Aláàfin Oyo tuntun jáde ní Ìpèbí lẹ́yìn ọjọ́ bíì mọ́kànlélógún, ariwo sọ l'Oyo

Aworan Alaafin Oyo tuntun

Oríṣun àwòrán, Akin Abubakar/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Alaafin ti ilu Oyo tuntun, Ọba Abimbola Owoade, ti jade ni Ipebi lonii ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Keta, lẹyin ọjọ bii mọkanlelogun ti ori ade naa ti wa nibẹ.

Tilu tifọn lawọn eeyan ilu Oyo fi pade Ọba Owoade nigba ti o n bọ lati Ipebi.

Ọgọọrọ eeyan lo kọwọ rin pẹlu Ọba Owoade bi ori ade naa ṣe n rin laarin ilu Oyo lọ si aafin rẹ ti ilu si n ro lakọ lakọ.

T'ọmọde t'agba to fi mọ awọn agbofinro lo peju pẹsẹ sibi eto naa.

Awọn oniṣẹṣe lo ṣaaju kabiyesi nigba ti onikakaki ọba n fọn kakaki lati yẹ Ọba Owoade si.

Ohun ti a gbọ ni pe Koso ni Alaafin yoo sun lalẹ oni.

Laaarọ ọla ọjọ Abamẹta ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu yii ni Ọba Owoade yoo dade iṣẹmbaye.

Lẹyin ti ori ade naa ba de ade yii tan ni a gbọ pe awọn araalu ilu le maa pe e ni kabiyesi.

''Kara o le'' ni a gbọ pe wọn n ki Alaafin tuntun lọwọ yii, lẹyin ti Ọba Owoade ba de ade iṣẹmbaye tan lawọn eeyan yoo bẹrẹ si ni ni kabiyesi.

Ọjọ Ẹti ọjọ keje oṣu Kẹta yii ni kabiyesi Owoade wọ Ipebi.

Aláàfin Owoade kéde kókó ohun tí yóò ṣe lórí ìtẹ́

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹwẹ, Alaafin Ọyọ tuntun, Oba Akeem Abimbola Owoade ti fi ọrọ lede nipa awọn afojusun rẹ lori aleefa.

Atẹjade kan ti Bode Durojaiye, tii se adari ikede ati ipolongo fun Ọba Owoade, fisita fawọn akọroyin lo sisọ loju ọrọ yii.

Ọba Owoade ni ọkan pataki lara awọn akanṣe iṣẹ ti oun yoo ṣe lori itẹ ni lati ri daju pe awọn ọdọ to n fi ẹsẹ gbalẹ kiri, lẹyin ti wọn ti kẹkọọ jade lai ri iṣẹ, yoo kuro ni ẹgbẹ alaini iṣẹ.

Bakan naa ni Kabiyesi fi kun ọrọ rẹ wi pe, oun yoo ṣe agbekalẹ idanilẹkọ nipa iṣẹ ọwọ fun awọn ọdọ.

Alaafin fi idi rẹ mulẹ wi pe, awọn akẹkọọjade kan ti wọn ti kẹkọọ gboye 'Bsc tabi HND' yoo ri iranlọwọ gba lati kọ nipa aabo ori itakun ayelujara, 'Cyber Security', ki wọn le ni anfani lati lọ ṣiṣẹ ni oke okun.

Alaafin Owoade fi kun ọrọ rẹ wi pe, oun yoo tẹsiwaju ni ibi ti Alaafin ana, Oba Adeyemi ti ṣiwọ iṣẹ, fun idagbasoke ọdun Ṣango ati Ọranmiyan.

Bakan naa ni atẹjade naa tọka si pe awọn opo yoo ri iranlọwọ gba fun igbeaye irọrun.

Idagbasoke eto ilera ilu Ọyọ naa ko gbẹyin gẹgẹ bi Ọba alade naa ṣe n gbero lati ke si awọn ẹlẹyinju aanu lati oke okun lati ṣe atilẹyin fun ijọba rẹ.

Ọba Owoade yoo tun riidaju wi pe gbogbo awọn nnkan iṣẹmbaye ilu Ọyọ ti wọn ti ko lọ si ilẹ Gẹẹsi lati ọdun 1895 ni yoo di dida pada.

O fikun pe awọn ohun isembaye naa yoo pada pẹlu ere owo gẹgẹ bi o ṣe n ṣe ileri lati bẹ awọn agbekalẹ ohun atijọ wo.