Ìdí tí olórí ọmo ogun tó dìtẹ̀ gbàjọba ṣe tẹ́wọ́gba ìjọba alágbádá ní Gabon

Aworan Brice Clotaire Oligui Nguema

Oríṣun àwòrán, AFP

    • Author, Paul Melly
    • Role, Africa analyst
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Lẹyin oṣu mọkandinlogun tawọn ologun ditẹ gbajọba Ali Bongo ti ẹbi rẹ ti n ṣejọba orilẹede Gabon fun aadọta ọdun, awọn eeyan orilẹede naa yoo dibo yan aarẹ tuntun lọla ọjọ Abamẹta ọjọ kejila oṣu Kẹrin yii.

Oludije ti ọpọ eeyan ti n sọ pe oun ni yoo jawe olubori ninu eto idibo naa ni Ọgagun Brice Clotaire Oligui Nguema to dari awọn ọmogun to ditẹ gbabọja aarẹ Bongo.

Ọgagun Nguema yoo koju awọn oludije meje mii ninu eto idibo aarẹ ọhun.

Akori ọrọ to n sọ lasiko ipolongo ibo ni wọn n pe ni "C'BON" eyi to yọ jade ninu orukọ rẹ, eyi to tumọ si nnkan to dara ni ede Faranse.

Aworan Olootu ijọba Gabon tẹlẹ, Alain-Claude Bilie-By-Nze

Oríṣun àwòrán, Reuters

Lara ohun to jẹ ki ọpọ eeyan gbagbọ pe Nguema ni o ṣee ṣe ko wọle ibo aarẹ ọjọ Satide ni pe Alain-Claude Bilie-By-Nze to jẹ olootu ijọba aarẹ Bongo ni oludije to tun fẹẹ lẹnu julọ ninu gbogbo awọn alatako rẹ.

Ọdun meje ni ẹni to ba jawe olubori ninu eto ibo aarẹ ọjọ Abamẹta yoo lo lori aleefa.

Eeyan bii miliọnu meji ati abọ lo wa ni Gabon, orilẹede naa si wa lara awọn orilẹede to ni epo rọbi ati okuta iyebiye ''manganese.''

Yatọ si rogbodiyan lẹyin eto idibo gbogbogbo to ṣẹlẹ ni Libreville ti i ṣe olu ilu Gabon lọdun 2016, alaafia ti jọba ni Gabon fun ọpọlọpọ ọdun sẹyin bayii.

Ọgbọnjọ oṣu Kẹjọ ọdun 2023 ni Nguema atawọn ọmọ ogun rẹ ditẹ gbajọba lorilẹede Gabon, lẹyin ti ajọ eleto idibo fẹẹ kede laarin oru wi pe Aarẹ Ali Bongo Ondimba ti wọle ibo aarẹ fun saa kẹta.

O nira fun ọpọ eeyan lati gba esi idibo ti ajọ eleto idibo sọ pe Bongo ni ida 64% gbogbo ibo tawọn araalu di gbọ.

Lọdun 2009 ni Ali Bongo rọpo baba rẹ Omar gẹgẹ bii aarẹ orilẹede Gabon.

Awọn eeyan kan n kaanu rẹ nigba to ni arun rọparọsẹ lasiko to n ṣabẹwo si orilẹede Saudi Arabia.

Amọ, ọpọ ọmọ orilẹede Gabon binu nigba ti Ali Bongo kede wi pe oun yoo dupo aarẹ fun saa kẹta.

Ọpọ lo gbagbọ pe iyawo rẹ Sylvia ati ọmọkunrin rẹ Nourredin Bongo Valentin lo n ti i lati dije fun ipo aarẹ fun saa kẹta bo tilẹ jẹ pe o ni ailera.

Inu awọn araalu dun lẹyin ti awọn ologun mu Sylvia ati Nourredin, ti wọn si ha Ali Bongo mọ inu ile.

Aworan awọn oludibo to n ṣe ayẹwo orukọ wọn ni ibudo idibo to wa ni Lambaréné, Gabon.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Oniruuru ajọ ajafẹtọọ ni wọn fara mọ bi awọn ologun ṣe ditẹ gbajọba Ali Bongo.

Nguema fa ọpọ awọn to ti di ipo kan tabi omiran mu ni ijọba tẹlẹ ri mọra lati ṣisẹ pọ pẹlu rẹ lẹyin toun atawọn ọmogun gbajọba tan.

O tu awọn ti ijọba ti ju sẹwọn oṣelu silẹ, amọ, iyawo Ali Bongo ati ọmọkunrin rẹ si wa ni ahamọ nibi ti wọn ti n reti igbẹjọ lori ẹsun iwa ibajẹ.

Nguema ko pa awọn akọroyin lẹnu mọ gẹgẹ bi ohun to n ṣẹlẹ lawọn orilẹede ti ologun ti gbajọba ni Afirika bii Mali, Burkina Faso, Guinea ati Niger.

Aworan Aarẹ Emmanuel Marcon ati olori ologun Gabon, Brice Clotaire Oligui Nguema

Oríṣun àwòrán, AFP

Awọn ijọba ologun to ti gbajọba lawọn orilẹede iwọ oorun Afirika ti kọ ẹyin si awọn orilẹede alagbara ti wọn ko wọn lẹru, amọ, Nguema ko ṣe bẹẹ.

Nguema ti lo awọn agbaagba ninu oṣelu lati ṣiṣẹ lori ibasepọ to wa laarin Gabon atawọn orilẹede to ti goke agba.

Ni bayii, ibaṣepọ to dan mọran lo wa laarin Gabon ati orilẹede France to ko orilẹede naa lẹru.

Bakan naa ni Nguema ti n ṣe oniruuru akanṣẹ iṣẹ eyi ti yoo ṣe awọn araalu lanfaani.

Aworan awọn oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ lori oju ọna reluwe ni Gabon

Oríṣun àwòrán, AFP

Pupọ ninu $520m ti Nguema ya nipasẹ Eurobond loṣu Keji to kọja ni o fi san gbese ti ijọba jẹ silẹ.

O si tun ti ya owo kan sọtọ lati san gbese ti Gabon n jẹ banki agbaye.

Amọ, Nguema yoo koju awọn ipenija kan ti o ba wọle ibo aarẹ orilẹede Gabon.

Lara awọn ipenija yii ni ebi to n pa araalu lorilẹede Gabon.

Ko saba si ẹnikan to koro oju si bi eto ibo ti yoo fopin si ijọba ẹbi Bongo to ti ṣe ijọba Gabon fun aadọta ọdun.

Awọn kan fi aidunnu wọn han nigba ti Nguema fagile ipo olootu ijọba lati wa ojutuu si ọrọ tawọn kan n sọ pe agbara ti pọju fun aarẹ Gabon.

Amọ, eleyii ko tumọ si pe oun nikan ni yoo maa da ṣe ijọba ti o ba le wọle ibo aarẹ ọjọ Satide.

Awọn alẹnulọrọ bii Alexandre Barro-Chambrier and Marc Ona Essangui lo wa ninu igbimọ to n ri si gbigbe ijọba fun aarẹ tuntun ti ilu fẹẹ dibo yan.

Awọn eeyan yii si le tẹsiwaju lati maa ba a ṣiṣẹ lẹyin to ba wọle tan.

Aworan awọn ọkọ to n kọja lori afara odo Ogooué ni Lambaréné, Gabon

Oríṣun àwòrán, Reuters

Gabon jẹ ọkan lara awọn orilẹede ti o da igbo rẹ si, o si ti gba oriyin fun eyi.

Amọ, ijọba ni lati jẹ ki orilẹede naa gboriyin nipa ṣiṣe nnkan amayedẹrun fun araalu, papaa julọ nipa lilo epo rọbi atawọn alumọni mii ti Eledua fi jinki ilẹ naa daadaa.

Awọn olugbe igberiko n beere lọwọ ijọba lati daabo bo ẹtọ wọn lati ṣọdẹ ninu igbo ati lati ṣiṣẹ agbẹ.

Awọn olugbe Libreville ti wọn to idaji gbogbo eeyan to wa ni Gabon nilo iṣẹ to dara.

Akọsilẹ fi han wi pe ọpọ eeyan ni iṣẹ n ba finra, bo tilẹ jẹ pe orilẹede to ni oniruuru alumọni ni Gabon.

Aṣaju ẹgbẹ oṣiṣẹ, Jean Remy Yama, ti wọn yọwọ kurọ ninu eto idibo ọjọ Satide tori ko ri iwe ọjọ ibi baba rẹ fi silẹ wa lara awọn to le sọ nipa nnkan tawọn eeyan Gabon n la kọja.