'Iṣẹ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ ló gbé mi dé Eko, àmọ́ mo ti di ẹni tó ní iléèṣẹ́ mẹ́rin báyìí'
Ori lo mọ iṣẹ aṣela! Nigba ti Arabinrin Opeyemi Babatope n fi ilu abinibi rẹ, Ile-Ife, silẹ, lati ma a gbe niluu Eko, ko mọ koko iṣẹ aje ti yoo ṣe jẹun.
Ẹni ọdun mẹtalelọgbọn ọhun, sọ fun BBC ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pe, inu iporuru ọkan ni oun kuro ni ilu naa, nitori bi eto ọrọ aje rẹ ko ṣe dara.
Arabinrin Babatope sọ pe iṣu dindin ati dodo ni oun n ta niluu Ife, amọ nnkan ko papa ri bo ṣe fẹ ko ri.
O ni irinajo to l'agbara lo gbe oun lọ si Eko.
"Nigba ti ma a fi kuro, ara ti ni mi pupọ."
Inira ati ibanujẹ yii lo mu ki Opeyemi pe ẹnikan to mọ, to n gbe nipinlẹ Eko, lati ba a wa iṣẹ to le ṣe.
Amọ wọn ko ba a ri iṣẹ meji, bi ko ṣe iṣẹ lati maa tọju iya agbalagba kan to wa lori idubulẹ aisan.
Opeyemi Babatope gba lati maa tọju iya naa, amọ ko tii ju oṣu kan lọ to bẹrẹ si ni tọju iya naa, ti iya agba ọhun fi ku.

"Aanu iya naa ma n ṣe pe mi pupọ pe, ẹni to yẹ ko maa jẹun ọmọ, wa lori idubulẹ aisan."
Iriri rẹ lọdọ ẹni to kọkọ tọju, lo mu ko ni afojusun ati ipinnu lati da ileeṣẹ kan silẹ, eyi ti yoo maa mojuto itọju awọn arugbo.
"Lati igba naa ni mo ti kiyesi pe, wọn o ki n fi iṣẹ mii lọ mi ju itọju arugbo lọ.
Igbiyanju rẹ lo mu ko da ileeṣẹ tiẹ to pe ni Magdalene Caregivers silẹ.
Arabinrin Bamidele ṣalaye pe, iwe ẹri marundinlọgbọn, ni oun ni nipa itọju arugbo.
"Gbogbo awọn to bu mi nigba ti mo n ṣe iṣẹ ọmọ-ọdọ, ti wọn ni kini mo ri ninu iṣẹ idọti, ni mo n kọ bayii, paapaa awọn to fẹ lọ maa ṣe niluu oyinbo."
Yatọ si itọju arugbo, o ni oun tun n ṣe iṣẹ agbẹ, kata-kara ile ati eto ironilagbara fun awọn obinrin.



