Wande Abimbola sọ̀rọ̀ lórí ìdí tí Ifa ṣe yan ará ìlú òyìnbó bíi Aláàfin dípò ẹni tó wà ní Nàíjíríà
Lẹyin ọdun mẹta ti awuyewuye ti rọ mọ ipo Alaafin Ọyọ ati ori itẹ, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makide kede Alaafin tuntun fun ilu Ọyọ.
Ninu atẹjade ti ijọba ipinlẹ Ọyọ fi ranṣẹ si awọn oniroyin lorukọ Kọmisana fun iroyin, Ọmọọba Dọtun Oyelade, wọn kede Ọmọọba Akeem Abimbola Owoade gẹgẹ bii Alaafin tuntun fun Ọyọ.
Alaafin Owoade si lo n jẹ Alaafin lẹyin ti Alaafin ana, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta waja ni ọjọ Kejilelogun osu kẹrin ọdun 2022.
Loni ọjọ Karun osu kẹrin ọdun 2025 ni ayẹyẹ iwuye Alaafin tuntun fun ilu Oyo, Ọba Abimbola Akeem Owoade Kinni.
Ilu Oyo si ni ayẹyẹ iwuye naa yoo ti waye, ti BBC Yoruba si ti wa nikalẹ digbi lati maa mu awọn iroyin ohun to n sẹlẹ nibẹ wa fun yin.
Ilu Oyo naa si la ti se alabapade agba awo to tun jẹ Ọjọgbọn fasiti ti wọn to fẹyinti, Wande Abimbola.

"Ki lo de to jẹ pe ilu oyinbo ni Ifa ti lọ mu Ọba Owoade tii se Alaafin tuntun, ti ko si mu awọn ọmọ oye to wa nilẹ Naijiria"
Agba awo Ogunwande Ifagbemi Sangodahunsi, lo jẹ Awisẹ Agbaye fun gbogbo Babalawo ati ọkan ninu awọn Awo fun Ọọni tilu Ile Ife.
Ibeere ti ọpọ eeyan si maa n beere lọpọ igba lori ayelujara lo kọkọ wa sọkan ikọ iroyin BBC Yoruba lati bi Ọjọgbọn Wande Abimbola.
Ibeere naa ni pe ki lo de to se jẹ pe ilu oyinbo ni Ifa ti lọ mu Ọba Owoade tii se Alaafin tuntun, ti ko si mu awọn ọmọ oye to wa nilẹ Naijiria.
Nigba to n dahun ibeere yii, agba awo Abimbola sọrọ lori Ifa to da lati mu Alaafin tuntun naa.

"Se eeyan maa n beere lọwọ Ifa ni, pe se ara Naijiria ni ki wọn mu ni tabi ẹni to n gbe ni ibikan"
Nigba to n dahun ibeere yii, Baba Abimbola ni ohun to wu Ifa, ni Ifa se.
"Ifa yan Ọba tuntun fun wa ni Oyo, Ọba Abimbola Akeem Owoade Kinni, Baba Ẹlẹwu Ẹtu, Aboko leti Akinmọrin, aboko leti Abodonpa.
Ifa lọ yan-an, Ifa lọ yan-an, ki Ọlọrun jẹ ki ade rẹ pẹ lori, ki bata rẹ si pẹ ni ẹsẹ.
Se eeyan maa n beere lọwọ Ifa ni pe se ara Naijiria ni ki wọn mu ni tabi ẹni to n gbe ni ibikan.
Ọlọrun si ba wa ṣe, ẹja nla ni Ifa tiwa gbe, Ifa wa ko gbe Ìsín, bẹẹ ni ko gbe Ìkòrò, Àrúnwọ́n, ẹja kan n bẹ, ti wọn n pe ni Aruwọn, ni Ifa mu.
Ki Ifa o b awa ṣe, ki Eledumare o b awa ṣe, ko ni ojo dunlẹ, awo ile Elesiẹ, oun naa lo difa fun Elesiẹ ọ̀wọ.
Bi ori ba pẹ nilẹ, yoo di ire.







