ''Fans Mi''

NBC fofin de awọn ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ lọdun 2015 wi pe wọn o gbọ lo orin ''Fans Mi'' ti Davido gbe jade mọ.

Ọrin ọhun ti olorin orilẹede Amẹrika Meek Mill naa jade ninu rẹ ni ajọ NBC sọ pe wọn lo egboogi oloro kan ti ko yẹ ki wọn lo ninu fidio orin naa..

Ajọ NBC tun sọ pe awọn eeyan to n ṣira silẹ wa ninu fidio orin ọhun eyi ti ko yẹ kawọn eeyan maa wo.

Ajọ naa tun sọ pe orin ọhun n polowo kata kara oogun oloro.

Lilo awọn ọrọ kobakungbe ati ihuwa ipa ni awọn idi mii ti ajọ naa fi gbẹsẹ le orin ọhun.

Wizkid – ''In My Bed''

Loṣu Keje ọdun 2015 ni ajọ NBC paṣẹ fawọn ileesẹ igbohunsafẹfẹ ni Naijiria wi pe wọn o gbọdọ lo orin Wizkid to pe akọle rẹ ni ''In My Bed'' mọ.

NBC ni idi tawọn fi gbẹsẹ le orin naa ni pe o n ṣafihan awọn iwa buruku eyi to le kọ awọn ni ikọkukọọ.

Ajọ NBC tun sọ pe fidio orin naa n ṣe igbelarugẹ kata-kara oogun oloro eyi to lodi sofin orilẹede Naijiria.

Bakan naa ni ajọ to n moju to awọn ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ tun sọ pe fidio orin ọhun n ṣafihan awọn eeyan ti wọn n ṣira silẹ papaa julọ awọn obinrin.

Tiwa Savage – ''Tiwa's Vibe''

Gbajugbaja akọrin obinrin Tiwa Savage fi aidunnu rẹ han loju opo Instagram rẹ lọjọ kẹfa oṣu Kẹfa ọdun 2018 lori bi ajọ NBC ti fofin de awọn ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ wi pe wọn gbọdọ lo orin rẹ to gbe jade to pe akọle rẹ ni ''Tiwa Vibe'' mọ.

Orin ti Tiwa Savage gbe jade loṣu karun un ọdun naa ni NBC sọ pe o le ede ''shayo''ninu orin ọhun eyi to le maa jẹ kawọn ọdọ maa mu ọti lamu para.

O ni igbesẹ ajọ naa ya oun lẹnu tori pe ọti mimu ko lodin sofin orilẹede Naijiria.

Amọ, ajọ naa ko tori nnkan ti Tiwa Savage sọ gbẹsẹ kuro lori naa.

Olamide – ''Wo''

Lọdun 2018 ni ajọ NBC fofin de orin gbajugbaja akọrin takasufee, Olamide Adedeji, ti o pe akọle ẹ ni ''Wo.''

Ajọ naa si paṣẹ pe awọn ileeṣẹ redio ati tẹlifisan o gbọdọ gbe orin naa sori afẹfẹ mọ tori o n polowo siga mimu eyi to le ge ẹmi awọn eeyan kuru.

Amọ, Olamide fesi pe oun ko ni erongba lati ṣakoba fun awọn ololufẹ oun pẹlu orin ti oun gbe sita.

Olamide ni ''mi o ni erongba lati ṣe ipolowo siga mimu eyi to le gbẹmi araalu.

Mo fẹran awọn eeyan mi, mo si nifẹẹ orilẹede mi pẹlu.''

9ice – ''Living Things''

Ajọ to n ṣamojuto awọn ileeṣẹ igbohusafẹfẹ gbẹsẹ le orin kan ti 9ice kọ to pe akọle rẹ ni ''Living Things'' bakan naa.

Ajọ NBC ni fido orin ọhun n sọ nipa awọn ọdọ to n lu jibiti lori itakun ayelujara.

Ṣaaju ki ajọ NBC to fofin de orin naa ni olorin mii Falz to jẹ akẹgbẹ 9ice ti kilọ pe kawọn eeyan ṣọra ki ọrọ to wa ninu orin naa ma ba ṣi wọn lọna.

Falz ni olorin ti ko ba mọ pe nnkan to buru ni pe ki o maa kọ orin to n ṣe igbelarugẹ egboogi oloro ati jibiti ori ayelujara ko wa idagbasoke ati ilọsiwaju Naijiria.

Reminisce – ''Tesojue''

Akọrin takasufee Reminisce naa fara kaasa lọwọ ajọ NBC lẹyin ti ajọ naa fofin de orin rẹ to pe akọle rẹ ''Tesojue'' lọdun 2014.

Ajọ naa ni awọn ọrọ ati fidio to wa ninu orin ọhun le kọ awọn ọdọ Naijiria ni nnkan ti ko dara.

Nigba to sọrọ lori igbesẹ NBC, Reminisce gba ajọ naa ni imọran wi pe ki wọn maa gbe alakalẹ lori ọrọ ati fidio to maa n wa ninu orin sori afẹfẹ fun gbogbo eeyan lati mọ ko to di pe wọn fofin de orin kankan.

''O yẹ ki NBC gba awọn akọṣẹmọṣẹ lori ọrọ gbigbe orin jade tori iru awọn ofin yii naa wa loke okun.

Ti wọn ba ti le gbe orin kan sori afẹfẹ nile iṣẹ redio, wọn kii da akọrin laamu mọ loke okun.

NBC ni lati gbe igbimọ kan dide eyi ti yoo maa ṣayẹwo orin wa ki a to gbe wọn jade, ti yoo si maa sọ fun wa ohun ti wọn ba fẹ ka yọ kuro nibẹ,'' Reminisce lo sọ bẹẹ.