Àṣírí ìgbeyàwó àádọ́rin ọdún wa - ọ̀pọ̀ ọdún la fi pínyà

Àkọlé fídíò, Aṣiri igbeyawo
    • Author, Ken Banks and David Delday
    • Role, BBC Scotland
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Tọkọtaya meji ti wọn ṣe igbeyawo ni ọdun 1955 ti sọ aṣiri si igbeyawo adọrin ọdun wọn, ohun to sọ tọkọtaya naa papọ fun ọpọlọpọ ọdun.

Tommy Budge ati Thelma Bruce ṣe ayẹyẹ kan papọ pẹlu ẹgbọn Tommy, Violet Budge ati Leslie ni Kirkwall, Orkney.

Awọn mẹrẹrin ti wa n ṣe ajọyọ ọpọ ọdun papọ bayii, ti wọn si ṣe ti asiko yii pẹlu awọn ọmọ, ọmọ-ọmọ ati awọn ọmọ-ọmọ-ọmọ.

Wọn ṣapejuwe igba ewe wọn papọ gẹgẹ bii eyi ti wọn fi n kọ lẹta si ara wọn dipo lilo foonu ati fifi atẹjisẹ ransẹ, wọn si fi n ṣe awada pe asiko ti wọn jina si ara wọn lo ṣe iwulo fun wiwa papọ wọn fun ọpọ ọdun.

Tommy Budge, Thelma Budge, Violet Flett ati Leslie Flett,

Oríṣun àwòrán, Flett family

Thelma jẹ ẹni ọdun 87, Tommy jẹ 89, Violet jẹ 91,ti Leslie si jẹ ẹni ọdun 94.

Igbeyawo ti wọn ṣe papaọ yii lo waye ni ọjọ kẹsan an ọdun 1955 nigba ti Tommy gba ipe lati wa darapọ mọ ileeṣẹ ologun.

Violet ati Leslie ti kọkọ ọjọ igbeyawo wọn.

Pẹlu asiko perete ti Tommy yoo lo ni ile, wọn parapọ lati ṣe igbeyawo wọn ni alarinrin.

Igbeyawo naa ni ọrẹ mọlẹbi kan, to jẹ akọwe lasiko naa ni ileeṣẹ iwosan Balfour se onigbọwọ fun, ti igbeyawo naa si waye.

Thelma ati Tommy Budge ni igba ewe

Oríṣun àwòrán, Budge family

Thelma ṣapejuwe asiko naa bi eyi ti Tommy n fo kiri.

"O wa ni ọjọ Ẹti, a ṣe igbeyawo lọjọ Ṣatide , o tun pada ni ọjọ Aje ," ranti.

Violet ranti igbeyawo naa, to si o waye ni irọnu.

"Awa mejeeji dide, ṣe igbeyawo, ti a si parọ aye, ti meji yooku naa si ṣe ti wọn," o sọ. "O da pe emi ati Les ni akọkọ ṣe."

Lẹyin ayẹyẹ, ti a ya aworan, gbogbo wọn morile ile awọn obi Leslie.

Asiko yii ni Violet gbiyanju Champagne.

"Mo ni eyi ni igba akọkọ ti ma dan Champagne wo ni eyi, ti yoo si igba ikẹyin," O ranti.

"Oh, n ko fẹran rẹ- ko da bi kọpu tii mi." o rẹrin.

Lẹyin naa ni a lọ si ile awọn obi Violet ati Tommy fun abọ ounjẹ adiẹ ati potatoes fun awọn alejọ ọgbọn.

Violet ati Leslie Flett ni igba ewe

Oríṣun àwòrán, Flett family

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn tọkọtaya mejeeji ni lati lo ọpọ igba lai si pẹlu ara wọn nitori iṣẹ ti wọn n ṣe.

Eyi jẹ nnkan ti wọn n fi ṣe awada bayii pe o jẹ ọkan lara idi ti wọn fi pẹ pẹlu ara wọn.

Tommy jẹ arin irinajo, ti Violet jẹ oṣiṣẹ nọọsi to n ṣe iṣẹ alẹ ni ile iwosan abẹlẹ.

Violet ni: "Aṣiri mi ni pe mo n ṣiṣẹ alẹ, mo ma n wa ni ile ni oṣan ganagan, ti ma si jade ni alẹ.

"Ọkọ mi ma n siṣẹ ni ọsan, ti yoo si wa ni ile ni alẹ, aṣiri niyẹn - lati ma ri ara wa."

O fikun: "Mo ma kọ lẹta, ti ma si fi kọ digi wa. Ọkọ yoo ri lẹta yii, yoo ka, ti yoo si fesi, ti oun naa yoo si fi lẹta silẹ fun mi. Bayii ni a ṣe n balọ."

Thelma ni bayii lo ṣe jẹ fun ohun ati Tommy naa to wa ni ileeṣẹ ologun fun ọdun mẹta ko to di pe o bẹrẹ si ni ṣe iṣẹ aṣọ ile ina.

"Adọrin ọdun igbeyawo, boya ọdun marundinlogoji papọ," o sọ pẹlu ẹrin lẹnu.

O tẹsiwaju: "Ni akọkọ, o lọ fun oṣu mejidinlogun igbardi ileeṣẹ ologun, ti n ko si foju kan. Nigba to tun ya, o lọ fun oṣu meji, to si lo ọsẹ meji ni ile.

Leslie Flett, Violet Flett, Thelma Budge atiTommy Budge,

Oríṣun àwòrán, Evie McGowan

Aworan awọn tọkọtaya

Awọn tọkọtaya yii n gbe ni Orkney, ti ile wọn ko si jina si ara wọn.

Inu wọn dun nigba ti wọn gba lẹta lati ọwọ Oba Charlse ati Ayaba Camila, ti wọn si kọkọ gba lẹta lati ọwọ Ọbabinrin Elizabeth lati ṣe ayajọ ọgọta ọdun ati ọdun marundinlaadọrin igbeyawo wọn.

Violet ni "Kaadi akọkọ ti a gba, a ni , iwọ Ọlọrun, kaadi lati Ọbabinrin- iyalẹnu ree.

"Nigba to ya, a tun omiran, omi lati ọwọ Ọbabinrin, ti a ro pe n jẹ a ma waye laaye lasiko ti Ọba Charlse ba de sipo.

"Ṣugbọn awọn to ma n mu kaadi ni ọjọ diẹ sẹyin, a si ri kaadi naa."

'Gba ọjọkijọ bi o ṣe wa'

Ohun iyalẹnu ibẹ ni pe wọn jọ n ṣe ayẹyẹ igbeyawo wọn Oba ati Ayaba Charlse ni wọn naa ṣe igbeyawo ni ogun ọdun sẹyin ni ọjọ kẹsan an oṣu keji.

Violet ni "O jẹ ọjọ kan ti mo ro pe a ko ni le de.

"O ga ju ero gbogbo wa lọ paapa fun awa mẹrẹrin lati tun kopa. O jẹ ohun iyalẹnu fun gbogbo wa."

Ki ni imọran Violet fun awọn tọkọtaya tuntun ?

"Gba gbogbo ọjọ bi o ba ṣe wa," o sọ.