Oyún mẹ́ta jábọ́ lára mi, ọkọ kọ̀ mí, IVF já sófo, kí n tó di ọlọ́mọ l'áyé - Dayo Amusa

Dayo Amusa

Oríṣun àwòrán, Dayo Amusa/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gbajumọ̀ òṣère tíátà, Dayo Amusa ti sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìlàkàkà tó là kọjá kó tó di ọlọ́mọ láyé.

Ní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù Kọkànlá, ọdún 2024 ni Dayo Amusa kéde lórí ìkànnì Instagram rẹ̀ pe òun ti di ọlọ́mọ láyé, pé Ọlọ́run ti fi ọmọkùnrin ta òun lọ́rẹ.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló bá Dayo Amusa dáwọ́ ìdùnnú nígbà náà pàápàá àwọn tó mọ ohun tí ó là kọjá kó tó di pé ó bímọ.

Àtẹ̀jáde kan tí Dayo Amusa fi léde lójú òpó Instagram rẹ̀ lọ́jọ́ díẹ̀ sẹ́yìn, ló ti sọ̀rọ̀ nípa onírúurú ìgbésẹ̀ tó gbé nígbà tó ń wá oyún láti bíi ọdún mẹ́sàn-án sẹ́yìn.

Dayo Amusa nínú àtẹ̀jáde náà ní lẹ́yìn tí oyún jábọ́ lára òun nígbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ́dún 2015 ni àwọn dókítà sọ fún òun pé òun ní àìsàn uterine myomatosis.

Ó ní èyí mú kí àwọn dókítà sọ fún òun pé à fi kí wọ́n yọ ilé ọmọ òun kúrò, àmọ́ òun kọ̀ jálẹ̀ nítorí láti kékeré òun ni ó ti wu òun láti jẹ́ ìyàwó àti ìyá nígbà tí òun bá dàgbà.

Ó sọ pé dípò kí òun yọ ilé ọmọ, òun gbà láti ṣe iṣẹ́ abẹ láti fi yọ nnkan tó dì sínú ilé ọmọ náà, èyí tó ń da òun láàmú, iṣẹ́ abẹ náà sì lọ déédéé.

Ẹni tí mò ń fẹ́ kọ̀ mí sílẹ̀ nítorí pé mi ò rí oyun ní

Gbajúmọ̀ òṣèré náà tẹ̀síwajú pé lẹ́yìn ọdún kan ìyẹn ni òun tún gbìyànjú láti wá oyún sùgbọ́n tí gbogbo ìgbìyànjú òun já sí pàbó nítorí àwọn dókítà tún sọ fún òun pé ọ̀pá to máa n gbé ẹ̀yin ọmọ nínú òun ti bàjẹ́.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ó ní èyí ló fa ìpinyà láàárín òun àti ọkùnrin tó n fẹ́ nígbà náà.

Ọdún 2019 ni Dayo Amusa ní òun àti ọkọ̀ tí òun fẹ́ nígbà náà tún gbìyànjú láti wá oyún ṣùgbọ́n tí gbogbo ìgbìyànjú àwọn kò so èso rere.

Bákan náà ló ní àwọn tún gbìyànjú láti ṣe IVF àmọ́ pàbó náà ni ó jásí tó sì tún ṣokùnfà ìpinyà láàárín òun àti onítọ̀hún.

Dayo Amusa ní àwọn ìrírí yìí sọ òun sínú ìrònú tó lágbára, tó jẹ́ pé òun kò bá ará àti ẹbí ṣe mọ́, tó jẹ́ pé òun kò tún lè kópa nínú eré mọ́ dàbí alárà.

Ó ní pẹ̀lú àwon nǹkan tí òun ń là kọjá yìí, òun kò káàárẹ̀ ọkàn nítorí òun gbàgbọ́ pé Ọlọ́run máa dá òun lóhùn àwọn àdúrà òun tó bá di ọjọ́ kan.

"Gbogbo àwọn àsìkò ti mò ń la ìṣòro kọjá yìí ni ìyá mi máa ń rọ̀ mí láti kúrò ni Nàìjírià lọ sí ilẹ̀ òkèrè.

"Ọdún 2021 ni mo ṣàmúlò ìmọ̀ràn ìyá mi ti mo kúrò ní Nàìjíríà, ti àyipadà sì bá ìgbé ayé mi."

Ó sọ pé nígbà tí oun fi máa padà sí Nàìjíríà láti ìrìnàjò náà, ọkàn òun yípadà tóun sì gbàgba pé Ọlọ́run máa ṣe èyí tó da fun òun àmọ́ tí ọkàn òun tún bẹ̀rẹ̀ sí ní pami lásìkò tóun àtàwọn ẹbí òun pàdé níbi àjọyọ̀ ọdún 2023 táwọn máa ń ṣe ní ọdọọdún.

Dayo Amusa pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Dayo Amusa/Instagram

"Mo rántí pé bí gbogbo àwọn ẹbí mi ṣe ń dáwọ́ ìdùnnú, tí wọ́n ń jó, tí wọ́n ń yọ̀, mo kàn jòkóò sí ẹ̀gbẹ́ kan, ti mò ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé mi ò fẹ́ dá ṣe ọdun 2024, mo gbàdúrà pé kí Ọlọ́run sọ mí di obìnrin pípé tó bá fi máa di oṣù Kejìlá, odun 2024.

"Mo sun ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹkún nígbà tí mo dele lálẹ́ ọjọ́ náà, mo mu ọtí yọ débi tí mò ń bì títí tí mo fi sùn lọ síbẹ̀.

"Nígbà tí mo jí lọ́jọ́ kejì, mo bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣàdurà nínú èébì náà, tí mò ń rawọ́ rasẹ̀ sí Ọlọ́run láti sọ ẹ̀gàn mi dògo nínú ọdún 2024."

Dayo Amusa tẹ̀síwájú àdúrà kí Ọlọ́run ṣe àyípadà ìtàn ayé òun ló gba ẹnu òun ní orú ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá ọdún 2023 bọ́ sí ọdún 2024 tí òun sì dúpẹ́ pé Ọlọ́run gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu òun.

Ó ni inú òun dùn pé Ọlọ́run fi ire wá òun rí gẹ́gẹ́ bí orúkọ tó sọ ọmọ rẹ̀.

Kí ni Uterine Myomatosis?

Uterine myomatosis jẹ́ àìsàn tó máa ń ṣe èèyàn nígbà tí ọ̀pọ̀ ìju bá so sára agbẹ̀du ọmọ (uterus) obìnrin.

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí, idá ogún sí ogójì obìnrin tó ti wà ní ìpele láti lè bí ọmọ ló ní àìsàn yìí.

Ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ni kìí mọ̀ pé àwọn ní àìsàn náà nítorí kìí farahàn tàbí fún wọn ní àmì tàbí àpẹẹrẹ kankan ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀.

Lára àpẹẹrẹ tí uterine myomatosis máa ń mú dání ni kí nǹkan oṣù obìnrin máa mú ìrora tó lágbára dání tàbí kí ẹ̀jẹ̀ máa pọ̀ gan lásìkò tí bìnrin bá ń ṣe nǹkan oṣù lọ́wọ́.

Ó máa ń fa kí inú máa dun obìnrin, ẹ̀yìn ríro, ìtọ̀ séréséré àti ìrora lásìkò ìbálòpọ̀.

Ìwádìí ṣàfihàn pé ìdá mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin tí oyún máa ń wálẹ̀ lára wọn ní gbogbo ìgbà ló jẹ́ pé uterine myomatosis ni okùnfà wọn.

Bákan náà ni ló jẹ́ ìdá márùn-ún nínú àwọn nǹkan tó máa ń fa àìrí ọmọ bí fún obìnrin.

Lára àwọn nǹkan tó máa ń fa uterine myomatosis ni ọjọ́ orí, oúnjẹ, ara àsanjù àti àjogúnbá.

Uterine myomatosis ṣe é tọ́jú nípa lílo oògùn tàbí iṣẹ́ abẹ.