Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Gbọ na, ṣe lootọ ni ijọba Saudi Arabia fofin Fisa de awọn ọmọ Naijiria to fẹ ṣe Hajj ọdun yii?
Ah, nibo lo ti gbọ iroyin yẹ kẹ?
Mo tilẹ gbọ pe yatọ si Naijiria, wọn tun fofin de orilẹede metala mii lọdun yii
Irọ nla! Ko si ohun to jọ bẹẹ o
Hmmmmmm
Ti o ba fẹ mọ ẹkunrẹ, lọ soju opo BBC Yoruba
___________________________________
Nipinlẹ Ondo
Ara ti san pa maalu mẹjọ ni ijoba ibilẹ Ọ̀sẹ́
Iroyin ni awọn Fulani darandaran to n wuwa ibajẹ lagbegbe naa lo faa ti ara fi san pa maalu wọn
Amọ ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe amuwa Ọlọrun ni iṣẹlẹ naa, ko si ni nnkankan ni ṣe pẹlu iwa awọn Fulani
_____________________________________
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinle Eko ti ṣawari ile kan ti awọn obinrin ti n bi ọmọ fun tita lagbegbe Ijegun
Ọlọpaa doola eeyan mẹwaa nibẹ, o si fi ṣikun ofin mu afurasmi mẹta
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin sọ pe
Akara awọn to n ṣiṣẹ laabi naa tu sepo lẹyin ti awọn araalu ṣi awọn nigbẹrẹ ipakọ