Iná tó ń jó kíkankían ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ ní Los Angeles lórílẹ̀èdè Amẹ́ríkà

Aworan agbegbe kan ni Los Angeles ti ina ti n jọ kikankikan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Titi di asiko ti apari akojọpọ iroyin yii ni ọrọ ijamba ina to waye niluu Los Angeles ṣi n jẹ fun ọpọ awọn eeyan, pẹlu bi eefin ina ṣe ṣẹyọ, to si jo ọpọ dukia di eeru.

Ori ilẹ ti ko din ni ogun eeka (20acres) ni eefin ọhun ti bẹrẹ nitosi ori oke Pacific Palisades, agbegbe kan to sunmọ Malibu ati Santa Monica.

Bi awọn eeyan ṣe kọkọ bẹrẹ sii ri eefin naa to tun n yọ ina, lo ti n jẹ kayeefi fun wọn nipa ohun to n ṣẹlẹ, ṣugbọn ti eefin ọhun tun bọlẹ kọja sisọ.

Aarin ogun iṣẹju ni iroyin sọ pe eefin ina ọhun fi tan de ori ilẹ to le ni igba (200acres) ni nnkan bi agogo mẹwaa aabọ aarọ ti wọn.

Afẹfẹ nla kan ti wọn ti n ṣe ikilọ rẹ tipẹ la gbọ pe o n gbe eefin nla naa kaakiri, to si bọle gidi.

Loju ẹsẹ ti iroyin yii ti kan awọn alakoso lara, ni wọn ti ran awọn ọkọ ofurufu agberapa ti awọn panapana lọ sibẹ lati dawọ rẹ duro.

Ileeṣẹ gomina ti gbe awọn ọkọ baalu agberapa oniranwọ bii aadọta dide lati ṣe iranwọ.

Ṣaaju asiko yii la gbọ pe aṣotẹlẹ ti jade sita nipa iji Santa Ana pe eefin rẹ yoo bọlẹ rẹpẹtẹ gidi.

Aworan agbegbe kan ni Los Angeles ti ina ti n jọ kikankikan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn alakoso ti n ṣe ikilọ fun gbogbo awọn to n gbe ni LA tẹlẹ.

Krishan Chaudry, ọkan lara awọn to n gbe nitosi ibi ti ina ọhun ti ṣẹyọ sọ pe lojiji loun ri ina to n jo lẹyinkule ile oun, toun si sare jade.

O ni ojiji inaa ọhun ṣẹyọ lai mọ ohun to fa a, o sọ fun iroyin CBS.

"Aarin iṣẹju aaya ni iṣẹlẹ naa bẹrẹ," Chaudry sọ bẹẹ.

"A kan ṣa n wo eefin nla to bọlẹ naa ni, to si jẹ pe lojiji,a bẹrẹ sii ri ina kaakiri."

Bi ina ati ọhun ṣe n tan kaakiri, ni awọn alakoso ti bẹrẹ sii pariwo pe ki awọn olugbe awọn agbegbe naa ttete ba ẹsẹ wọn sọrọ ko too pẹ ju, ki ina naa ma ba a gbẹmi wọn.

O jẹ iyalẹnu nigba ti awọn ọkọ bẹrẹ sii jona lori iduro.

Akọroyin BBC bẹrẹ sa asala fun ẹmi ara rẹ

Sheriff

Lucy Sheriff to jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ BBC naa n gbe lagbegbe yii, o si ti palẹmọ awọn ẹru rẹ kuro nibẹ loju ẹsẹ.

Nigba to n sọrọ, Sheriff sọ pe "Mo ṣi wa nile, bo tilẹ jẹ pe awọn alaṣẹ ti sọ pe ki gbogbo eeyan kuro ni Palisades, ti awa naa si ti n palẹmọ. Gbogbo opopona ni sunkẹrẹ-fakẹrẹ ti wa, to jẹ pe ko sẹni to le lọ siwaju tabi ẹyin. Mo ṣi n woye...ko to di pe emi naa kuro nile.

"Mo ti palẹmọ awọn ẹru mi diẹ sinu baagi kan, ki n le lọ sibi ti mo le lọ. O ṣi n jẹ kayeefi bi ina ọhun ṣe n gbilẹ. Ni nnkan bi agogo mẹwaa aabọ aarọ, mo ṣakiyesi eefin kekere kan to n bọ lati agbegbe ori oke naa, to si jẹ pe nigba ti yoo fi di wakati kan, eefin naa ti dabi kurukuru.

"Ọkan lara awọn alabagbe lo fun mi ni aṣọ iboju-bomu ti mo lo lati fin min ninu eefin ati kurukuru naa," Sheriff sọrọ.

Awọn ile-ẹkọ naa tilẹkun pa

Awọn alakoso ile-ẹkọ Los Angeles Unified School District sọ pe awọn ti n ko gbogbo awọn akẹkọọ wọn kuro nile-ẹkọ naa lati daabo bo wọn.

Ko tii ju bi ọsẹ meloo kan sẹyin ti ile-ẹkọ naa ṣilẹkun lẹyin ti asiko otutu dopin.

Awọn ọmọde la gbọ pe wọn n lọ sile ẹkọ yii.

Wọn ko awọn ohun ọsin inu ile pamọ fun aabo

Oloogbo

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn araalu ti wọn ni awọn ohun ọsin ni iroyin fi to wa leti pe wọn ti n wa ibi ti wọn yoo ko awọn ohun ọsin wọn lọ lati daabo bo wọn.

Ko din ni ile itọju awọn ohun mẹjọ to wa nitosi ni wọn ti ṣilẹkun wọn silẹ bayii lati gba awọn ohun ọsin kekeekee, ki awọn olowo wọn baa le roju-raye wa aabo funra wọn.

Ṣugbọn ṣa, wọn ti ri ijapa kekere kan to n sare lopopona lasiko ti awọn eeyan n sa asala fun ẹmi ara wọn lagbegbe Eaton to wa ni Altadena.

Igba akọkọ ree ti ajalu yii yoo maa waye ni Pasadena

Jennifer Colby, ọka lara awọn alakoso eto aabo ni Pasedena sọ pe wọn ko ri iru iṣẹlẹ naa ri lagbegbe ọhun, ati pe igba akọkọ ree.

"O ṣoro gidigidi," o sọ fun BBC.

Colby ni ẹgbẹẹrun awọn oṣiṣẹ ni wọn n "ṣiṣẹ takuntakun lati ṣe iranwọ fawọn ara agbegbe naa, lojuna lati rii pe gbogbo eeyan ni ko farapa, wọn si wa ni ilera pipe."

Awọn ileeṣẹ panapana sọ pe ayipada oju ojo le ṣe iranwọ laarin ọjọ diẹ le dẹkun ajalu ọhun.