Mọ̀ nípa Mojisola Raimi, ọmọ ìpínlẹ̀ Osun tó gbadé Omidan tó rẹ́wà jùlọ ní Naijiria f'ọ́dún 2025

Oríṣun àwòrán, quuentiwa/Instagram
Omidan Joy Raimi Mojisola, ti gba ade Omidan Agbaye Naijriia fun ti ọdun 2025.
Joy, ẹni ọdun mẹrinlelogun (24) to ṣoju ipinlẹ Osun, gbegba oroke nibi idije naa to waye ni Victoria Island, ipinlẹ Eko lopin ọsẹ.
Lapapọ, omidan mẹtadinlogoji lo kopa ninu idije obinrin to rẹwa ju fun ti ọdun 2025 yii.
Lati ipinlẹ kọọkan ni Naijiria ni wọn ti mu awọn akopa naa, ki wọn too din wọn ku si ogun (20) to kopa ni aṣekagba.
Lopin abala to kẹyin, awọn omidan mẹrin lo dije pẹlu Mojisola , awọn naa ni: Omidan lati ipinlẹ Ebonyi, Abuja, Abia, ati Imo.
Pẹlu aṣeyọri yii, Omidan Mojisola Raimi ni yoo ṣoju orilẹeede Naijiria nibi idije obinrin to rẹwa ju lagbaaye.
Eyi yoo jẹ ẹlẹẹkejilelaadọrin idije naa (72nd) ti yoo waye lati ọjọ keje si ikọkanlelọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2025.
Lati kopa ninu idije agbaye yii, ogoje omidan (140) ni Mojisola Raimi yoo maa ba figa gbaga.
Ta a ni Joy Mojisola Raimi?

Oríṣun àwòrán, quuentiwa/Instagram
Loju opo ayelujara Instagram rẹ, 'queentiwa' lawọn eeyan mọ Omidan Joy Mojisola Raimi, si.
Ọmọ bibi ipinlẹ Osun ni ọmọge ẹni ọdun mẹrinlelogun naa.
Iya rẹ ti ku lati igba ti Joy wa ni kekere, gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ nipa rẹ, o si koju iya pupọ lasiko to n dagba.
Eyi kọ ni igba akọkọ ti Omidan Joy yoo kopa ninu idije ọmọge to rẹwa, lati nnkan bii ọdun mẹrin sẹyin lo ti bẹrẹ si i kopa.
Mojisola ti yoo ṣoju Naijiria ninu idije obinrin to rẹwa ju lagbaaye, lo gbegba oroke ninu idije Omidan Intercontinental Africa to waye ni 2022.
Loju opo Instgram rẹ ni Omidan Raimi ti ṣalaye pe, oun fẹran lati maa ṣaanu ọmọniyan.
O ni ọkan lara awọn asiko ti ara oun maa n ya gaga ju ni asiko ti oun ba n fun awọn eeyan ni ireti, ti oun si n mu inu wọn dun.
Ọpọlọpọ iṣẹ itọrẹ aanu lo ni oun ti ṣe fawọn eeyan to nilo rẹ, ti oun si tun lero lati maa tẹsiwaju gẹgẹ bi awokọṣe fun awọn eeyan ti oun ju lọ lọjọ ori.














