Àrùn HMPV: Ǹjẹ́ ó yẹ kí ẹ̀rù arùn yìí máa ba gbogbo aye?

Awọn iya agbalagba meji ti wọn bo imu wọn ree ni opopona kan, ni Beijing, orilẹ ede China.

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Awon eeyan Beijing yii mura nilana to le dena HMPV, lẹyin ti iroyin jade pe arun naa ti pọ si i.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Arun kan ti wọn n pe ni Human Metapneumovirus (HMPV), ni wọn lo gbilẹ si i lagbegbe Ariwa China laipẹ yii, eyi si mu ibẹrubojo wa lọkan awọn eeyan ibẹ.

Eyi n waye lẹyin ọdun marun-un ti arun Covid-19 bẹ silẹ ni China, to si ṣe bẹẹ kari agbaye, ti akọsilẹ si wa pe eeyan miliọnu meje ni Corona pa.

Gẹgẹ bi awọn agba eleto ilera China ṣe wi, wọn ni awọn ti ọjọ ori wọn wa laaarin ọdun mẹrinla si isalẹ ni aisan HMPV yii n ba finra ju. Ṣugbọn wọn tako iroyin to ni aisan naa ti pọ debii pe awọn ileewosan ti kun ni China.

Bakan naa ni awọn kan naa ti lugbadi arun yii ni India, bi iroyin ṣe sọ.

Aworan awọn eeyan to n kọja lọ lẹgbẹẹ ipolongo to n kede pe ki wọn maa lo ibomu ni India. Ọjọ Aje, ọjọ kẹfa, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025 ni eyi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aworan to n kede pe kawọn eeyan maa lo ibomu ni India, lẹyin ti HMPV mu awọn eeyan kan nibẹ.

Ṣé àrùn tuntun ni HMPV yìí?

Gẹgẹ bi ẹka to n ri si ajakalẹ aruna ti itankalẹ rẹ, iyẹn Centers for Disease Control and Prevention (CDC) lorilẹ ede US ṣe wi, ọdun 2001 ni wọn kọkọ mọ ohun to n jẹ HMPV. Ṣugbọn awọn akọṣẹmọṣẹ lori arun, ṣalaye pe o ṣee ṣe ki arun yii ti wa fun ọdun gbọọrọ sẹyin ju 2001 lọ.

Bi a ba fi oju lasan wo HMPV, awọn apẹẹrẹ rẹ jọ ti otutu tabi ọfikin. Awọn apẹẹrẹ rẹ ni ikọ, iba, ki imu eeyan di, ki eeyan ma le mi daadaa. Ṣugbọn fun awọn mi-in, o le lagara ju bayii lọ.

Ẹka CDC sọ pe o le fa iṣoro aile mi daadaa fun ẹnikẹni tabi ọjọ ori yoowu ko jẹ. Wọn ni o le fa arun to n daamu igba aya ti oloyinbo n pe ni bronchitis. Bakan naa ni wọn lo le fa arun mi-in ti a mọ si pneumonia in people of all ages.

Wọn fi kun un pe awọn ọmọde, awọn to ti n dagba lọjọ ori atyi awọn ti ilera wọn ko ba peye lo maa n kọlu ju.

Iye ọjọ ti wọn ni HMPV fi n ṣoro fun ẹbi to ba mu ni ọjọ mẹta si mẹfa. Bi yoo ṣe daamu eeyan si da lorii bo ba ṣe lagabra si i lara ẹni to kọlu naa.

CDC sọ pe iwadii awọn fi han, pe asiko otutu ni HMPV maa n gbilẹ ju lawọn ilu olotutu bii oke okun.

Báwo ló ṣe ń tàn kálẹ̀?

Arun HMPV maa n tan kalẹ ju nigba ti ẹni to kọlu ba hukọ tabi sin lai bo ẹnu tabi imu. O le gbabẹ bọ sawọn to wa nitosi lara.

O tun ṣee lugbadi nigba ti ifara-rora ba pọ.

Awọn bii fifi ọwọ kan ẹlomi-in, gbigba ọwọ lọwọ ara ẹni ( shaking hands). Fifi ọwọ kan awọn nnkan eelo tabi ara nnkan ti kokoro HMPV ti wa, ki eeyan waa mu ọwọ naa lọ sẹnu, imu tabi oju rẹ, yoo lugbadi arun naa bi wọn sẹ sọ.

HMPV sabaa maa n tan kalẹ lasiko awọn oṣu otutu, nigba ti awọn eeyan maa n wa nile ju ti tẹlẹ lọ.

Aworan to n ṣalaye awọn apẹẹrẹ arun HMPV.
Àkọlé àwòrán, Aworan to n ṣalaye awọn apẹẹrẹ arun HMPV.

Kí ló dé tó jẹ́ àwọn ọmọdé àti arúgbó ni ewu HMPV wà fún jù?

Arun HMPV yii le mu ẹnikan ṣoṣo ni ọpọ igba. Awọn akọṣẹmọṣẹ sọ pe igba akọkọ to ba kọkọ mu eeyan naa lo maa n lagbara ju ṣaa.

Wọn ni lẹyin ikọlu akọkọ, ẹni naa yoo ti ni awọn ajẹsara kan ti yoo fi le koju HMPV to ba tun kọlu u.

Wọn ni bi ajẹsara yii ba ṣi wa lara eeyan, ti ko dinku latari awọn aisan bii HIV tabi jẹjẹrẹ, ara ẹni naa yoo le koju HMPV to ba tun mu un.

Eyi lo fa a ti awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko to ọdun marun-un, ati awọn agbalagba ti ọjọ ori wọn ti ju marundinlaaadọrin (65) lọ ti wọn ko si ni ajẹsara to pọ fi wa ninu ewu ikọlu HMPV.

Awọn ẹni to wọn ba ni aisan aile mi daadaa naa wa ninu ewu ikọlu HMPV.

Ṣugbọn ṣaa, awọn akọṣẹmọṣẹ lori ilera, gbagbọ pe nigba ti HMPV ti wa laye tipẹ, ajẹsara ti yoo dena rẹ naa ti wa kaakri aye.

Kí ló ń ṣẹlẹ̀ ní China?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aworan ati fidio awọn eeyan ti wọn tun n bomu kiri lorilẹede China tun ti gba ori ayelujara kan bayii.

Eyi mu kawọn eeyan maa ro o pe wahala kan tuntun ti wa, ati pe awọn ileewosan ti n kun si i latari arun kan.

Koda, awọn ẹka iroyin ibilẹ kan fi asiko yii we igba ti Korona gbode ni 2020.

Olori ẹka to n ri si arun to le tran ẹnikeji ni China, Kan Biao, sọ pe o ṣee ṣe ki awọn aisan aile-mi-daadaa kọlu China lasiko otutu ta a mọ si Winter ati Spring .

Kan Biao ṣalaye nibi ipade awọn akọroyin kan, pe bi HMPV ṣe n mu awọn ọmọ ti ọjọ ori wọn ko to mẹrinla n pọ si i ni.

Gẹgẹ bi Ọjọgbọn Tulio de Oliveira, oludarii ''Centre for Epidemic Response and Innovation'' ṣe ṣaalye, o ni HMPV jẹ ẹyọkan ninu awọn arun mẹrin to n waye lasiko otutu ni China bayii. Awọn mẹta yooku bo ṣe darukọ wọn ni : Respiratory syncytial virus, Covid ati Influenza.

O ni bi awọn eeyan ṣe n tara ni China bayii, pe ki ileewosan ṣiṣẹ wọn ko jẹ ijọloju, nitori asiko otutu ti wọn wa ati bi awọn arun mẹrin yii ṣe maa n sare ran.

Ọjọ Ẹti ni orilẹede China kede, pe awọn n ṣe iwadii lori oriṣii arun Pneumonai kan to dode ti ẹnikẹni komọ ibi to ti wa.

Bẹẹ ni wọn kede awọn arun ti ki i jẹ ki eeyan le mi daadaa kan, ti wọn lo ṣee ṣe ko pọ si i lasiko Winter.

Igbaradi yii yatọ si ohun to ṣẹlẹ lọdun marun-un sẹyin, nigba ti Corona kọkọ gbode.