Ẹ fura o! Àwọn agbébọn àti ajínigbé ti fẹ́ sọ ilẹ̀ Yorùbá dilé - Gani Adams, Makinde

Seyi Makinde, Gani Adams

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Gani Adams

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ààrẹ̀ ona-kakanfo ilẹ̀ Yorùbá, Iba Gani Adams ti rọ àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá láti wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí nípa ètò ààbò ní agbègbè kóówá wọn.

Àrọwà Gani Adams yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde kọminú lórí bí àwọn agbébọn ṣe ń ya kúrò ní ẹkùn ìwọ oòrùn àríwá wọ gúúsù Nàìjíríà.

Gómìnà Makinde ti ṣáájú ké gbàjarè pé àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá nílò láti tètè mójútó ọ̀rọ̀ náà kó tó di ohun tí apá kò ní ká mọ́.

Àtẹ̀jáde tí olùrànlọ́wọ́ pàtàkì lórí ìròyìn sí Gani Adams, Kehinde Aderemi fi léde rọ àwọn gómìnà láti má kọ etí ikún sí ìkìlọ̀ náà.

Gani Adams wòye pé ọ̀rọ̀ ètò ààbò jẹ́ ìpèníjà ńlá tó ń bá Nàìjíríà fínra.

Ó ní láti ọdún tó kọjá ni òun ti ń pe àkíyèsí àwọn gómìnà sí ọ̀rọ̀ náà àmọ́ tí wọn kò ṣe ohunkóhun sí ìpè náà.

Ó sọ pé ojoojúmọ̀ ni ètò ààbò Nàìjíríà sì ń mẹ́hẹ síi.

"Ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ètò ààbò ilẹ̀ Yorùbá àtàwọn míì tó wà lábẹ́ àkóso mi ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ láti ri dájú pé agbègbè wa ní ààbò tó péye.

"Nísìn-ín tí Gómìnà Makinde ti ké gbàjarè nípa rẹ̀, a nílò láti wá ọ̀nà láti mójútó kó tó di nǹkan míì mọ́ wa lọwọ́."

Ó ní àwọn kò ní gba kí àwọn agbébọn àti àwọn ajínigbé sọ ilẹ̀ Yorùbá di ilé.