Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ọba Abimbola Akeem Owoade, Alaafin tuntun fún ìlú Oyo

Lẹyin ọdun mẹta ti awuyewuye ti rọ mọ ipo Alaafin Ọyọ ati ori itẹ, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makide kede Alaafin tuntun fun ilu Ọyọ.
Ninu atẹjade ti ijọba ipinlẹ Ọyọ fi ranṣẹ si awọn oniroyin lorukọ Kọmisana fun iroyin, Ọmọọba Dọtun Oyelade, wọn kede Ọmọọba Akeem Abimbola Owoade gẹgẹ bii Alaafin tuntun fun Ọyọ.
Alaafin Owoade si lo n jẹ Alaafin lẹyin ti Alaafin ana, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta waja ni ọjọ Kejilelogun osu kẹrin ọdun 2022.
Loni ọjọ Karun osu kẹrin ọdun 2025 ni ayẹyẹ iwuye Alaafin tuntun fun ilu Oyo, Ọba Abimbola Akeem Owoade Kinni.
Ilu Oyo si ni ayẹyẹ iwuye naa yoo ti waye, ti BBC Yoruba si ti wa nikalẹ digbi lati maa mu awọn iroyin ohun to n sẹlẹ nibẹ wa fun yin.
Amọ ki ayẹyẹ iwuye to bẹrẹ, ẹ wa wo awọn ohun pataki to yẹ ki ẹ mọ nipa igbe aye Alaafin Abimbola Akeem Owoade, tii se Alaafin kẹrindinlaadọta ti yoo jẹ nilu Oyo.

Awọn ohun pataki nipa igbe aye Alaafin Abimbola Akeem Owoade, Alaafin kẹrindinlaadọta nilu Oyo
Wọn bi Ọmọọba Akeem Owoade ni aadọta ọdun sẹyin, si idile Owoade-Agunloye niluu Ọyọ. O jẹ ọkan lara awọn ọmọ Alagba Rasaki Ibiyosi Owoade, ọmọ-ọmọ Aremo Aderounmu Iyanda Owoade, ni agboole Agure niluu Ọyọ.
Owoade pari ẹkọ Girama ni ile ẹkọ 'Baptist High School', Saki, n'ipinlẹ Ọyọ l'ọdun 1992.
O kẹkọọ gboye ọdun mẹrin nipa Imọẹrọ ni ile ẹkọ gbogboniṣe Poli ilu Ilaro n'ipinlẹ Ogun, laarin ọdun 1994 si 1997. Bakan naa ni o kẹkọọ ni ile ẹkọ gigia gbogboniṣe, Poli Ibadan, laarin ọdun 1999 si 2001.
O ṣe Agunbanirọ pẹlu ileeṣẹ afẹfẹ gaasi orilẹede Naijiria, 'Nigeria Gas Company', gẹgẹ bii Onimọẹrọ to n gba imọ kun imọ ni ọdun 2002.
O ṣiṣẹ pẹlu ile ifowopamọ 'Oceanic Bank International Plc' ni ilu Warri laarin ọdun 2003 si 2004.
Ọmọọba Akeem Owoade tun tẹsiwaju lẹnu ẹkọ rẹ lọ si ile Gẹẹsi, nibi ti o ti kẹkọọ nile ẹkọ giga 'University of Sunderland' l'ọdun 2008, ati 'Northumbria University' ni ọdun 2012 ni ibi ti o ti kẹkọọ gboye imọ ẹrọ.
Ọmọọba Akeem Owoade tun gba iwe ẹri imọ nipa akoso akanṣe iṣẹ, PMP, ninu oṣu kẹfa ọdun 2015.

O ṣiṣẹ gẹgẹ bii Onimọẹrọ nileeṣẹ epo rọbi, 'Oil Reach Company, Glasgow ni United Kingdom fun ọdun diẹ, ki o to lọ si orilẹede Canada fun awọn anfani ọtun.
Lọwọlọwọ bayii, Ọmọọba Akeem Owoade ni alakoso ileeṣẹ to n pin ina mọnamọna, 'Manitoba Hydro' ni Canada. Bakan naa ni o tun jẹ aarẹ ileeṣẹ ' 100279 Manitoba Limited', ileeṣẹ to n ri si awọn ileigbe ati eti ẹnawo ni Manitoba lorilẹede ede Canada.
Awọn iṣẹ wọnyii si ni o n ṣe lọwọ ti iroyin fi gbode kan wi pe oun ni Alaafin Ọyọ tuntun.














