Mọ̀ nípa ìwọ́de 'take it back' tó gbòde káàkiri Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Take it back/X
Iwọde lati tako eto iṣejọba to n mu inira ba araalu gberasọ kaakiri orilẹede Naijiria lonii ọjọ Aje ọjọ keje oṣu Kẹrin yii.
Awọn to ṣe agbatẹru iwọde naa ṣalaye pe ohun to wa fun ni lati pe fun eto iṣejọba ti yoo maye dẹrun fun araalu.
Awọn to ṣe agbekalẹ ifehonuhan ọhun ti sọ fawọn eeyan ṣaaju wí pe ki wọn ko ara jọ pọ lawọn ibikan kaakiri Naijiria lati le kopa ninu iwọde naa.
Wọn ni awọn tun fẹ lo iwọde ọhun lati fopin si bíi ijọba ṣe n lo ofin lori iwa ọdaran ori ayelujara lati pa araalu lẹnu mọ.
Akori iwọde naa ni won pè ni "ifẹhonuhan tako eto iṣejọba to n ni araalu lara ati titẹ ẹtọ araalu lati sọrọ mọlẹ" gẹgẹ bi awọn to sagbatẹru iwọde naa ti ṣalaye.
Awọn olori ẹgbẹ yii sọ loju opo X wọn pe awọn kọ lẹta s'awọn ọlọpaa ṣaaju lati pese abo fawọn lasiko iwọde naa.
Oludari ẹgbẹ 'Take it back Movement', Kọmureedi Sanyaolu Juwon at'awọn abẹnugan mii ninu ẹgbẹ naa, sọ pe ofin lori iwa ọdaran ori ayelujara ni ijọba n lo lati mu awọn akọroyin, awọn ajafẹtọọ at'awọn ọmọ Naijiria lapapọ.
Awọn olufẹhonuhan naa n kepe ijọba lati fagile ofin yii lati le daabo bo ẹtọ araalu gẹgẹ bi o ti wa ninu iwe ofin Naijiria.
Wọn ni awọn ko ni dẹkun ṣiṣe ifẹhonuhan titi ti ijọba yoo fi fagile ofin naa.
Ki ni ọlọpaa sọ?

Ileeṣẹ orilẹede Naijiria ni iwọde yii n kọ awọn lominu.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejobī, ṣalaye ninu atẹjade kan ti o fi sita wí pe iwọde naa n kọ awọn lominu tori ọjọ keje oṣu Kẹrin ti ijọba ti yà sọtọ fún ayajọ awọn ọlọpaa lawọn olufẹhonuhan mu lati ṣe iwọde wọn.
Adejobi ni Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Kayode Egbetokun, bọwọ fun ẹtọ araalu, amọ, o fẹ k'awọn oluwọde gba ọna to tọ labẹ ofin lati sọ ohun tí wọn n fẹ lọdọ ijọba.
O ni ọga ọlọpaa wa rọ gbogbo awọn oluwọde lati jiroro pẹlu ijọba lori ohun tí wọn n beere.
Bi iwọde 'take it back' ṣe lọ kaakiri Naijiria
Ifẹhonuhan waye kaari orilẹede Naijiria gẹgẹ bi awọn to ṣe agbatẹru rẹ ṣe pinnu.
A gbọ pe awọn ọlọpaa wa pẹlu awọn to n ṣewọde lawọn ipinlẹ kan.
Nipinlẹ Eko, awọn oluwọde bẹrẹ ifẹhonuhan lati agbegbe Ikeja, wọn si rin lọ ileeṣẹ ijọba tó wa ni Alausa lati ibẹ.
Ọpọ ninu wọn lo mu beba ti wọn kọ oriiṣiriṣii nnkan ti wọn n beere si dani.

Oríṣun àwòrán, Take it back/X

Oríṣun àwòrán, Take it back/X
Awọn oluwọde naa bẹrẹ si ni kọrin nigba ti wọn pade awọn ọlọpaa lọna.
Ni ìpínlẹ̀ Rivers, awọn oluwọde f'ẹsẹ fẹ niluu Port Harcourt lẹyin tàwọn ọlọpaa yin tajutaju lati tu wọn ka.
Fidio kan to wa lori ayelujara tiẹ ṣafihan bi ọlọpaa kan ṣe n yin tajutaju si aarin awọn olufẹhonuhan ni Port Harcourt.
Bakan naa ni ọmọ ṣori niluu Abuja tíì ṣe olu ilu orilẹede Naijiria.
Ohun tí a gbọ ni pe awọn ọlọpaa yin tajutaju lati tu awọn oluwọde ka l'Abuja bakan naa.















