Mubarak tó ní kò sí Ọlọ́run gba ìtúsílẹ̀ lẹ́wọ̀n, ṣùgbọ́n ẹ̀rù ikú ṣì ń bà á

Mubarak Bala lasiko ifọrọwanilẹnuwo.
Àkọlé àwòrán, Mubarak Bala.
    • Author, Yemisi Adegoke
    • Role, BBC News, Abuja
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gbajumọ ọmọ Naijiria ti ko gbagbọ pe Ọlọrun wa, ni Mubarak Bala.

Wọn ṣẹṣẹ fi silẹ lọgba ẹwọn bayii ni nitori ẹsun isọrọ-odi si Ọlorun ti wọn fi kan an.

Mubarak ti lo ju ọdun mẹrin lọ lọgba ẹwọn ko too jade bayii. Ọkunrin naa ti n gbe nile kan ti aabo ti wa fun un bayii, ṣugbọn ibẹru iku ṣi wa lọkan rẹ ati tawọn lọọya rẹ to gba ẹjọ ro fun un ni kootu.

Mubarak Bala, ẹni ogoji ọdun, ni wọn pe lẹjọ ni kootu kan nipinlẹ Kano, ijọloju lo si jẹ, pe o jẹwọ pe oun jẹbi ẹsun mejidinlogun ti wọn fi kan an nitori ọrọ kan to kọ loju opo Facebook ni ọdun 2020.

Nigba to n ba BBC sọrọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ti wọn ṣe fun un lẹyin to jade lẹwọn, Bala sọ pe " ọrọ nipa aabo mi lo maa n wa lọkan mi nigba gbogbo."

Bẹẹ ni Mubaraq Bala wi bo ṣe bẹrẹ si i jẹ ounjẹ akọkọ lẹyin to gba ominira lẹwọn.

Gẹgẹ bi a ṣe mọ, orilẹede Naijiria jẹ ibi kan ti ẹsin ti rinlẹ pupọ. Bi ẹnikẹni ba si n sọrọ abuku si ẹsin, boya ti Islam abi ẹsin Kristẹni , wọn ki i fi oju ire wo ẹni bẹẹ.

2014 ni Mubarak Bala kọ ẹsin Islam silẹ

Iwa ọdaran ni ki eeyan sọ ọrọ odi si Ọlọrun ninu ofin ẹsin Islam ti i ṣe Sharia.

Ofin Sharia yii pẹlu ofin orilẹede Naijiria ni wọn n lo ni ipinlẹ mejila ni Ariwa Naijiria.

Ni ti Bala, ọdun 2014 lo ni oun ko ṣe ẹsin Islam mọ, to si kuro ninu ẹsin naa.

Lasiko ti wọn fi si ahamọ, o ni oun maa n ro o pe o ṣee ṣe ki oun ma jade lẹwọn naa laaye.

Mubarak sọ pe ẹru maa n ba oun pe, awọn to n ṣọ oun tabi awọn ẹlẹwọn mi-in le da oju sọ oun lọgba ẹwọn Kano ti oun kọkọ wa, nigba to jẹ awọn Musulumi lo pọ ju nipinlẹ Kano.

" Ominira ti de loootọ, ṣugbọn ẹru ṣi n ba mi, o ṣee ṣe kawọn ohun to n ba mi lẹru tẹlẹ ṣi wa nita fun mi."

Bi ko ba jẹ ti ile-ẹjọ Ko-tẹ-mi-lọrun to din ẹwọn ọdun mẹrinlelogun ti wọn fun Mubarak ku lakọọkọ ni, ko ba pẹ lẹwọn ju bayii lọ.

Ṣugbọn adajọ sọ pe aṣeju ni ẹwọn ọdun gbọọrọ ti wọn fun un naa, o si ba a dinku.

Nigba to n jade lati inu ọgba ẹwọn naa, o han pe o ti rẹ ẹ, bẹẹ lo n sọ pe gbogbo nnkan lo ti yipada, to n jọ tuntun loju oun.

Ta a ni Mubarak Bala?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọdun 1984 ni wọn bi Mubarak Bala niluu Kano. Diẹdiẹ lo ni oun bẹrẹ si i sọ igbagbọ ninu Ọlọrun nu.

O ni ohun to jẹ ki oun jade fi ara oun han bii ẹni ti ko ni igbagbọ ninu Ọlorun, ni iṣẹlẹ ọmọbinrin kan ti wọn bẹ ori rẹ ni 2013, nitori ọrọ ẹsin.

Bala ni Aarẹ ẹgbẹ Humanist Association of Nigeria, o ti koju ipenija gidi, ọlọpaa si ti mu un fun bo ṣe jade si gbangba lati sọ pe ko si Ọlọrun.

Lọjọ karun-un, oṣu Kẹrin, ọdun 2022, ile ẹjọ giga ipinlẹ Kano ju Mubarak Bala si ẹwọn ọdun mẹrinlelọgun, lẹyin to ni oun jẹbi ẹsun mejidinlogun ti wọn fi kan an, eyi to ni i ṣe pẹlu isọrọ odi si Ọlọrun ati sisọ ọrọ to le mu awọn eeyam mi-in huwa aitọ.

Mubarak Bala jẹ ẹnikan to maa n sọrọ tako ẹsin, awọn eeyan si mọ ọ daadaa pẹlu igbagbọ rẹ to ni pe ko si Ọlọrun.

Awọn ikọ agbẹjọro kan ni wọn fi ọrọ rẹ to ọlọpaa leti nipa iru ọrọ bẹẹ kan to fi sori ayelujara, o pada de kootu, o si lo ọdun meji ni kootu ṣiwaju idajọ rẹ ni 2022.

Nigba to n jẹjọ ẹsun naa, Bala ni oun jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan oun, sugbọn eyi ko yi ipinnu ati igbagbọ rẹ pada.

"Mo gbagbọ pe ohun ti mo ṣe da aabo bo ẹmi mi ati ẹmi awọn eeyan mii ti ẹjọ mi kan, nitori wọn le dojusọ awọn naa pẹlu.

"Gbogbo bi mo ṣe maa n ja fun ẹtọ, ati awọn nnkan ti mo maa n gbe sori ayelujara yẹn, mo mọ pe wọn le pa mi, mo mọ ewu to rọ mọ, ṣugbọn mo ṣi pinnu lati tẹsiwaju, mi o si kabaamọ ohun ti mo ṣe"

Mubarak ni oun gbero lati bẹrẹ aye oun pada, paapaa julọ, o lo wu oun lati mọ ọmọkunrin ti oun bi ki oun to o lọ sẹwọn, ọmọ ti ko ju ọmọ ọsẹ mẹfa lọ nigba naa.

Nigba ti wọn ju Bala sẹwọn, o di ariwo laaarin awọn ẹgbẹ to faramọ iwa to n hu, wọn ni ọkunrin yii ko ṣe ẹṣe kankan.

Leo Igwe, oludasilẹ ẹgbẹ kan to n ri si ọrọ ọmọniyan, sọ pe ọpẹ ni pe Bala jade lẹwọn.

O ni ṣugbọn awọn eeyan yoo ṣi maa fi oju abuku wo o bi i pe ọdaran kan ni.

''Ni ti awa ti a n ri si ọrọ ọmọniyan, ko da ẹṣẹ kankan.''