Taa ló ni àwọn òṣìṣẹ́ tó n fi POS gba káàṣì lọ́wọ́ awakọ̀ láì sí rìsíìtì lórúkọ ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun?

Àkọlé fídíò, Taa ló ni àwọn òṣìṣẹ́ tó n lo POS, gba káàṣì lọ́wọ́ awakọ̀ láì sí rìsíìtì lórúkọ ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun?
Taa ló ni àwọn òṣìṣẹ́ tó n fi POS gba káàṣì lọ́wọ́ awakọ̀ láì sí rìsíìtì lórúkọ ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun?
    • Author, Busayo James-Olufade, Emmanuel James, Afolabi Akinlabi

Ẹnu iṣẹ ni awọn oṣiṣẹ BBC Yoruba n lọ ni ọsẹ bii meji sẹyin nipinlẹ Ogun, ki wọn o to o pade awọn kan to pe ara wọn ni oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ naa to da ọkọ wọn duro.

Bi wọn ṣe de agbegbe Ojodu si Akute, ni awọn gende ọkunrin meji kan da ọkọ duro, ti wọn si gbe igi di oju ọna.

Oṣiṣẹ ijọba ibilẹ Ifo nipinlẹ Ogun ni wọn pe ara wọn. Bi wọn ṣe da ọkọ wa duro ni wọn beere fun iwe kan ti wọn lo n jẹ JTB.

Awọn akọroyin ileeṣẹ BBC to wa ninu ọkọ pẹlu awakọ ileeṣẹ sọ pe, ki awọn to mọ nnkan to n ṣẹlẹ, ẹnikan lara awọn ọkunrin naa ti yọ nọmba ara ọkọ.

"O dunkooko lati lu wa pẹlu ka to o kuro nibẹ, nitori pe a beere idi to fi hu iru iwa bẹẹ."

Iwadii lati ẹnu awọn ara adugbo naa sọ pe, bi awọn eniyan ọhun ṣe ma n gbe igi dina lojoojumọ niyẹn, ti wọn si ma n daamu awọn awakọ

Bawo ni wọn ṣe n ṣe iṣẹ wọn?

Awọn oṣiṣẹ to n fi ipa gba owo

Nnkan ti awọn eeyan yii to pe ara wọn ni oṣiṣẹ ijọba ibilẹ Ifo, kọkọ ma n ṣe ni pe, wọn yoo gbe igi di ọna ibi ti ọkọ n gba kọja.

Ti wọn ba ti da ọkọ duro, wọn yoo beere iwe kan ti wọn n pe ni JTB. Awakọ ti ko ba ti ni iwe naa, kia, irinajo di ọfiisi wọn to wa ninu ile kan ni Ojodu-Abiodun.

Owo afi ipa gba kan, ẹgbẹrun mẹwaa, ni wọn o kọkọ gba lọwọ awakọ naa.

Lẹyin naa ni wọn yoo sọ pe ko san owo iwe ẹri JTB ọhun.

Nnkan iyalẹnu kan to wa lori ọrọ owo naa ni pe, ko si koko iye to jẹ - iye ti ẹni to wa ninu ọfiisi naa ba sọ pe o jẹ naa ni.

Fun awọn akọroyin BBC, ẹgbẹrun lọna aadọrin naira, 70,000, ni wọn kọkọ pe owo iwe ẹri JTB. Amọ, lẹyin ọpọlọpọ iduna-dura, ẹgbẹrun lọna marundinlaadọta, 45,000 ni awọn akọroyin naa san.

"A kọkọ yari pe a ko nii san owo naa nigba ti wọn sọ pe inu apo asunwọn ẹnikan, ti kii ṣe ti ijọba ni ka san owo naa si.

"Wọn ni ẹni naa ni alamojuto, aladani, ti ijọba yan lati ma ba a mojuto ọrọ iwe ẹri naa."

Igbesẹ awọn akọroyin BBC yii bi awọn to wa ni ọfiisi ti wọn ti n gba owo naa ninu, debi i pe, nigba ti awọn oṣiṣẹ wa gba lati san owo naa, wọn ni awọn ko gba a sinu apo asunwọn naa mọ.

Ibo ni wọn dari wọn si? Inu ṣọọbu ẹnikan to n ṣe POS ninu ọgba naa, ni wọn dari wọn si lati lọ ọ gba owo wa.

Obirnin to wa lara wọn yari pe, kaaṣi – owo lọwọ, ni awọn fẹ ẹ gba bayii, kii ṣe sinu apo asunwọn alamojuto mọ.

Ko tan sibẹ o. Lẹyin ti awọn akọroyin BBC ko owo le wọn lọwọ tan, ṣebi o yẹ ki wọn o kọ risiiti, iyẹn iwe to ṣafihan rẹ pe, wọn san "owo itanran ati owo iwe ẹri JTB".

Nnkan ti ẹ n ro lọkan gan-an lo ṣẹlẹ. Wọn kuku ko awọn iwe kan fun wa, amọ ofifo ni awọn iwe naa wa.

Ẹyin naa kọ ha! Ibeere nla ni pe, taa ni awọn eeyan to n da ọkọ duro, gbe igi dina, fi ipa gba owo sinu aka-n-ti ti kii ṣe ti ijọba ipinlẹ Ogun?

Tabi, ṣe ijọba naa lo ni ki wọn o maa ṣe iduna-dura owo JTB, bi ẹni n na iṣu lọja Ọbada?

Akọroyin BBC Yoruba ba kọmisanna fun igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Ogun, Olugbenga Dairo sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun.

Ọgbẹni Dairo sọ pe ko si ijọba ibilẹ kankan ti oun mọ, to n gba iru owo bẹẹ nipinlẹ Ogun.

Bakan naa lo ṣalaye pe ẹnikẹni to b an gba iru owo yii, n ṣe nnkan to tako ofin ipinlẹ naa.

Nigba to n tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ, kọmisanna fun igboke-gbodo ọkọ ọhun, sọ pe nnkan to yẹ lati ṣe ni pe ki wọn o ni ki awakọ ti ko ba ni awọn iwe to yẹ ko ni, san owo itanran ti ijọba fọwọ si.

O tun rọ awọn olugbe ipinlẹ Ogun, to ba ni iru iriri ti awọn akọroyin BBC ni, lati fi to ileeṣẹ rẹ leti.