Wo àwọn ọmọ Adúláwọ̀ tí owó wọn wọ bílíọ̀nù, tí Forbes kéde fún ti ọdún 2025

Aworan awọn mẹta ninu olowo nla ọmọ ile Adulawọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ Forbes to maa n ṣe akojọpọ awọn olowo nla (Billionaires) lagbaaye ti gbe ti ọdun 2025 yii jade.

Ninu rẹ ni wọn ti ṣa awọn ti wọn jẹ Adulawọ to wa ni isọri naa fun ti ọdun yii.

Apapọ awọn biliọnia ti Forbes kede fun ti ọdun 2025 jẹ 3,028, apapọ ọrọ̀ wọn si wọ $16.1 trillion.

Lara awọn to wa nipo naa ninu awọn Adulawọ ni a ti ri awọn mẹtalelogun (23).

Apapọ owo awọn Adulawọ yii to $96.2 billion bi Forbes ṣe kede.

O ni lati ara okoowo, ẹka agbara ati imọ ẹrọ ni awọn owo naa ti wa ju.

Wo awọn olowo nla ọmọ ilẹ Adulawọ mẹtalelogun naa

1. Aliko Dangote

:$23.9 billion.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Orisun ọrọ̀: Cement, ṣuga

Orilẹede: Naijiria.

Ọdun 2013 ni Dangote bẹrẹ ile ifọwopo to tobi ju l'Afica. Lẹyin ọdun mọkanla, pẹlu $23 billion to tun na lori ileeṣẹ epo ati agbara naa, owo Dangote gunke si I pẹlu $10.5, nigba ti ileeṣẹ naa bẹrẹ iṣẹ ni2024.

2. David Steward

: $11.4 billion

Orisun owo: ipese nnkan ikansira ẹni

:Orilẹede: U.S

3) Robert F. Smith

: $10.8 billion

Orisun owo: Tita ipin idokowo fun awọn aladaani

Orilẹede : U.S.

4) Alexander Karp

: $8.4 billion

Orisun owo: Ipese awọn nnkan eelo kọmputa

Orilẹede: U.S.

5) Mike Adenuga

: $6.8 billion

Orisun owo: Ẹka ibaraẹnisọrọ, epo

Orilẹede: Naijiria

6) Abdulsamad Rabiu

$5.1 billion

Orisun owo: Simẹnti, ṣuga

Orilẹede: Naijiria

7) Michael Jordan

: $3.5 billion

Orisun owo: Charlotte Hornets, (ere bọọlu alapẹrẹ) òǹtẹ̀

Orilẹede: U.S.

8) Patrice Motsepe

: $3 billion

Orisun owo: Iwakusa

Orilẹede: South Africa

8) Oprah Winfrey

: $3 billion

Orisun owo:Eto ori amohunmaworan

Orilẹede: U.S.

10) Jay-Z

: $2.5 billion

Orisun owo: Orin kikọ

Orilẹede: U.S.

11) Adebayo Ogunlesi:

: $2.2 billion

: Tita ipin idokowo fun awọn aladaani

Orilẹede: U.S.

12 )Magic Johnson

: $1.5 billion

Orisun owo: Bọọlu alapẹrẹ, idokowo

Orilẹede: U.S.

12 ) Femi Otedola

: $1.5 billion

Orisun owo: Ẹka agbara, nnkan eelo

Orilẹede: Naijiria

Awọn yooku ni:

14) Tope Awotona

: $1.4 billion

Nnkan eelo Kọmputa

Orilẹede: United States

14 )Tyler Perry

: $1.4 billion

Orisun owo: fiimu, amohunmaworan

Orilẹede: U.S.

14 ) Tiger Woods

: $1.4 billion

Orisun owo: ere idaraya Golf

Orilẹede: U.S.

14) Rihanna

: $1.4 billion

Orisun owo: Orin kikọ, nnkan ipara

Orilẹede: Barbados

18) Mohammed Ibrahim

: $1.3 billion

Orisun owo:Ẹka ibaraẹnisọrọ

Orilẹede: UK

18) LeBron James

: $1.3 billion

Orisun owo: Bọọlu alapẹrẹ

Orilẹede: U.S

20. Strive Masiyiwa

: $1.2 billion

Orisun owo:Ẹka ibaraẹnisọrọ

Orilẹede: Zimbabwe

21) Michael Lee-Chin

: $1.1 billion

Orisun owo: Akojọpọ owo

Orilẹede: Canada

21) Herriot Tabuteau

: $1.1 billion

Orisun owo: ipese nnkan ilera

Orilẹede: U.S.

23. Sheila Johnson

: $1 billion

Orisun owo: Tẹlifiṣan ayelujara aladaani ati ọpọ ile itura.

Ilu: America.