Kí ló tún fà gbasgbos láàárín ẹgbẹ́ òṣèlú Labour, Peter Obi àti Alex Otti?

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹgbẹ awọn alaṣẹ NEC tí ẹgbẹ oṣelu Labour Party ti ní digbi ni awọn wa lẹyin igbimọ olori ẹgbẹ naa NWC.
Igbimọ olori yii ni Julius Abure jẹ olori fun
Bakan naa ni ẹgbẹ oṣelu naa tun fẹsun kan oludije aare labẹ ẹgbẹ oṣelu naa, Peter Obi ati Alex Otti, gomina ipinẹ Abia.
Labour Party ni Obi ati Otti n ṣísẹ tako ẹgbẹ oṣelu, ti wọn si n dalẹ ẹgbẹ oṣelu naa.
Eyi lo wa ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ naa fi lede lọjọ Aje lẹyin ipade to way niluu Abuja.
Akọwe ẹgbẹ naa, Umar Farouk ni inu NEC dun pupọ si idajọ ile ẹjọ to da agbara, ogo ati idunu ẹgbẹ naa pada si ibi to yẹ.
Bẹẹ ba gbagbe, ile ẹjọ to ga ju lorilẹede Naijiria wọgile iyapa ẹgbẹ oṣelu Labour Party, to si gbe agbara fun ẹgbẹ tí Julius Abure lewaju fun un.
Lọjọ Eti ọsẹ to kọja ni igbimọ onidajọ ẹlẹni marun-un gbe idajọ naa kalẹ pe Abure ni ojulowo olori ẹgbẹ oṣelu Labour Party.
Saaju ni ile ẹjọ ko tẹmilọrun gbe idajọ kalẹ pe ki wọn yọ Abure gẹgẹ bii olori sugbọn Ile ẹjọ gíga Supreme wọgile idajọ naa.
"Ile ẹjọ ti da agbara pada sibi to yẹ ati pe ìṣejọba ẹgbẹ oṣelu ki n ṣe fun ile ẹjọ lati da si, ti ile ẹjọ o sì le yọ ẹnikẹni ni ipo.
"Ile ẹjọ ti wa fìdí rẹ mulẹ pe ipade ẹgbẹ oṣelu Labour to waye ni ọjọ Kẹtadinlọgbọn oṣu kẹta ọdun 2024, nibi ti wọn ti yan Barr Julius Abure ni ofin fọwọ ṣi."
Awọn ọmọ ẹgbẹ to ṣíṣẹ tako wa yoo foju wina ofin
Bakan naa ni ẹgbẹ oṣelu Labour Party fẹsun kan Gomina Ipinlẹ Abia, Alex Otti pe o n ṣísẹ tako ẹgbẹ oṣelu naa.
Umar Farouk ni Otti pe fun ipade pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ tí wọn ko ni ẹtọ.
Umar Farouk ni Otti tun ṣe atilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu miiran lasiko idibo ẹgbẹ oṣelu ìjọba ìbílẹ nipinlẹ naa.
Peter Obi ati Gomina Alex Otti ko ti fesi si awọn ẹsun wọnyi.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post












