Àwọn afurasí darandaran kọlu abulé márùn ún ní Naijiria, ṣekupa àádọ́ta èèyàn, jí 50 míì gbé lọ

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy
Olubadabamọran fun Aarẹ Bola Tinubu lori eto abi, Malam Nuhu Ribadu ti sọ pe ijọba apapọ ti n gbe igbesẹ lati pa ina rogbodiyan to n waye ni ipinlẹ Plateau.
Ribadu lo sọ ọrọ naa lasiko to ṣayẹwo si olu ọọfisi ikọ Operation Safe Haven niluu Jos lẹyin akọlu si ijọba ibilẹ Bokkos.
O le ni aadọta eeyan ti wọn ṣekupa laarin ọsẹ kan ninu ikọlu ti awọn afurasi darandaran ṣe si ilu marun un ọtọtọ.
Nigba ti akọwe ijọba Plateau, Samuel Jatau ṣabẹwo si awọn ilu naa, o ni ijọba ipinlẹ ọhun n ṣe sa gbogbo ipa rẹ lati kapa awọn afurasu ọdran to n fẹmi sọfọ nibẹ naa.
Olori awọn olugbe agbegbe Hurti, Yohanna Michael ni o le ni oku ọgbọn eeyan ti awọn ti sin, awọn si tun n wa ọpọ awọn mii bayii.
Lọwọ yii, nnkan bii ẹẹdẹgbẹrin eeyan lo ti sa fi ile wọn silẹ lawọn agbegbe ti ikọlu naa ti waye.
Agbebọn pa fijilante mẹtala ni Kebbi
Ẹwẹ, awọn ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi Lakurawa ti ṣekupa eeyan mẹtala ni abule Morai to wa ni ijọba ibilẹ Augie ni Kebbi.
Oṣoju mi koro kan nibẹ, Alhaji Augie sọ fun awọn akọroyin pe ṣaaju ni awọn fijilante naa ti kọkọ gbọ pe awọn agbebọn ọhun n bọ wa kọlu abule naa ti wọn si sapamọ lati dẹ ọdẹ fun wọn.
O ni "O ṣeni laanu pe awọn agbebọn naa ti yi awọn fijilante ọhun ka ti wọn si ṣeku pa gbogbo awọn mẹtala naa lẹsẹ kan naa.
"Nnkan bii kilomita mẹta si abule wa ni iṣẹlẹ naa ti waye.
"A ti sin oku mẹfa ninu wọn bayii ni ilana ẹsin Musulumi, nigba ti a ṣi n wa awọn akẹgbẹ wọn to ku.
Agbebọn ji aadọta eeyan ni Katsina, ṣekupa eeyan mẹfa mii
Awọn olugbe ijọba ibilẹ Funtua ni Katsina ti ke gbajare pe agbebọn ti ji aadọta eeyan gbe lọ lagbegba awọn.
Wọn ni awọn obinrin atawọn ọmọde wa lara awọn ti wọn ji gbe ọhun.
Yatọ si awọn ti wọn ji gbe, awọn agbebọn tun ṣekupa eeyan mẹfa mii ni ijọba ibilẹ Dandume ninu ikọlu mii.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ọjọ Abamẹta ni awọn agbebọn naa ya wọ awọn ilu naa ti wọn si ṣọṣẹ titi di ọsan ọjọ Aiku.












