Sarkin Sasa kì í ṣe oyè nílùú Ibadan, Baálẹ̀ Sasa ni a dá mọ̀- Olúbàdàn

Oríṣun àwòrán, Others
Olubadan ti ilu Ibadan, Ọba Owolabi Olakulehin ti wọgile ipo Sarkin Sasa tuntun ni ijọba ibilẹ Akinyele lẹyin to ni ipo naa ko ni gbongbo ninu iwe ofin oye jijẹ nilẹ Ibadan.
Ọrọ yii lo jẹyọ ninu ipade igbimọ ilu to waye ni Aafin Olubadan to wa ni Oke Aremo, niluu Ibadan.
Iroyin ni Sarkin Sasa ana ni alaga ẹgbẹ awọn Arewa ni ipinlẹ mẹtadinlogun to wa ni Guusu Naijiria ṣaaju ipapoda rẹ.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ẹyin iku ọkunrin naa ni igbimọ awọn to n ṣakoso Sasa ọhun kede ọmọ rẹ, Ahmed Haruna ti ọpọ mọ si Ciroma, gẹgẹ bii Sarkin Sasa lai jẹ ki Olubadan mọ si.
Lẹyin naa ni agbẹnusọ olubadan, Gbenga Ayoade, sọ ninu atẹjade kanpe Oloye Akinade Ajani Amusa nikan ni Olubadan da mọ gẹgẹ bii Baalẹ Sasa ni Akinyele.
Atẹjade naa ni "A fẹ ki araalu mọ pe abẹ Baalẹ Sasa ni gbogbo awọn to n gbe ni Sasa wa.
"Nitori naa, o ṣe pataki lati bu iyi tọ si fun un ki wọn si maa tẹle aṣẹ rẹ.
"A ko ni gba ki ẹnikẹni tapa si aṣẹ rẹ, ẹnikẹni to ba ṣe bẹẹ ti n fi ọwọ pa ida Olubadan loju."
Wọn yan Sarkin Sasa tuntun lai bun Olubadan gbọ
Nigba ti BBC kan si aafin olubadan lati tan imọlẹ si ọrọ naa, ọkan lara awọn oloye ilẹ Ibadan amọ ti ko fẹ fi orukẹ rẹ lede sọ pe ootọ ni Olubadan fi aṣẹ naa lede.
O ni "Lootọ ni ohun ti agbẹnusọ Olubadan sọ.
"Gẹgẹ bii ohun ti mo gbọ, wọn ni o sọ pe oun fẹ ṣe saara ọjọ mẹjọ, ni ṣe wọn kan ṣadede ri pe wọn n tọban rẹ gẹgẹ bii Sarkin Sasa.
Oloye naa sọ fun wa pe bo tilẹ jẹ pe kii ṣe Olubadan lo n yan Sarkin Sasa, wọn gbọdọ bun un gbọ ki wọn to kede ẹnikẹni ti yoo di ipo naa mu ki o le fi aṣẹ si.















