''Ẹ ní kí Portable mú ẹ̀rí mílíọ́nù kan Náírà tó ní Ibadan fún òun wá'' - Máníjà Taye Currency

Oríṣun àwòrán, Portable/Taye Currency FB
Eti to ba gbọ alọ, o yẹ ko gbọ abọ.
Lẹyin ti olorin sufee-taka nni, Habeeb Okikiola (Portable), pe awọn ọmọ Ibadan lahun nitori ode orin ti ko le lọ niluu naa mọ, Maneja Taye Currency, Mc-Bokujaka, ti ni ara n ta Portable ni.
Mc Bokujaka ninu fidio kan to ṣe, ṣalaye pe ko sẹni to fi miliọnu kan naira ranṣẹ si Portable lati waa kọrin n'Ibadan.
O ni ayẹyẹ to fẹẹ da Portable ati Taye Currency pọ naa ku diẹ ko waye, ni awọn agbagba Ibadan sọ pe ẹtẹ ni yoo jẹ fun ilu naa bi Portable ba fi waa sibẹ lati kọrin.
Eyi ni Bokujaja sọ pe o fa a ti wọn fi ni ki Ọmọ Ọlalọmi, bawọn kan ṣe maa n pe Portabe ma wa mọ.
''Èmi ni mo kọ́kọ́ pe akiyesi Taye Currency si ere ti Portable fẹẹ waa ṣe n'Ibadan''

Oríṣun àwòrán, Screenshot
" Nipa ariwo ti Portable n pa, o yẹ ki ẹnikọọkan mọ pe ara n ta a nitori awọn to gbe eto kalẹ yọ orukọ rẹ kuro nibẹ ni.
"Wọn ni ko ma wulẹ wa s'Ibadan mọ.
Bi orukọ Taye Currency ko ba le gbe Portable wọ Ibadan, igba wo lo fẹẹ sẹe ṣe fun lati waa kọrin n'Ibadan.
"Ẹ jẹ ki Portable jade waa fi ẹri owo miliọnu kan ti Taye Currency fi ranṣe si i han.
"Ẹ ni ko fi ẹri han, pe Taye Currency lo pe oun.
"Bawo ni Taye Currency yoo ṣe fẹẹ fi Portable lokiki n''Ibadan, nibi to jẹ ilẹ rẹ gangan ( Ilẹ Currency).
"Emi ni mo kọkọ pe akiyesi Taye currency si ere ti Portable fẹẹ waa ṣe n'Ibadan, mo fun un lawọn idi to pọ ti wiwa rẹ le fi koba ayẹyẹ naa ati okiki Taye Currency n'Ibadan.
"Nigba ti Taye Currency n kuro nibi kan to ti lọọ kọrin lo pe mi, o sọ fun mi pe awọn agbaagba Ibadan pe oun, wọn ni nnkan abuku ni yoo jẹ bi Portable ba fi le waa kọrin n''Ibadan lẹyin gbogbo yẹyẹ to ti fi wọn ṣe.
''Ọrọ awọn agbagba Ibadan lo mu Currency pe awọn to ni ayẹyẹ naa lati sọ fun Portable pe ko ma wa mọ.''
Bayii ni Mc Bokujaja, Maneja Taye Currency ṣalaye.
O fi kun un pe ki gbogbo awọn ololufẹe Taye Currency kaakiri aye ma da Portable lohun.
O ni ki Portable too di gbajumọ olorin, Kogbagidi, ti mu un wa sọdọ Taye Currency ri, ti Taye fun un lowo.
Wọn tun pade niluu Ore, ipinle Ondo, Taye tun fun un lowo to pọ gidi bi Bokujaka ṣe sọ.
Portable gbọdọ dọbalẹ bẹ gbogbo ọmọ Ibadan
Lori ọrọ yii kan naa ni Ọmọọba Asawale Asanike, to ni Olori ọmọ ọba Ibadan ni oun, sọ pe Portable gbọdọ dọbalẹ fun gbogbo ọmọ Ibadan lati bẹ wọn.
Inu fidio kan ni Asawale ti sọrọ naa pẹlu alaye pe oju opo ti Portable ti ni Ibadan ko ni POP,to tun pe wọn lahun lo ti gbọdọ dọbalẹ.
O ni bi Portable ko ba ṣ eyi, wọn ko ni i lo awo orin rẹ mọ lori awọn redio ilẹ Ibadan.
Ìsọ̀rọ̀ nìgbèsì, Portable fún àwọn ará Ibadan lésì ìdí tí kò fi yọjú s'Ibadan

Oríṣun àwòrán, Portable Zazuu/Facebook
Gbajugbaja onkọrin takasufee ti ẹnu n kun ju lasiko yii, Habeeb Okikiola ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Portable ti sọ pe ko si otitọ kankan ninu iroyin wi pe oun lọ siluu Ibadan lati kọrin, ṣugbọn ti wọn ko jẹ ki oun kọrin nitori eto aabo.
Ọmọ Olalomi, gẹgẹ bi Portable tun ṣe n pe ara rẹ sọ pe ile oun l'oun wa, ti oun ko si rin irinajo lọ sibikankan lati ṣere nitori pe ara oun n fẹ ìsinmi.
Portable ni owo ti Taye Currency to ṣagbekalẹ eto ariya naa san fun oun ko pe iye ti mọnija oun n beere fun, eyi to jẹ miliọnu marun-un naira, to si ni miliọnu kan naira ni agba olorin Fuji naa fi ranṣẹ.
"Ẹyin ololufẹ mi, ẹ wo o, wọn purọ mọ mi ni o, mi o kuro nibi kankan, ilu Eko ni mo wa leti Sango. Ṣe o ti ye e yin, ara mi ko ya, mo n sinmi nile mi ni, bo ṣe gba," Portable ṣalaye ninu fọnran to gbe sita lọjọ Ẹti to kọja.
"Ti wọn ba tiẹ sọ pe mo ṣe fọnran lati fi fontẹ luu wi pe mo maa wa si ode ariya wọn, mo fi pọn wọn le lasan ni, ṣe o ti yee yin, owo kiliṣi ni wọn tẹ si mi.
"Eyin marun-un (miliọnu marun naira) ni mọnija mi sọ pe ki wọn fi ranṣẹ lati fi pọn wọn le nitori pe miliọnu mẹwaa naira la n gba.
"Igba ti wọn ko le san owo naa, to jẹ pe miliọnu kan naira ni wọn fi ranṣẹ. Ṣe miliọnu kan naira ni maa fi wọ mọto, ti maa fi gbe mọto mi, ti maa fi ko awọn ọmọ ẹyin mi, ati awọn ẹṣọ aabo, ti maa tun wa sibẹ.
"Rara, iyẹn ko ṣee ṣe bẹẹ. Ẹyin ti ẹ fi miliọnu kan naira ranṣẹ si mi, o yẹ ki ẹ fi mọto ranṣẹ lati gbe mi, ki ẹ tun fi awọn ẹṣọ aabo ranṣẹ, ki ẹ si ṣe adehun pẹlu awọn alakoso mi.
"Miliọnu kan naira ti wọn fi ranṣẹ ko le ra kiliṣi. Ati pe ibi ti wọn ba ti nifẹ mi, ni emi maa n lọ, ẹni ti Ọlọrun ran ni mi. Ibi ti wọn ba ti sọ pe awọn ko fẹran mi, mi o nii lọ sibẹ.
"Ẹ dakun, ti ẹ ba ti pe irawọ si ode ariya, ẹ ni lati pe awọn ẹṣọ aabo to maa daabo bo o, pẹlu mọto. To ba tiẹ jẹ pe ẹni ki n fi apo owo mi ranṣẹ, lotitọ mo ni manija," Portab;e fi kun ọrọ rẹ.
Ọdọkunrin olorin naa to fi ilu Sango nipinlẹ Ogun ṣebugbe tun jẹ ko di mimọ pe miliọnu mẹwaa naira loun maa n gba lati lọ si ode ere, ṣugbọn to ni oun pọn Taye Currency le, gẹgẹ bi agba olorin Fuji toun naa jẹ, loun ṣe ni ko san miliọnu marun-un naira.
O ni bi ko ṣe fi owo to ku ranṣẹ, ti owo to fi ranṣẹ ko si le gbe oun de ilu Ibadan, lo jẹ koun jokoo sile oun lati maa sinmi.
"Miliọnu mẹwaa naira ni mo sọ pe mo fẹẹ gba, ṣugbọn mo tun ro o pe gẹgẹ bi olorin si olorin, ki wọn fi miliọnu marun-un ranṣẹ. Wọn wa fi miliọnu marun naira ranṣẹ, owo ti ko ra epo si mọto, ti a si tun maa fun ọlọpaa lowo."
Ki lo ṣẹlẹ tẹlẹ?
Bi ẹ ko ba gbagbe, awọn alakoso eto ariya ita gbangba ti gbajugbaja akọrin Fuji , Taye Currency gbe kalẹ niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo sọrọ lori idi pataki ti akọrin takasufee, Habib Okikiola tọpọ mọ si Portable ko ṣe kọrin nibẹ.
Ileeṣẹ naa ti wọn pe ni Jarule Entertainment sọ pe aabo ẹmi ati dukia awọn araalu, paapaa awọn ololufẹ Taye Cureency ṣe pataki pupọ, idi ree ti wọn ko fi gba Portable laaye lati kọrin nibi eto naa.
Wọn ni awọn kan to n binu si Portable to tun n pe ara rẹ ni Were Olorin ni wọn fẹẹ lo anfaani eto ariya naa lati fiya jẹ Portable, to si ṣee ṣe ki wahala ti wọn ko lero ṣẹlẹ.
Ṣaaju asiko yii ni Portable ti sọrọ jade sita wi pe Taye Currency ti fi owo ranṣẹ soun lati wa kọrin niluu Ibada, to si bẹbẹ pe ki awọn ara ilu Ibadan forijin oun.















