Ọmọ ọdún mẹ́jọ jáde láàyè lẹ́yìn tó lo ọjọ́ márùn-ún pẹ̀lú kìnìún bí ogójì nínú igbó

Tinotenda Pudu

Oríṣun àwòrán, Mutsa Murombedzi/Twitter

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọmọdékùnrin kan, ẹni ọdún mẹ́jọ ni wọ́n ṣàwàrí rẹ̀ láàyè lẹ́yìn tó lo ọjọ́ márùn-ún nínú igbó kan èyí táwọn erin, kìnnìún àtàwọn ẹranko búburu ń gbé.

Àríwa orílẹ̀-èdè Zimbabwe ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé gẹ́gẹ́ bí aṣòfin kan ní orílẹ̀-èdè náà ṣe sọ.

Aṣòfin Mutsa Murombedzi tó ń ṣojú ẹkùn Mashonaland West kọ sójú òpó X rẹ̀ pé, ọmọkùnrin náà, Tinotenda Pudu sọnù sínú igbó Matusadona Game Park tó kún fún àwọn ẹranko búburú.

Ọjọ́ márùn-ún ni Pudu lò nínú igbó náà, tó ń sùn sórí àpáta pẹ̀lú bí àwọn kìnnìún ṣe ń bú ramúramù, táwọn erin sì ń kọjá.

Àwọn kìnnìún tó wà nínú igbó Matusadona tó ogójì. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí African Parks, igbó Matusadona sì ti fìgbà kan jẹ́ igbó tó ní kìnnìún jùlọ nílẹ̀ Africa.

Àwọn aláṣẹ Zimbabwe Parks and Wildlife Management Authority fìdí ìròyìn náà múlẹ̀ fún BBC àmọ́ wọn kò ṣàlàyé bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé.

Aṣòfin Murombedzi lóju òpó X rẹ̀ ní, Tinotenda lo ìmọ̀ rẹ̀ nípa inú igbó láti ri dájú pé ó wà láyé ní gbogbo ọjọ́ tó lò nínú igbó náà.

Àwọn èso ló ń jẹ nínú igbó náà, tó sì tún fi igi gbẹ́ ilẹ̀ láti wá omi tó ń mu.

Àwọn èèyàn rẹ̀ ní ìlú Nyaminyami bẹ̀rẹ̀ si ni lu ìlù ní ojoojúmọ́ nígbà tí wọ́n ń wa, kí o le máa tọ ohun ìlù tó ń gbọ́ náà padà sílé.

Àmọ́ àwọn òṣìsẹ́ inú igbó náà ló padà dóòlà Tinotenda kúrò nínú aginjù tó wà náà.

Murombedzi sọ pé lẹ́yìn ọjọ́ karùn-ún ni Tinotenda gbọ́ ohùn ọkọ̀ tó ń bọ̀ tó sì sáré sí wọn àmọ́ ti kò bá wọn.

"Àwọn òṣìṣẹ́ náà ri ojú ẹsẹ̀ ọmodé, wọ́n wá gbogbo àyíká náà títí tí wọ́n fi ṣàwárí rẹ̀"

Igbó Matusadona fẹ̀ ní ìwọ̀n kílómítà 1,470sq táwọn ẹranko bíi erin, kìnnìún, àtàwọn ẹranko búburú si wà níbẹ̀.

Níṣe ni àwọn èèyàn ń kan sáárá sí ọmọ náà lórí ayélujára.