Kí ló dé tí ẹnu fi ń kun ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù 3SC ilẹ̀ Ibadan?

Oríṣun àwòrán, Facebook/ShootingStarsFC
Laarin oṣu kan si akọkọ yii ni awọn iroyin ti ko fi bẹẹ wu ni lori n jade nipa ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Ibadan, 3SC ti ọpọ eeyan mọ si 'Shooting Stars'.
Ninu oṣu kẹta ọdun yii ni fọran kan lu sita lori ayelujara nibi ti wọn ti ṣe afihan olukoni fun awọn to n ṣọ oju ile, iyẹn goli fun ẹgbẹ agbaboolu 3SC, John Dosu ti awọn eeyan kan n du digbadigba lori papa iṣere Adamasingba ilu Ibadan, gẹgẹ bi wọn ṣe n fi ẹsun kan wi pe ọkan lara awọn aṣoju ẹgbẹ agbabọọlu Niger Tornadoes lo kan an ni ẹṣẹ lasiko ti ifẹsẹwọnsẹ kan fẹ waye laarin won.
Nigba ti yoo tun fi di Ọjọru ni iroyin mii to lu sita wi pe ajọ to n ṣe akoso bọọlu alafẹsẹgba lorilẹede yii, NPFL ti fi ofin de awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu 3SC pe wọn ko gbọdọ fi oju han nibi ifẹsẹwọnsẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa mọ, wọn si tun gbọdọ san owo itanran to jẹ Milliọnu marun un Naira lori ẹsun wi pe wọn ṣe ikọlu si ọkọ ẹgbẹ agbabọọlu Ikorodu City FC lẹyin ifẹsẹwọnsẹ to waye laarin awọn mejeeji ni papa iṣere Adamasingba niluu Ibadan.
Ajọ NPFL ni ẹgbẹ agbabọọlu 3SC jẹbi ẹsun wi pe wọn ko pese eto aabo to peye wọn tun kọ lati ṣe atọkun awọn ololufẹ wọn to wa wo ifẹsẹwọnsẹ naa, bakan naa ni wọn tun fi ẹsun kan wọn wi pe wọn n lẹ nnkan mọ awọn adari ayo lori papa iṣẹrẹ naa.
BBC Yoruba kan si agbẹnusọ ẹgbẹ agbabọọlu 3SC, Tosin Ọmọjọla fun ariwisi ẹgbẹ agbabọọlu naa lori awọn ẹsun wọnyii ati ijiya ti ajọ NPFL gbe kalẹ fun wọn, alaye to ṣe fun akọroyin wa ni akọroyin wa ni pe, "A ko le fẹ iru awọn iṣẹlẹ bayii ku ninu ere bọọlu alafẹsẹgba."
O ni gbogbo ipa ni awọn n sa lati ṣe atunṣe ki wọn le bọriyọ ninu awọn iya ti ajọ NPFL kede rẹ.
Kaakiri ode agbaye ati nilẹ wa ni awọn ololufẹ ere bọọlu alafẹsẹgba ti maa n fa wahala ti ẹgbẹ agbabọọlu wọn ba fi idi rẹmi. Eleyii si wọ pọ ni awọn asiko to jẹ wi pe ẹni ti wọn gba lalejo lo bori ayo.











