Olùdásílẹ̀ ilé ìfowópamọ́ Diamond, Pascal Dozie, jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Uzoma Dozie/Instagram
Oludasilẹ ileeṣẹ ifowopamọ Diamond, ti wọn ti kogba wọle ati alaga tẹlẹri fun ileeṣẹ MTN, Pascal Dozie ti jade laye.
Eyi lo wa ninu atẹjade kan ti mọlẹbi oloogbe fi lede lati kede iku oloogbe lọjọ Ìṣegun.
Ẹni ọdun marun-undinlaadọrun ni oloogbe naa ko to jade laaye.
Gẹgẹ bii awọn aṣoju mọlẹbi to kede oloogbe ṣe ṣalaye, o ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bii baba rere to jẹ onigbagbọ ododo.
"Pẹlu ibanujẹ ọkan ati idupẹ fun Ọlọrun la fi kede ipapoda iku Baba wa, Pascal Gabriel Dozie, ẹni to jade laye lọjọ kẹjọ oṣu kẹrin ọdun 2025.
"Baba wa jẹ ọkọ rere, baba, baba baba ati eeyan Ọlọrun to fi gbogbo aye rẹ sin Ọlọrun, mọlẹbi ati orilẹede rẹ.
Aarẹ Bola Tinubu ati ọmọ Naijiria ṣe idaro oloogbe
Aare Bola Ahmed Tinubu tí darapọ mọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati ṣe idaro oloogbe naa.
Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ Aarẹ fi lede, Aarẹ ṣapejuwe Dozie gẹgẹ bii olori rere to ni ọgbọn, imọ ati oye to si gbe igbeaye rere.
Aarẹ ni ipapoda naa jẹ ibanujẹ ọkan fun ọpọlọpọ ileeṣẹ aladani.
Gomina Ipinlẹ Anambra tẹlẹri, Peter Obi naa ti kan sanra si Dozie gẹgẹ bii oṣiṣẹ banki to ni oye pupọ.
Taa ni Pascal Dozie?
Oloye Pascal Gabriel Dozie ni oludasilẹ ileeṣẹ ifowopamọ Diamond Bank ati alaga akọkọ fun MTN ni Naijiria.
Wọn bi oloogbe naa ni ọjọ kẹjọ oṣu kẹrin ọdun 1939 niluu Egbu, Owerri, nipinlẹ Imo.
O tun sisẹ gẹgẹ bii olukọ ni ile ẹkọ gbogbo nise Poly North Western niluu London
O jẹ oludasilẹ ileeṣẹ ifowopamọ Diamond Bank laarin ọdun 1991 si 2006, ko to di pe o fa le ọmọ rẹ Uzoma Dozie lọwọ.















