'Wọ́n máa n pè mí ní ọmọ omi nítorí bí ara mi ṣe rí láti kékeré'

Louisa Enyonam Ansah jẹ akanda ẹda l'obinrin, to si ti mu gbogbo afojusun rẹ wa si imusẹ, nitori bi o ṣe n ran awọn ọmọde lọwọ, paapaa awọn ọmọ ti awọn naa jẹ akanda ẹda.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Pidgin, Ẹnyonam ni, kete ti wọn bi oun ni ọpọ eeyan ti bẹrẹ si ni ma pe oun ni ọmọ omi nitori wọn ko ri iru oun ri.
Eyi ko ṣẹyin bo ṣe jẹ pe, ko ni apá tabi ọwọ kankan.
O tẹsiwaju pe botilẹ jẹ pe iṣẹ agbẹjọro lo wu oun lati ṣe ṣugbọn olutọju oun ni, oun ni ẹbun kikọ eeyan.
O ti to ọgbọn ọdun bayii ti Enyonam ti fẹyinti lẹnu iṣẹ olukọni, to si gbajumọ siṣe itọju awon ọmọde to jẹ akanda to wa ni abẹ rẹ.
"Mo fẹ di agbẹjọro sugbọn ọkùnrin to n tọju mi ṣakiyesi pe, mo ni ẹbun kikọ eeyan.
"Eyi lo fa a ti mo fi lọ si ile-ẹkọ awọn olukọni.
"Mo bẹrẹ si ni ma kọ awọn akẹkọọ girama ni ọdun 1990."
Enyonam ni ile aye ko rọrun fun oun rara sugbọn nitori pe oun jẹ akinkanju ọmọ, oun pinnu pe ohunkohun ko ni daoun duro lati tẹsiwaju.
"Eyi ni mo n fi si ọkan awọn ọmọ yii pe, nkankan ko gbọdọ da wọn duro nitori ipo ti wọn wa
Enyonam ni awọn mọkanlelogun ni awọn jọ n gbe ile bayii ti wọn jẹ ọmọde
O ni fun awọn eeyan bí toun ti wọn ko ni apa, ni oun ti kọọ bi wọn ṣe le ṣe nítori wọn le wo oun.















